Kò yẹ kí nǹkan tó bá ń ṣẹlẹ̀ lọ́jà àgbáyé máa mú ìnira bá àwọn ọmọ Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ti kepe ijọba apapọ lati ṣe iranwọ fawọn oṣiṣẹ latari bi owo epo bẹntiroolu ṣe n lọ soke loorekoore.
NLC kepe ijọba lati mu adinku ba inira to n ba awọn oṣiṣẹ nitori owo epo to n lọ soke lera lera.
Bakan naa tun ni ẹgbẹ oṣiṣẹ rọ ijọba Aarẹ Bola Tinubu lati ṣe agbekalẹ eto ti yoo jẹ kawọn ileeṣẹ ifọpo rọbi maa ri epo rọbi ra pẹlu owo naira.
NLC képe ìjọba àpapọ̀ láti ṣèrànwọ́ fáwọn òṣìṣẹ́ ní Naijiria bí owó epo bẹntiróòlù ti di ₦1,430

Oríṣun àwòrán, NLC Headquarters/X
Iroyin fidi rẹ mulẹ pe ọpọ eeyan lo ti bẹrẹ sii rin lọ sibi iṣẹ wọn fawọn ti ibi ti wọn ti n ṣiṣẹ ko jinna ju tori epo bẹntiroolu to gbowo lori.
Ko din ni N1,430 tawọn eeyan n ra jala epo bẹntiroolu kan kaakiri orilẹede Naijiria, koda, iwadii fi han pe awọn mii n ra a ju bẹẹ lọ.
Aarẹ NLC, Joe Ajaero, sọ pe bi epo bẹntiroolu ṣe gbowo lori yoo tun dakun iṣoro tawọn ọmọ Naijiria n ba a finra tẹlẹ.
Ajaero ni bẹntiroolu to gbowo lori yoo jẹ ki owo ounjẹ, ọwọ ọkọ, owo ile ati owo ile ẹkọ naa lọ soke si i ni Naijiria.
Ajaero ni lasiko ti awọn alagbata epo fẹ mu adinku ba iye ti wọn n ta epo ni owo epo tun ṣadeede lọ soke.
Aarẹ ẹgbẹ NLC sọ pe ko yẹ ki nnkan to ba n ṣẹlẹ lagbaaye maa ni ipa to buru lara awọn ọmọ Naijiria tori ọpọ nnkan alumọni ni Eledua fi jinki orilẹede Naijiria..
O wa rọ ijọba apapọ lati ṣe agbekalẹ eto iranwọ fun araalu pẹlu owo bẹntiroolu to lọ soke lasiko yii.
Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ ni awọn orilẹede tawọn naa ni epo lagbaaye bii Naijiria ti n ṣeranwọ fun araalu latari owo epo to n lọ soke lagbaaye.



























