EFCC gbẹ́sẹ̀ lé àpò ìkówósí ìjọba Osun, Adeleke ní kóòtù yóò bá àwọn dà a

Alaga EFCC,Ola Olukoyede lapa osi, Gomina Ademola Adeleke lapa ọtun.

Oríṣun àwòrán, EFCC/Gov. Ademola Adeleke/FB

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Bi idibo sipo gomina ipinlẹ Osun sẹ ku ọjọ mẹwaa lonii, iroyin to gbode ni pe ajọ EFCC to n ri si ajẹbanu ti gbẹsẹ le apo ikowosi ijọba ipinlẹ naa.

Gẹgẹ bi a ṣe fidi ẹ mulẹ lẹyin ti Gomina Ademola Adeleke ba awọn akọroyin sọrọ l'Ọjọru nibi ipade oniroyin l'Osogbo, asunwọn ti wọn fi n san owo oṣu awọn oṣiṣẹ ni EFCC gbe ote le.

Wọn ko le gba owo jade nibẹ, wọn ko le lo kaadi ATM, bẹẹ ni wọn ko le fi ọna kankan gba owo jade lati ibẹ.

Igbesẹ n waye lẹyin wakati diẹ ti gomina Ademola Adeleke kede pe EFCC n pete ati fi ofin de akanti ijọba Osun ati tawọn lọgalọga nipinlẹ naa.

Ile ẹjọ giga Osogbo yoo ba wa da a- Gomina Adeleke

Ninu ọrọ rẹ nibi ipade oniroyin naa, Gomina Ademola Adeleke sọ pe owurọ oni Ọjọru, ọjọ karun-un oṣu Keje 2026 ni oun gba iwe kan lati ọdọ ajọ EFCC, eyi to ka pe wọn ti fofin de apo ikowosi ijọba ipinlẹ Osun.

Gẹgẹ bi Gomina Adeleke ṣe wi:

" Gbogbo yin lẹ mọ bi rogbodiyan ṣe n waye nipinlẹ Osun lati bii oṣu meloo sẹyin, ti wọn n pa awọn eeyan ipinlẹ Osun, ti wọn n yinbọn niluu, ti wọn n ko awọn ọmọ ẹgbẹ Accord lai mu ẹgbẹ alatako kankan.

"Ẹ mọ bi wọn ṣe da oju ijọba ibilẹ bolẹ pẹlu.

"Won ti pa ọpọ ọmọ egbẹ Accord, wọn ti awọn mi-in mole l'Abuja lai si iwe aṣẹ imuni kankan.

"Gbogbo ikọlu yii n waye pẹlu aṣẹ Gboyega Oyetola, lori ibo ti oludije re ko le bori.

"Aarọ oni ni a tun gba lẹta ti EFCC fi gbẹsẹ le apo ikowosi ijọba ipinlẹ Osun, amọ a o ni i gba iru ẹ laye.

"Won ko fi to kootu leti ti won fi fi leta ohun ranse, a o ni i dake ki won se ohun ti ofin ko faaye gba fun wa."

Gomina Adeleke sọ pe idunkooko mọ ijọba demokresi ni iru iwa yii, boun ba si gba ko lọ bẹẹ, iwọnba to ṣẹku ninu demokresi naa ni wọn yoo tun tẹ loju mọlẹ.

"Emi o beere nnkan mi-in, ju ki Alaga EFCC ṣalaye fawọn eeyan ipinlẹ Osun ati gbogbo ọmọ Naijiria lapapọ, idi ti wọn fi gbẹsẹ le asunwọn ijọba, ko si fi idi eri re han kawọn eeyan ri i.

"Yatọ si eyi, mo ti paṣẹ fun Olootu idajọ nipinlẹ Osun lati gbe ọrọ naa lọ sile ẹjọ giga ilu Osogbo, kootu yoo ni lati ba wa da a."

Asunwọn ti wón ti n sanwo awọn tiṣa, oṣiṣẹfẹyinti, ilera atawọn mi-in ni EFCC gbẹsẹ le, Adeleke ko si nawo ijọba polongo ibo- Olootu idajọ Osun

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Amofin Jimi Bada, Olootu eto idajọ nipinlẹ Osun, ṣalaye ni tiẹ pe igbesẹ to lodi labẹ ofin ni EFCC gbe.

O ni wọn ko lẹtọọ labẹ ofin lati gbẹsẹ le apo ikowosi ijọba ipinlẹ rara.

" Apo ikowosi tijọba fi n sanwo oṣu oṣiṣẹ bii tiṣa, ijoba ibilẹ, tawọn oṣiṣẹfẹyinti, ti ilera, eto ẹkọ atawọn mi-in ni wọn gbẹsẹ le.

Eyi ko yẹ ko ri bẹẹ, nitori owo to wa fun iṣejọba ati fun araalu ni wọn gbẹsẹ le yẹn.

"Gomina Adeleke ko lo owo ijọba polongo ibo, o tun fi owo rẹ sanwo ijọba ibilẹ ni.

"Abala 24 ati 38 ofin to de owo nina ko fi aaye gba igbesẹ yii, eyi ni Gomina ṣe paṣẹ fun mi lati gbe ọrọ naa lọ si kootu."

Olootu idajọ Osun naa sọ pe ki I ṣe ọrọ ija, bẹẹ ni ijọba Osun bọwọ fun ẹka ijọba bi EFCC.

O ni ṣugbọn ile ẹjọ ni awọn yoo pada si, ki kootu ṣalaye idi ti EFCC yoo fi gbẹsẹ le asunwon ijọba.

Jimi Bada fi kun un pe ki araalu fi ọkan balẹ, ki won reti abọ kootu lai ṣiyemeji.

O ni ifẹ ti wọn ni si Adeleke yoo gbe e de ipo naa bo ti wu ki atako pọ to.