Kí ló tún da omi àláàfíà rú l‘Osun tí Adeleke ṣe ń lọgun ké sí Tinubu pé ọlọ́pàá ti gbàbọ̀dè, bí Oyebamiji ṣe lọgun pé APC ló ń kojú ìpànìyàn l'Osun?

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/X/Bola Oyebamiji/X
Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, to jẹ oludije sipo gomina fegbẹ Accord ti sọ pe oun ko foya lori eto idibo gomina ipinlẹ naa to n bọ, amọ, gomina sọ pe oun ko ni igboya ninu ileeṣẹ ọlọpaa ṣaaju eto idibo naa.
Gomina Adeleke ko ṣai fi idi rẹ mulẹ pe oun si ni igbagbọ ninu igbimọ to n pe fun alaafia ninu eto idibo to n bọ eyi ti Olori ologun orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, Ọgagun fẹyinti Abdulsalami Abubakar jẹ alaga rẹ.
Nigba to n sọrọ lẹyin eto ''Ọjọ Kan Pẹlu Gomina'' eyi ti ọfiisi olori awọn oṣiṣẹ ṣagbatẹru rẹ, Adeleke ni oun ko mikan rara tori Ọlọrun wa lẹyin oun ati lẹyin awọn eeyan ipinlẹ Osun.
Lẹyin to buwọlu adehun alaafia ṣaaju eto idibo gomina ọjọ kẹẹdogun oṣu yii to n bọ, Gomina Adeleke sọ pe ''igbimọ to n ri si bi eto idibo to n bọ yoo ṣe lọ ni alaafia ti ṣeleri lati bawọn ọlọpaa sọrọ.
Amọ, mi o ni igbagbọ ninu awọn ọlọpaa lọwọ yii, mo gbadura pe Ọlọrun yoo fọwọ tọ wọn lọkan.''
"Ẹgbẹ oselu alatako kan n halẹ lasan ni, emi ni maa bori ibo gomina Osun"
Adeleke fikun ọrọ rẹ pe o da oun loju wi pe oun yoo jawe olubori ninu ibo gomina to n bọ, o ni awọn ẹgbẹ oṣelu alatako kan n halẹ lasan an ni.
Gomina ipinlẹ Osun sọ pe gbogbo nnkan ti ẹgbẹ oṣelu alatako n ṣe lati da eto idibo naa ru yoo jasi pabo.
Oludije sipo gomina fẹgbẹ Accord ni awọn araalu yoo dibo foun tori awọn akanṣẹ isẹ ti oun ti ṣe nipa ipese ohun amayedẹrun, mimu ileri toun ṣe fun araalu ṣẹ, ati sisan owo ajẹmọnu fawọn oṣiṣẹ .
''A ti wa ni igbaradi, mo si fẹ rọ awọn araalu wi pe ki wọn ma foya.
Ijọba awarawa ni a wa, ẹnikẹni ko gbọdọ bẹru idunkoko ẹgbẹ oṣelu APC.
Ifẹ Ọlọrun ati ti eniyan nikan ni yoo ṣẹ, mo n rọ gbogbo eeyan lati jade wa dibo lọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ yii.
Ṣaaju lọsẹ ti kọja ni alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ ẹka ipinlẹ Osun, Kọmureedi Christopher Arapasopo, ti sọ pe awọn oṣiṣẹ ko ni pada si igba to buru jai laye ijọba APC nipinlẹ Osun.
O rọ gbogbo oṣiṣẹ wi pe ki wọn ma bẹru lati jade dibo lọjọ kẹẹdogun oṣu yii tori ẹtọ wọn ni.
Mo ke pe Aarẹ Bola Tinubu lati dẹkun rogbodiyan to n ṣẹlẹ l'Osun, ileesẹ ọlọpaa ti gbabọde – Adeleke
Ẹwẹ, Gomina ipinlẹ Osun ti ke pe Aarẹ Bola Tinubu lati wa ojutuu si rogbodiyan ati ipaniyan to n lọ lọwọ nipinlẹ naa ṣaaju eto idibo gomina ọjọ kẹẹdogun ọsu yii.
Adeleke sọrọ yii niluu Osogbo nibi to ti n ṣe ipolongo ibo ni ijọba ibilẹ Olorunda.
Gomina ran Aarẹ Tinubu leti wi pe ẹgbẹ oṣelu oun, Accord, ti yan an gẹgẹ bi oludije ti wọn yoo dibo fun ninu ibo aarẹ ọdun 2027.
