Wo ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí tuntun márùn-ún táwọn agbésùnmọ̀mí ń lò láti ṣe ìkọlù apanirun

Agbebọn kan to gbe ibọn lọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Bi awọn ẹka aabo kaakiri Naijiria ṣe n gbiyanju lati kapa awọn agbesunmọmi, agbebọn, ajinigbe ati bẹẹ bẹẹ lọ, bẹẹ ni awọn ikọ onikọlu naa ko sun, wọn n ja ọgbọn tuntun bi ojumọ ṣe n mọ.

Lẹnu lọọlọ yii, awọn to n ṣe ikọlu yii ko fi mọ lori araalu lasan mọ, wọn ti n koju ibudo awọn ologun atawọn ẹṣọ alaabo mi-in.

BBC ṣayẹwo awọn ọgbọn alumọkọrọyi marun-un tawọn ikọ apani n lo bayii lati fi ṣe ikọlu apanirun.

Kikọlu awọn ẹṣọ alaabo, ki wọn too yabo araalu

Ọkan lara awọn ọna tuntun ti awọn agbebọn n lo bayii ni ki wọn kọkọ yi awọn ẹṣọ alaabo po, ki wọn gba agbara lọwọ wọn ki wọn too yabo ilu ti wọn ti fẹ ṣoro.

Kaka ki wọn kọlu ilu taara, wọn yoo kọkọ yi ibudo ologun tabi alaabo yowu ko jẹ po, bi wọn ba ti ṣe eyi, yoo rọrun lati kọlu ilu.

Akawe iru rẹ to ṣẹlẹ laipẹ ni ti ilu Kasuwan Daji, niluu Kaura, ijọba ibilẹ Namoda to wa nipinlẹ Zamfara.

Wọn kọlu awọn ṣọja to wa nibẹ, wọn si pa ninu wọn.

Bi wọn ṣe ri i pe awọn ṣọja n wa ọna ti wọn yoo fi da aabo bo ibudo wọn, awọn kan ninu awọn onikọlu naa yabo ilu, wọn pa awọn eeyan, wọn si ji eeyan aadọta gbe lọ.

Bẹẹ naa ni wọn ṣe loṣu Keje, nigba ti wọn y abo Abule Tsamaye, Sabon Birni, nipinlẹ Sokoto, awọn araalu sọ pe wọn kọkọ yi awọn ẹṣọ alaabo to wa labule naa po, won si dana ibọn ya wọn, eyi ti ko jẹ ki ṣọja kankan le wa gba araalu silẹ mọ nigba ti wọn bẹrẹ ikọlu.

Nigba naa ni wọn bẹrẹ si i ya ile sile pa awọn eeyan, wọn n ko wọn ni dukia, won si ji awọn mi-in gbe lọ.

Awọn onimọ nipa aabo sọ pe ilana yii maa n fun awọn bandiiti ni anfaani lati maa ṣọṣẹ lọ lai si idiwọ.

Awọn agbebọm na ibọn wọn soke, wọn fi aṣọ bo oju wọn

Oríṣun àwòrán, Others

Didana sun awọn eeyan mọnu ile

Ọna tuntun mi-in ti wọn tun n gba ni ki wọn ti awọn eeyan mọnu ile ki wọn si sọ ina si ile naa.

Awọn onimọ nipa aabo sọ pe ki i ṣe eeyan nikan ni wọn fi ilana yii pa, wọn tun maa n lo o lati da ibẹrubojo si aarin ilu ati abule.

Laipẹ yii, ninu ikọlu kan nipinlẹ Sokoto, awọn bandiiti pa eeyan mejila o kere tan, wọn si ji awọn ọmọde atawọn obinrin wọgbo lọ.

Awọn olugbe ibẹ sọ fun ẹka iroyin Reuters pe eeyan mẹfa ni wọn dana sun mọle ninu idile kan ṣoṣo, nigba ti awọn onikọlu naa ti wọn mọle ti wọn si sọ ina sile naa.

Lẹyin eyi ni wọn ji awon nnkan ọsin wọn atawọn dukia mi-in.

Bakan naa ni wọn ti lo ilana idanasunle yii ni Zamfara, Katsina ati ipinlẹ Kebbi, nibi ti wọn ti ji ọpọ eeyan kọ lẹyin ti wọn dana sunle, ja wọn lole.

