Wo ìpínlẹ̀ 15 tí ìjọba àpapọ̀ kìlọ̀ pé yóò kojú ẹ̀kún omi fọ́jọ́ méje ní Naijiria

Omi gba gbogbo agbegbe kan ninu aworan yii, awọn ọkọ to ri wa nibẹ rì

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba apapọ Naijiria lati ọdọ ajọ to n ri si ẹkun omi lorilẹede yii,Nigeria Hydrological Service Agency, (NiHSA), ti kilọ pe ẹkun omi yoo ṣẹlẹ lawọn ipinlẹ mẹẹẹdogun kan lorilẹede yii ninu ọsẹ yii, afi kawọn olugbe ibẹ tete wa ibomiran lọ.

Ọga agba ajọ NiHSA, Umar Mohammed lo kede bẹẹ.

Omiyale ọhun ni NiHSA kede pe yoo bẹrẹ lati ọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹsan-an ọdun 2026 yii, yoo si wa bẹẹ titi di ọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu kan naa.

Nipa ohun ti yoo fa ẹkun omi yii, ajọ naa sọ pe akunju awọn odo ni.

Bi ẹkun omi yii ba waye, ẹgbẹrun mẹjọ agbegbe ati ile ẹkọ to din diẹ lẹgbẹrun marun-un (4,500) ni ajọ naa sọ pe yoo kan.

Àwọn ipinlẹ ti wọn ni yoo kan

Gẹgẹ bi NiHSA ṣe kede, awọn ipinlẹ ti ẹkun omi naa yoo kan ni:

Imo, Cross River, Delta, Ebonyi, Benue, Anambra, Akwa Ibom, Edo, Enugu, Bayelsa, Kogi, Abia, Taraba, Rivers ati Eko.

Bi ẹkun omi naa ba ṣẹlẹ, Mohammed sọ pe awọn ibi ti yoo kan ju ni ile ẹkọ, ile iwosan, ọja, oko, awọn ile ijọsin ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O rọ ijọba awọn agbegbe yii lati tete ṣeto bi wọn yoo ṣe ko awọn eeyan to ba n gbe ni agbegbe ti ẹkun omi naa le kan kuro.

Atupalẹ awọn ibi ti ẹkun omi naa yoo de

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Eko: Eti-Osa, Lagos Island, Oke-Ira Nla (Ajah), Kirikiri Sea Port, Ilaje Waterfront Jetty ati Jetty Terminal B .

Bakan naa ni wọn kilọ fawọn ti Isheri North, Kara, Itowolo, Ajegunle, Majidun, Ogolonto ati apa kan Agboyi.

Kọmiṣanna eto ayika ati omi nipinlẹ Eko; Tokunbo Wahab, rọ awọn eeyan to n gbe lawọn agbegbe yii lati tete kuro nibẹ.

Bakan naa ni ijọba kilọ pe bi omi ṣe n kun si i, ati bi ojo ṣe n rọ pupọ, paapaa lagbegbe Odo Ogun atawọn ọna omi miran le fa omiyale.

Wọn rọ awọn eeyan to n gbe lagbegbe to lewu naa lati maa tẹti si ikede lori oju ọjọ, ki wọn si tete maa kuro nibẹ pẹlu awọn dukia to ba ṣe e gbe.

Awọn agbegbe yooku ni

Imo: Aboh-Mba, Ahizu-Mb, Ehime-Mb, Ezinihit, Ideato No, Ihitte/U ati Ikeduru.

Cross River: Abi, Akamkpa, Akpabuyo, Biase, Calabar, Calabar South, Ikom ati Obubra.

Ebonyi: Abakaliki, Afikpo, Afikpo South, Ebonyi, Ezza North ati Ezza

Benue :Buruku, Gboko, Guma, Katsina-Ala, Logo ati Ukum.

Anambra:Aguata, Anambra East, Anambra West, Anaocha, Awka North, Awka South ati Ayamelum.

Akwa Ibom: Abak, Eket, Etinan, Ibeno, Ibesikpo Asutan, Ibiono Ibom, Ika ati Ikono.

Ati bẹẹ bẹẹ lọ.