Ìjọba Nàìjíríà, Atiku kẹ́dùn ikú Olu Jacobs

Oríṣun àwòrán, Others
Ijọba Naijiria ti kọrin aro lẹyin awọn agba ọjẹ ninu iṣẹ tiata, Olu Jacobs to jade laye lẹni ọdun mẹrinlelọgọrin (84).
Atẹjade ti agbẹnusọ Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu, Bayo Onanuga fi sori ikanni X rẹ juwe agba oṣere naa bi ẹni ti iṣẹ rẹ kọja ṣiṣe fiimu nikan.
Tinubu ni Olu Jacobs lo imọ ati iriri rẹ lati fi mu idagbasoke ba ẹka ere idaraya eyi to jẹ ọpakutẹlẹ tawọn oṣere ode oni n lo gẹgẹ bi awokọṣe.
Atẹjade kan ti Minisita fun ọrọ aṣa ati Inaju, Hannatu Musawa fi lede juwe iku eekan onitiata naa bii adanu nla si ẹka ere fiimu ni Naijiria.
O woye pe bii aadọta ọdun ni Olu Jacobs fi kopa ribiribi nidii iṣe tiata, to si jẹ pe awọn ipa rẹ nidii iṣẹ naa ko kere rara.
Atẹjade ti agbẹnusọ Minisita naa, Nneka Anibeze fi lede sọ pe ọkan lara awọn ọpakutẹlẹ to gbe ẹka ere idaraya Naijiria ni Olu Jacobs je, ti wọn yoo si ṣafeku rẹ lagbo ere tiata.
Ninu ọrọ tirẹ, Minisita feto irinna oju ofurufu, Festus Keyamo ni agba ọje to ṣe e wo ni awokọṣe ni Keyamo jẹ, ti ipa rẹ ninu iṣẹ tiata kii ṣe ohun to ṣe e fọwọ rọ sẹyin rara.
Keyamo ninu atẹjade to fi soju opo X rẹ gbadura ki Eledumare tẹ Olu Jacobs si afẹfẹ rere.
Bakan naa ni oludije sipo aarẹ Naijiria lẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC, Atiku Abubakar ninu atẹjade to fi soju opo X rẹ ni ibanujẹ ni gbigbọ iku Olu Jacobs mu ba oun.
Atiku woye pe ṣaaju ni ki ere sinima Naijiria to di ohun ti gbogbo aye mọ ni Olu Jacobs ti n gbe ogo Naijiria ga pẹlu awọn ere tiata, to si wa lara awọn ti wọn ṣeto ipilẹ tawọn oṣere tuntun asiko yii n gunle.
Igbakeji aarẹ Naijiria tẹlẹ ri naa wa ba iyawo oloogbe, Joke Silva ti oun naa jẹ agba oṣere atawọn ọmọ oloogbe kẹdun.
O ni oun gbagbọ pe wọn yoo mu ọkan akin lori adanu wọn yii paapaa ti wọn ba ranti awọn ohun meremere ti wọn ti jọ gbe ṣe nigba aye e rẹ.
Awọn oṣere tiata kan saara si igbe aye Olu Jacobs
Yatọ si awọn eekan ilu wọnyii, awọn oṣere naa n kọrin aro lẹyin ẹni wọn to lọ irinajo aremabọ, ti wọn si n kan saara si iṣẹ trakuntakun to ṣe lagbole tiata nigba to wa laye.
Funke Akindele kọ wi pe ki Ọlọrun tẹ oloogbe si afẹfẹ rere.
Ini Edo ni tirẹ sọ pe didun ni iranti olododo, ti awọn ko si gbagbe rẹ laelae.
Williams Uchemba kọ soju opo rẹ pe Olu Jacobs gbe igbe aye rere, to si gbadura ki Ọlọrun ṣe iku ni isinmi fun-un.
Bukky Wright sọ pe ipa rere ti agba oṣere naa fi lelẹ ko le parẹ laelae paapaa lọkan awọn to nifẹẹ ere idaraya.
Bakan naa ni ọmọ ṣe ṣori bi Kehinde Bankole naa ṣe sọ pe Olu Jacobs gbe igbe aye rere.
Wo kókó mẹ́fà tó yẹ kí ò mọ̀ nipa Olu Jacobs, àgbà òṣèré tó lọ sinmi

Oríṣun àwòrán, Olu Jacobs/Instagram
Odu ni gbajugbaja agba oṣere nni, Oludotun Baiyewu Jacobs, kii ṣaimọ f'oloko, paapaa lagboole oṣere tiata nilẹ Naijiria, ati lagbaye.
Oludotun Jacobs, tọpọ awọn eeyan tun mọ si Olu Jacobs wa lara awọn to sọ iṣẹ di irọrun kaakiri ilẹ Naijiria.