O rọ aarẹ lati ṣe ojuṣe baba ki o si fopin si iṣẹlẹ ipaniyan to n ṣẹlẹ nipinlẹ Osun bayii.
Adeleke ko ṣai fi idi rẹ mulẹ pe awọn araalu yoo tako erongba ẹnikẹni to ba fẹ ṣe eeru ninu eto idibo to n bọ.
''Aarẹ Tinubu, nnkankan n ṣẹlẹ nipinlẹ Osun ti ẹ o tii fi opin si.
Ni ṣe ni wọn n ṣekupa awọn eeyan wa, ẹyin si ni aarẹ ati baba gbogbo wa.
Ipinlẹ Osun ti sọ pe awọn ko ni faye gba yiyi ibo, ẹ ranti nnkan to ṣẹlẹ lọdun 1983 o.
Ilẹ Yoruba ni o ti bẹrẹ lẹyin ti wọn ṣe eeru fun Bola Ige ati Adekunle Ajasin.
Osun ko ni i gba o, a fẹ ki eto idibo to n bọ lọ ni irọwọ rọsẹ.
Aarẹ Tinubu, ki lo de ti wọn tun n pa wa lẹyin ti a ti yan yin gẹgẹ bi oludije aarẹ ti a o dibo fun lọdun 2027?'' Adeleke sọrọ soke.
Gomina Adeleke fẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa wi pe wọn n ṣegbe lẹyin ẹgbẹ oṣelu kan lori rogbodiyan to n ṣẹlẹ l'Osun.
O wa rọ ijọba apapọ lati dẹkun ipaniyan to n ṣẹlẹ ki iru rogbodiyan to ṣẹlẹ lọdun 1983 ma ba tun ṣẹlẹ.
''Emi atawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lo n fara kaasa rogbodiyan to n ṣẹlẹ l'Osun - Oyebamiji
Ẹwẹ, oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Osun, Bola Oyebamiji, ti ọpọ mọ si Ambo ti pariwo lori rogbodiyan to n ṣẹlẹ ni ipinlẹ naa ṣaaju eto idibo ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ to n bọ.
Oyebamiji ṣalaye pe ko din ni ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC mẹẹdọgbọn to padanu ẹmi wọn ninu rogbodiyan to ṣẹlẹ sẹyin lọdun 2022 l'Osun.
Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ niluu Eko, Ambo ṣalaye pe kii ṣe ẹgbẹ oṣelu APC lo n da rogbodiyan silẹ kaakiri ipinlẹ Osun.
O ni ijọba to wa lori aleefa gan an lo n da ilu ru lati le dẹru bawọn araalu ki wọn ma ba le jade dibo.
Oludije sipo gomina fẹgbẹ APC sọ pe ''mo n fi asiko da awọn eeyan ipinlẹ Osun ati gbogbo ọmọ Naijiria loju wi pe emi atawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lo n fara kaasa rogbodiyan to n ṣẹlẹ l'Osun.
O le ni ọmọ ẹgbẹ APC mẹẹdọgbọn ti a gbọ pe ẹgbẹ oṣelu ijọba to wa lori oye ṣekupa lasiko eto idibo gomina ipinlẹ Osun lọdun 2022.
Wọn ṣekupa alaga ijọba ibilẹ Irewole, Remi Abass, to jẹ ijọba ibilẹ temi gan an.
Bakan naa ni ẹgbẹ wa ni akọsilẹ oriṣiiriṣii ikọlu ati ipaniyan eyi ti a n beere pe ki idajọ ododo waye lori rẹ.
Eyi tumọ si pe ijọba to wa lori oye bayii nipinlẹ Osun lọwọ ninu rogbodiyan to n ṣẹlẹ bayii.
Laipẹ yii ti ọga agba ọlọpaa Naijiria ṣabẹwo si ipinlẹ Osun ni o sọ pe awọn janduku ọdaran kan ti ọlọpaa n wa sapamọ sile akọwe ijọba ipinlẹ Osun.
Bakan naa ni wọn tun ṣe ikọlu si awọn ọmọ ẹgbẹ wa niluu Ede to jẹ ilu Gomina Adeleke.''
Oyebamiji ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe ẹgbẹ oṣelu APC ṣetan lati da ogo ipinlẹ Osun pada.






























