A ò fẹ́ irú àjọṣepọ̀ tí ò ń bèèrè fún – Àwọn gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlù APC kẹyìn sí Fayose lórí ìbò 2027

Oríṣun àwòrán, Hope Uzondima/Nyesom Wike/Facebook
Faakaja laarin awọn gomina ẹgbẹ oṣelu APC ati minisita Abuja, Nyesom Wike, lori siṣe atilẹyin fun Aarẹ Bola Tinubu ninu ibo ọdun 2027 ti gba ọna mii yọ lẹyin tawọn gomina tako agbekalẹ eto ajọṣepọ laarin laarin ẹgbẹ oṣelu APC ati ẹgbẹ oṣelu PDP to jẹ igun Wike eyi to pe ni ''Rainbow coalition.''
Awọn gomina APC fẹnu ko nibi ipade ti wọn ṣe l'Abuja wi pe irufẹ ajọṣepọ ti Wike gbe kalẹ yii le ṣakoba fun Tinubu ninu ibo aarẹ ọdun 2027, o si le jẹ ko lulẹ.
Ti ẹ o ba gbagbe, ọpọ awọn oludije to fidirẹmi ninu ibo abẹnu APC lo ti darapọ mọ igun Wike ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nibi ti wọn ti lanfaani lati di oludije sipo oṣelu kan tabi omiran.
Fàákája láàrin Wike àtàwọn Gómìnà APC lórí ọ̀rọ̀ Tinubu gbọ̀nà míì yọ, àlàyé rèé lórí ohun tó tún sẹlẹ̀

Oríṣun àwòrán, Hope Uzodinma/X
Lara awọn oludije bẹẹ ni Isa Pantami to wa ni APC tẹlẹ to jẹ minisita ibaraẹnisọrọ tẹlẹ, ẹni to ti di oludije sipo gomina bayii labẹ asia ẹgbẹ PDP nipinlẹ Gombe.
Amọ, Hope Uzodinma to jẹ alaga awọn gomina APC kede wi pe awọn ko da ohunkohun pọ pẹlu Wike lori eto ajọṣepọ to gbe kalẹ.
Uzodinma ni iru eto bayii yoo da wahala silẹ ninu ẹgbẹ, o si tun le ṣakoba fun APC ninu eto idibo ọdun 2027.
''Ẹgbẹ awọn gomina ti pinnu wi pe a o ni kopa ninu ajọṣepọ kankan pẹlu ẹnikẹni, ti kii ba tii ṣe oludije APC.
Ajọṣepọ to ba yatọ si eyi yoo da eto ẹgbẹ ru, yoo si da rukerudo silẹ.
Gbogbo ajọṣepọ ti a ba fẹ ṣe ninu ẹgbẹ ni lati wa ni ibamu pẹlu erongba aarẹ ati ti ẹgbẹ oṣelu APC,'' Uzodinma lo sọ bẹẹ.
Mo n ṣatilẹyin fun Aarẹ Tinubu loootọ lati wọle saa keji, amọ, n ko ṣeleri pe maa fawọn oludije ẹgbẹ PDP silẹ – Wike
Ẹwẹ, Wike tun ti ṣalaye wi pe oun yoo ṣatilẹyin fun Tinubu lati wọle saa keji ninu ibo aarẹ ọdun 2027.
Amọ, Wike ni oun o ṣeleri pe oun ko ni gbaruku tawọn oludije sipo gomina, ile aṣofin agba l'Abuja ati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP.
Minisita Abuja sọ pe Aarẹ Tinubu gan an mọ nipa ajọṣepọ laarin APC ati PDP eyi toun pe ni ''Rainbow Coalition.''
Wike wa sọ pe Aarẹ Tinubu loun ba da owo pọ kii ṣe awọn gomina APC.
Nigba to n sọrọ lori ẹrọ amohunmaworan Arise TV, Wike ṣalaye wi pe oun ko buwọ lu iwe adehun lori ajọṣepọ pẹlu awọn gomina APC.
Bakan naa lo ni oun ko bawọn gomina APC ṣepade pọ ri.
Minisita Abuja fikun ọrọ rẹ pe boun ti n ṣatilẹyin fun Tinubu ko tumọ si pe oun ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC.
''Mo ti sọ tẹlẹ wi pe ko si nnkan ti mo n ṣe ti Aarẹ Tinubu ko mọ si.
Lọdun 2023, a pinnu pe Tinubu la o tẹle tori o wa lati ẹkun guusu Naijiria.
Nigba tawọn gomina G5 jade lati ṣatilẹyin fun Aarẹ Tinubu, wọn o ṣe ipade kankan pẹlu awọn gomina APC nigba naa.
A ṣepade pẹlu Tinubu, nibẹ ni a ti sọ fun un wi pe oun la o ṣe atilẹyin fun,'' Wike lo sọ bẹẹ.
''Bi Wike ti n ṣe ẹgbẹ APC ati PDP pọ le ṣakoba fẹgbẹ mejeeji''
Onimọ nipa eto oṣelu kan, Ọjọgbọn Abubakar Kari, ti sọ pe bi Wike ti n ṣe ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP papọ le ṣakoba fun ẹgbẹ mejeeji.
Ọjọgbọn Kari sọ pe bi Wike ṣe n ṣatilẹyin fun Tinubu ti o si tun n gbaruku ti awọn oludije sipo mii ninu ẹgbẹ PDP le da nnkan ru ninu ẹgbẹ APC.
Onimọ nipa ọrọ oṣelu naa sọ pe bi Wike ti n ṣatilẹyin fawọn oludije sipo kan nipinlẹ Kwara ati Gombe yoo jẹ koun atawọn gomina APC tako ara wọn bo tilẹ jẹ pe o n ṣatiléyin fun Tinubu.
Ọjọgbọn Kari ni nnkan ti Wike n ṣe tako ilana eto oṣelu tori o n ṣatilẹyin fawọn oludije ẹgbẹ PDP nigba to n gbaruku ti Tinubu to jẹ oludije sipo aarẹ fẹgbẹ APC.
O ni nnkan ti Wike n ṣe tako ofin ati ilana ẹgbẹ oṣelu.
Ọjọgbọn naa sọ pe bi Wike ṣe n ṣatilẹyin fawọn oludije kan ninu ẹgbẹ PDP nigba to si n gbaruku ti Tinubu tumọ si pe o n kopa ninu eto to tako ofin ati ilana ẹgbẹ oṣelu APC.



























