Kò sí gómìnà tó ní àṣẹ láti dá iṣẹ́ ẹgbẹ́ awakọ̀ NURTW dúró ní ìpínlẹ̀ rẹ̀ - NURTW ṣèkìlọ̀ fún Gómìnà Adeleke l'Osun

Oríṣun àwòrán, Musiliu Akinsanya Ayinde/Facebook
Ẹgbẹ awọn awakọ nilẹ Naijiria, ẹka ti NURTW, ti sọ pe ko si gomina ipijnlẹ kankan to ni aṣẹ lati da gbogbo iṣẹ wọn dur oni ipinlẹ rẹ labẹ ofin.
NURTW, ẹka ti Musiliu Akinsanya tọpọ mọ si MC Oluomo lo sọrọ yii lasiko ti wọn n bura fun igbimọ adele ẹgbẹ ti yoo ṣakoso ipinlẹ Osun.
Nibẹ ni wọn ti sọ pe igbesẹ Gomina Ademola Adeleke lati dawọ gbogbo iṣẹ NURTW nipinlẹ Osun ko ba ofin ati ilana ti wọn fi da ẹgbẹ wọn silẹ mu.
Igbakeji aarẹ apapọ ẹgbẹ NURTW, Aliyu Issa Ore lo sọ eyi di mimọ nibi to ti n bura fun awọn oloye fidihẹ tuntun naa.
Ore sọ pe awọn oloye tuntun yii ni yoo ṣakoso gbogbo iṣẹ NURTW nipinlẹ Osun titi digba ti wọn yoo fi yanju awọn aawọ to n ṣẹlẹ nibẹ.
Ninu ọrẹ rẹ, Ore jẹ ko di mimọ pe "Ijọba ipinlẹ Osun da gbogbo iṣẹ ẹgbẹ wa duro nipinlẹ Osun, eyi to jẹ pe wọn ko ni agbara naa.
"Ko si gomina ipinlẹ kan to ni agbara lati da iṣẹ NURTW duro ni ipinlẹ rẹ, nitori pe a ko si labẹ ipinlẹ kankan. A ni iwe ofin to dẹgbẹ yii silẹ."
"Ọ̀pọ ẹjọ́ la borí"
Siwaju sii lo fi kun ọrọ rẹ pe ọpọ awọn ipinlẹ ni awọn tig be lọ sile-ẹjọ, lori bi wọn ṣe n da iṣẹ wọn duro, to si lawọn bori nile-ẹjọ.
O ni awọn ipinlẹ Oyo, Eko ati awọn miran ni awọn ti wọ lọ sile-ẹjọ, latari bi wọn ṣe foju tẹmbẹlu ẹgbẹ awọn, ṣugbọn ti awọn gba idalere.
"Ọpọ ẹjọ yii la ti bori nile-ẹjọ. Mo mọ ti ipinlẹ Oyo, Eko, ati ọpọ ipinlẹ. Wọn kọ eti ikun si ẹbẹ wa. Ṣugbọn iyẹn nikan kọ, ọrọ to wa nilẹ yii yatọ.
"Ohun to jẹ wa logun ni lati ni awọn olori wa, ki wọn wa ni ijokoo. Nitori eleyii, a ni lati gbe igbimọ iṣakoso adele dide lati maa ṣakoso ẹgbẹ NURTW, titi digba ti a maa fi yan gbogbo ohun to n ṣẹlẹ l'Osun."
Àwọn wo ló wà nínú ìgbìmọ̀ adelé yìí?
Igbakeji aarẹ naa tẹsiwaju pe awọn ti pinuu lati gbe igbimọ ẹlẹni meje ti yoo jẹ adele dide lati ri si gbogbo rogbodiyan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ NURTW nipinlẹ Osun.
"Awọn wọnyi ni wọn yoo maa ṣakoso ẹgbẹ NURTW nipinlẹ Osun lati asiko yii lọ: Alaga ni Kazeem Oyewale; Lukmon Hammed ni akọwe; nigba ti Ismaila Abdruraheem, Adebayo Tajudeen, ati Tajudeen Akeem ni yoo jẹ ọmọ ẹgbẹ," Ore fidi rẹ mulẹ.
Bakan naa lo tun sọ pe awọn yoo ṣi tẹsiwaju lati maa lo ẹni to jẹ akọwe ẹgbẹ naa tẹlẹ nipinlẹ Osun, nitori pe o fara mọ igun awọn.
"Ahbdulwahab Maruf Dodo ni yoo jẹ igbakeji akọwe fẹgbẹ. A ni akọwe tẹlẹ nipinlẹ Osun, bẹẹ lo si jẹ ọmọluabi si ẹgbẹ, orukọ rẹ ni Kọmureedi Sunday Bunmi Oludare."
"A kò rí alága NURTW ní ìpínlẹ̀ Osun"
Nigba to n ṣe ibura fun awọn oloye adele tuntun ọhun, Frank Uchehara to jẹ akọwe agba fun ẹgbẹ NURTW sọ pe awọn ni lati gbe igbesẹ lati di alafo to ṣi silẹ nipinlẹ Osun.
O fi kun ọrọ rẹ wi pe nigba ti awọn ṣabẹwo si ipinlẹ Osun lati mọ ohun to n ṣẹlẹ, awọn ko ri alaga nibẹ lati yọju si wọn.
"A pade ni olu ileeṣẹ ẹgbẹ wa to wa nipinlẹ Osun, a ko si ri alaga ipinlẹ naa titi di asiko yii. Gẹgẹ bi igbimọ alakoso agba, ati ni ibamu pẹlu ofin ẹgbẹ wa, aaye kankan ko gbọdọ ṣofo," Uchehara sọ bẹẹ.
O tẹsiwaju pe, "Fun idi eyi, mo n lo anfaani yii, pẹlu agbara to wa ni ikawọ mi, lati yan igbimọ adele fun ẹgbẹ wa nipinlẹ naa, titi di digba ti ọrọ to wa nilẹ yoo fi ni iyanju.
"Lorukọ aarẹ ẹgbẹ wa, Alaaji Musiliu Akinsanya Ayinde, MC Oluomo, ati akọwe agba, Komureedi Kayode Agboyagi, ti wọn ko si nibi lasiko yii lati bura fun un yin.
"Mo si n ṣe eyi niwaju igbakeji aarẹ wa, Isa Ore to n ṣoju aarẹ wa lapapọ lati bura fun igbimọ ẹlẹni meje ti yoo ṣakoso ẹgbẹ NURTW nipinlẹ Osun fun igba diẹ," O kadi ọrọ rẹ nilẹ.
Awọn alakoso agba naa wa gba igbimọ adele tuntun yii lamọran lati gba alaafia laaye nipinlẹ Osun, ki wọn si wa iyanju si gbogbo laasiko to n waye ninu NURTW nipinlẹ Osun.


