Aarọ Ọjọru, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan an, ọdun 2026 ni awọn mọlẹbi Olu Jacobs kede ipapoda rẹ.
Bo tilẹ jẹ pe mọlẹbi naa ko sọ ẹkunrẹrẹ nipa ohun to ṣokunfa agba oṣere nni yii, sibẹ, ohun ti ọpọ awọn eeyan nigbagbọ ni pe aisan to nii ṣe pẹlu ọjọ ogbo ni.
Tani Olu Jacobs?
Ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun 1942 ni wọn bi Olu Jacobs.
Ọmọ bibi ilu Abeokuta ni ipinlẹ Ogun ni baba ati iya rẹ, ṣugbọn ipinlẹ Kano lo ti ṣe kekere rẹ, to si lọ sile ẹkọ Holy Trinity nibẹ.
Gbara ti Olu Jacobs ti de ile-ẹkọ naa lo ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣere ti awọn akẹkọ nibẹ.
Lasiko to wa nibẹ, Olu Jacobs ni anfaani lati kopa ninu ere ori itage ti Hubert Ogunde lọ ṣe nipinlẹ Kano, iyẹn nile itura Colonial.
Ilu Kano naa ni Jacobs ti ri anfaani lati lọ siluu oyinbo, iyẹn orileede England, lati kẹkọọ nipa ere ori itage.
Nibẹ lo ti darapọ mọ ile-ẹkọ The Royal Academy of Dramatic Arts niluu London. Ọkan lara awọn ipa to ko nigba naa ni 'The Boy', ninu ere 'A Taste of Honey' ni ile aworan Crucible Theatre to wa ni Sheffield lọdun 1972.
Oniruuru sinima agbelewo ni Olu Jacobs kopa ninu rẹ bii 'The Goodies', 'Till Death Do Us Part', 'Below at Large', ati awọn miran ti a ko le mẹnuba tan nigba to wa ni England.
Àwon fiimu miran wo lo tun ti kopa?
Lọdun 1980s, Jacobs kopa ninu sinima agbelewo agbaye lọpọlọpọ bii ti John Irvins, The Dogs of War, Roman Polanski, Pirate, Baby: Secret of the Lost Legend, to fi mọ awọn miran.
Lẹyin ọpọlọpọ iṣẹ takuntakun ti Olu Jacobs ti ṣe ni England, o pinnu lati pada si Naijiria, lati lo awọn ọgbọn, ẹbun ati imọ rẹ ninu idagbasoke iṣẹ tiata nilẹ Naijiria.
Ipa to jọju ni Jacobs ko ninu ere ori itage ọlọsẹ-ọsẹ ti ileeṣẹ amohunmaworan NTA ṣagbatẹru rẹ, 'The Third Eye', nigba to de lọdun 1990.
Ko lonka ni awọn ere oritage ati sinima agbelewo ti Olu Jacobs kopa ninu rẹ nilẹ Naijiria, to si wa lara awọn agba ọjẹ ninu idasilẹ Nollywood.
Nibi iṣẹ tiata ti Olu Jacobs n ba kaakiri, lo ti pade akẹgbẹ rẹ, obinrin, toun naa jẹ gbajugbaja oṣere tiata, Joke Silva.
Ọdun 1989 ni awọn mejeeji di lọkọlaya nipa igbeyawo alarinrin ti wọn ṣe.
Adedaa fun awọn mejeeji ni ọmọ ọkunrin meji ninu igbeyawo wọn, ti wọ si gbe papọ ninu irẹpọ ati alaafia titi t'ọlọjọ fi de.
Ọpọ igba ni awọn eeyan ti sọrọ nipa igbeyawo mejeeji, paapaa bi Joke ṣi ṣe n jẹ orukọ baba rẹ tii ṣe 'Silva', ṣugbọn ti baba naa sọ pe oun ko ri nnkan to buru nibẹ.
Jacab sati iyawọ rẹ, Joke da ẹgbẹ kan ti wọn pe ni 'Lufodo Groups' silẹ, eyi ti wọn fi n ṣe igbelarugẹ fun iṣẹ tiata ati pinpin dukia, bẹẹ ni wọn tun da Lufodo Academy of Performing Arts silẹ.
Ààmì ẹ̀yẹ
Oniruuru aami ẹyẹ ti ko lonka ni agba oṣere yii ti gba nilẹ Naijiria ati kaakiri agbaye, lori awọn ipa manigbagbe to ti ko lagboole tiata.
Lara rẹ ni ti aami ẹyẹ idalọla ti ilẹ Naijiria, MFR ti Aarẹ tẹlẹri, Goodluck Ebele Jonathan fun un lọdun 2011.
Aami ẹyẹ idalọla yii ko waye lasan, wọn tun ṣa ayẹyẹ nla fun un, lati fi mọ riri ipa ribiribi to nidi iṣẹ tiata nilẹ Naijiria.
