Ìdí tí ẹ kò fi rí mi nínú iṣẹ́ sinimá rèé, ṣùgbọ́n mo ti padà sẹ́nu iṣẹ́ báyìí- Mosun Filani

Gbajugbaja oṣere tiata, Mosun Filani, ti sọ pe obinrin to ba gbe iṣẹ lori ju ẹbi rẹ lọ ko le ri ile ọkọ gbe.
Mosun fi idi ọrọ yii mulẹ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC News Yoruba.
Ilumọọka oṣere naa sọ pe ''nnkan ti kii jẹ ki ọpọ obinrin to gbe iṣẹ sori gbe ile ọkọ ni pe wọn kii le yẹba pẹlu iṣẹ wọn fun idile.
Mo le lọ ṣiṣẹ tiata fun bi oṣu meji nigba ti mi o tii ṣe igbeyawo, ṣugbọn mi o le ṣe bẹẹ mọ bayii.
Ti o ba jẹ obinrin to gbe ọrọ iṣẹ sori ju ọrọ ẹbi lọ, o maa pada kuro nile ọkọ.''
Gbajugbaja oṣere naa fikun ọrọ rẹ pe oun ko le ṣe iyawo keji, amọ, oun ko bu awọn to n ṣe bẹẹ.
''Ọkọ mi ti le ṣe igbeyawo kan ri, ṣugbọn mi o ba ẹnikankan lọdọ rẹ, mo fẹ ọkọ mi niṣu lọka ni.
Ọmọ atapata dide ni mi, tiṣa ni mama mi nigba ti baba mi jẹ olukọ ilẹ ẹkọ giga.
Lati igba ti mo ti wa nile ẹkọ alakọbẹrẹ ni mo ti maa n sin Iya Niwẹ jẹ, mo si maa n jo gan an,'' Mosun lo sọ bẹẹ.
Mosun ni nitori ẹbi oun ni oun fi yẹba fun ere ṣiṣe nigba kan lẹyin toun ṣe igbeyawo tan.
Gbajugbaja oṣere naa sọ pe oun gbe igbesẹ yii tori iṣẹ tiata ni ṣe pẹlu ki eeyan maa rinrin ajo kaakiri eyi to le ṣakoba fun ẹbi oun.
O ni oun loun pinnu lati fi aye silẹ lati mojuto awọn ọmọ toun bi.
Ilumọọka oṣere naa wa sọ pe asiko ti to foun lati pada sẹnu iṣẹ tiata bayii tori awọn ọmọ oun ti de ibi toun ti le fi wọn silẹ lọ ṣere tiata.
Mosun ni koko to wa nibẹ ni pe ki eeyan ma fi ara rẹ we ẹlomiran tori ori yatọ sori, ati pe eto onikaluku yatọ sira wọn.




