Nigba mi-in si ree, wọn tun maa n dana sun ile awọn to ba kọ lati sanwo itusilẹ tabi awọn to ba gbiyanju ati sa lọ.

Riri ado oloro mọlẹ

Awọn bandiiti yii ti ṣe afikun ọna ti wọn n gba lo ado oloro loju ọna to wọ awọn ilu ati abule.

Eyi tumọ si pe bi ẹnikẹni ba gbiyanju ati sa lọ, tabi bi ẹṣọ alaabo to ba fẹ waa gba wọn silẹ ba gba ibẹ, yoo bu gbamu pa wọn.

Eyi naa tun maa n ba awọn araalu lẹru lati tete sa lọ lasiko ikọlu, nitori ẹru ado oloro to ṣee ṣe ki wọn farako nibi ti wọn ba ti n sa lọ yoo maa ba wọn.

Bakan naa lo maa n jẹ kawọn ẹṣọ alaabo paapaa pẹ ki wọn to debi ti ikọlu ti n waye.

Awọn agbesunmọmi ṣe bẹẹ lọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu Keje ọdun 2024, nigba ti wọn pa o kere tan, ṣọja meje lẹyin ti mọto wọn tẹ ado oloro mọlẹ loju ọna Monguno-Baga, ipinlẹ Borno.

Loṣu Kẹfa ọdun 2026, iroyin jade pe ṣọja mẹrin ku lẹyin ti ọkọ ti wọn fi n wọde fara ko ado oloro ti awọn agbebọn kẹ si oju ọna Bargaja, nijọba ibilẹ Isa, ipinlẹ Sokoto.

Iroyin sọ pe ibugbamu naa ba ọkọ awon ṣọja ọhun je kanlẹ lai ni atunṣe ni.

Kikọlu awọn adajọ

Lai ti i pe ọsẹ kan tan, awọn agbebọn kọlu adajọ meji lapa Ariwa Naijiria.

Wọn ji ọkan gbe, ori ko ikeji yọ nigba ti wọn yabo kootu ti igbẹjọ ti n waye.

Lọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Keje ọdun 2026, awọn ajinigbe ji Adajọ agba ipinlẹ Kebbi gbe, ẹni ti orukọ rẹ n jẹ Faruku Hassan. Ijọba ibilẹ Bunza ni wọn ti ji I gbe.

Iroyin sọ pe miliọnu lọna igba naira ( N200 million) ni wọn n beere fun itusilẹ rẹ.

Leyin ojo die ti won gbe adaio naa lọ ní wón tún yabo kóòtù Sharia kan ni Abule Gwarjo, ní Katsinsa. Wọn da ìbọn bolẹ wọn sì ń beere pe nibo ni Adajọ Muktar wa?

Àwọn onimo nípa ààbò gbagbọ pé ìkọlù tí wọn ń ṣe sáwọn Adajo yìí kì í ṣe nítorí owó itusile nìkan.

Wọn ní o ṣeé ṣe kó je lati deru bá wọn ní, kí wọn máa lé sise wọn mọ.

Omowe Kabiru Adamu, onimọ nipa eto aabo ṣàlàyé fun BBC pé àwọn bandiit lè máa jí àwọn Adajo gbé láti di wọn lowo ẹjọ́ tó kàn wọn, ki wọn má sì lè dajo kankan tó bá kan agbesunmomi nígbà tí ọwọ òfin bá tẹ wọn.

Dìdena de àwọn tó bá ń sá lọ lati pá won

Àwọn agbebon máa ń pín ara wọn sónà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, báwọn kan bá ń koju ìlú kan lọ́wọ́, àwọn kan a sá pamo sínú igbó láti mú àwọn tó bá gbìyànjú àti sá lọ.

Bi won bá ti fe sá lọ ní àwọn tó ti lúgọ de wọn náà yóò ra wọn mú.

Ninu òpó ìkọlù kaakiri Sokoto, Zamfara ati Katsina, àwọn aráàlú sọ pé nise ni àwọn agbebon náà di àwọn ojú ona táwọn lè gbà sá lọ kí wọn yóò wọlé wá rara, àwọn tó fẹẹ sá lọ bọ si wọn lọwọ ni bi wọn ṣe sọ