Yatọ si eyi, Jacobs tun gba aami ẹyẹ ayeraye ti ileeṣẹ Afriff fi da a lọla niu oṣu Kọkanla, ọdun 2021.
Jacobs gba aami ẹyẹ AMVCA lọdun 2013; AVRS lọdun 2022 to fi mọ awọn miran.
Iye ìgbà tí wọ́n ti kéde ikù rẹ̀
2020
Ọpọ igba ni iroyin ti jade nipa iku agba oṣere naa, ṣugbọn ti awọn mọlẹbi n sọ pe irọ to jinna si otitọ ni.
Ọdun 2020 ni iroyin naa kọkọ jade sori ayelujara.
Awọn ori ẹrọ ayelujara bii 'X' ati Facebook ni awọn oniroyin pajawiri ti tan iroyin naa ka, lati ṣi awọn eeyan lọkan.
Loju ẹsẹ ni awọn mọlẹbi ti figbe ta wi pe iroyin ẹlẹjẹ lasan ni, nitori pe ko si otitọ kankan nibẹ.
2021
Bakan naa, lọdun 2021, awọn eeyan tun gbe iroyin naa sita wi pe agbara naa, Olu Jacobs ti ki aye pe o digboṣe.
Ọhun ti wọn sọ nigba naa ni pe Jacobs jade laye lẹyin aisan rampẹ to ba a finra.
Ṣugbọn loju ẹsẹ ni iyawo rẹ, Joke Silva ti bọ sita wi pe ko si otitọ kankan nibẹ, ati pe ki awọn eeyan dẹkun titan iroyin tik ii ṣe otitọ nipa ọkọ oun ka.
Joke Silva sọ pe lotitọ ni Jacobs n ṣaisan, ṣugbọn aisan to nii ṣe titete gbagbe nnkan lo n ṣe e, ati pe o ti n gba itọju.
2022
Ko tan sibẹ, lodun 2024 ni iroyin ọhun tun gba ori ayelujara wi pe Olu Jacobs ti ta tẹru nipa a.
Awọn mọlẹbi ko jẹ ki iroyin pajawiri ori ayelujara naa balẹ, ti wọn fi gbe fọnran oṣere naa sita, nibi ti wọn ti n ge irun ori rẹ.
Ninu fọnran naa ni wọn tun ti ṣafihan bi Olu Jacobs ṣe n dunnu.
2024
Eyi to buruju ninu awọn iroyin ẹlẹjẹ naa ni ti eyi to gba ori ayelujara lọdun 2024.
Asiko yii lo si bi awọn mọlẹbi Jacobs ninu, to fi mọ iyawo lati gbe ikilọ nla jade sita f'awọn oniroyin pajawiri ori ayelujara.
Lọdun naa, Joke Silva sọ pe bi awọn oniroyin ori ayelujara ko ba jawọ nipa gbigbe iroyin ẹlẹjẹ sita nipa mọlẹbi wọn, awọn yoo foju wọn winna ofin.
Àgbà òṣèré nnì, Olu Jacobs jadé láyé

Oríṣun àwòrán, mrjacobs_jnr/Instagram
Laaarọ oni, Ọjọru, ọjọ kẹridinlogun, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 ni awọn mọlẹbi gbajugbaja agba oṣere nni, Oludotun Baiyewu Jacobs wi pe baba naa ti dagbere faye.
Oludotun Jacobs, tọpọ awọn eeyan mọ si Olu Jacobs lo jade laye lẹni ọdun mẹrinlẹlọgọrin.
Ọkan lara awọn ọmọ oloogbe naa 'mrjacobs_jnr', lo fidi iroyin iku Olu Jacobs mulẹ lori ikanni ayelujara ti Instagram ni nnkan bi agogo mẹsan kọja iṣẹju mẹtadinlọgbọn, aarọn oni.
Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, Jacobs Junior sọ pe baba awọn jade laye lẹyin igbe aye rere to ti lo.
"Pẹlu idupẹ si Ọlọrun fun igbe aye rere ati ijakadi, la fi n kede ipapoda ọkọ wa ọwọ, baba wa, baba-baba ati ẹgbọn wa. Kiniun Lufodo.
"Oludotun Baiyewun Jacobs (MFR) – 11/07.1942- 16/09/2026."
Mọlẹbi naa wa rọ gbogbo awọn akọroyin ori ayelujara ati awọn gbajumọ lori ayelujara lati bọwọ fun mọlẹbi nipa iroyin ti wọn yoo maa gbe jade lasiko yii.
"A rọ gbogbo awọn oniroyin ori ayelujara ati awọn gbajumọ ori ayelujara lati bọwọ fun afipamọ mọlẹbi wa lasiko yii," mọlẹbi naa sọ bẹẹ.



























