Ọọ̀ni fi N100m, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ta Sunday Igboho lọ́rẹ láti ṣe àtìlẹyìn fún ikọ̀ aláàbò Ìru Ẹkùn

Oríṣun àwòrán, Inside Ile-Ife/Facebook
Lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii ni Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyeye Enitan Ogunwusi ṣeleri owo ti ko din ni ọgọrun kan miliọnu naira, lati fi ṣatilẹyin fun ileeṣẹ eleto aabo ibilẹ to [da silẹ, Iru-Ẹkun fun aabo ẹmi ati dukia ọmọ kaarọ-o-jiire.
Yatọ si owo ti Ọba Adeyeye, Arole Oodua fi ta Iru Ẹkun lọrẹ yii, kabiyesi naa tun gbe ọkọ bọọsi bọginni, Toyota Hilux silẹ lati fi ran iṣẹ eto aabo ibilẹ naa lọwọ.
Oloye Sunday Adeniyi Adeyemo tọpọ awọn eeyan mọ si Sunday Igboho lo da ileeṣẹ eleto aabo Iru Ẹkun naa silẹ lati fi ṣatilẹyin fun eto aabo kaakiri ilẹ Yoruba, paapaa awọn inu igbo lati ẹnubode ilu kan si ekeji.
Ọjaja Keji tun ṣeleri atilẹyin nla fun Sunday Igboho lori Iru Ẹkun, to si loun yoo kan si gbogbo awọn alẹnulọrọ kaakiri ilẹ Yoruba lati dide atilẹkun fun wọn pẹlu.
Irọlẹ ọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii ni Ọọni ṣe awọn ileri yii, lasiko ti Sunday Igboho lọ ṣabẹwo si kabiyesi laafin lori idi pataki to fi da ileeṣẹ eleto aabo naa silẹ.
Ninu atẹajde ti akọwe iroyin Ọọni, Sodiq Lawal fi sita lẹyin ipade naa, lo ti sọ pe idunnu nla ni ileeṣẹ eleto aabo naa jẹ fun kabiyesi.
"Ọọni gbe oṣuba kare fun Oloye Sunday Igboho fun igboya, ifarada ati ifarajin sori ọrọ eto aabo ati igbayegbadun ọmọ Yoruba, to si tọka sii pe ọna to gba fara si iṣẹ isin ilu jẹ pataki idagbasoke," atẹjade naa sọ bẹẹ.
Gẹgẹ bi Ọọni tun ṣe sọ siwaju, o ni gbogbo ọmọ Oduduwa patapata lo ni ojuṣe ati ẹtọ sọrọ alaafia, iṣọkan ati aṣeyọri ilẹ Yoruba, nitori pe eto aabo nikan ni ipilẹ ti idagbasoke ati ilọsiwaju le fi gbooro.
Kabiyesi ni owo naa kii ṣe pe oun kan fi ti Igboho siwaju lasan, bi ko ṣe pe oun naa fẹẹ ṣafihan ifarajin oun lati polongo alaafia, ifẹ ati aabo gbogbo iran Yoruba lapapọ.
"Mo gbe oṣuba kare fun Sunday Igboho pẹlu bo ṣe n fi akikanju ṣe gbogbo ohun to n ṣe, to n daabo bo awọn eeyan wa, lai wo ti oṣelu tabi ẹya.
"Gbogbo agbekalẹ lati daabo bo ẹmi ati dukia, pẹlu igbelarugẹ fun alaafia araalu la gbọdọ maa ṣatilẹyin fun," Ọọni sọ bẹẹ.
Igboho dupẹ
Igboho, nigba toun naa n dupẹ ni " Mo ki Ọlọrun ọba to ni aye ati ohun gbogbo.
Mo si ki baba mi Ọọni, ki Ọlọrun jẹ ka ri wọn pẹ.
Mo sọ lọjọ kan wi pe Ọlọrun lo ran Ọọni si wa lati jẹ olori gbogbo ọmọ Oduduwa.
"Baba jọ mi loju loni, ẹru tun ba mi. Kabiyesi tun ni ki wọn ṣilẹkun fun gbogbo awọn ti a jọ wa.
A ti n jẹ Ọọni, eleyi tun yatọ. Gbogbo ojumọ aye ni baba mi sọ fun mi pe Ọọni maa n ṣe etutu fun gbogbo ọmọ Yoruba lati ni alaafia ati iṣọkan," o sọ bẹẹ.
O wa fi ẹmi imoore rẹ han si Arole Oduduwa, to si ṣeleri pe oun ko nii jọ ara oun loju, ati pe gbogbo kọlọrọsi to ba fẹẹ da omi alaafia ilẹ Yoruba laamu lawọn yoo ran pada sibi ti wọn ti wa.





























