Ọlọ́pàá Ogun ri iPhone akẹ́kọ̀ọ́ mọ́kánlá gba padà lọ́wọ́ afurasi Adigun jalè meji

Oríṣun àwòrán, Babaseyi Oluseyi/WhatsApp
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ afurasi adigunjale meji, ti wọn fẹran lati maa ja awọn akẹkọọ lole.
Nnkan bi agogo mẹta ku ogun iṣẹju, oru ọjọ kẹtala, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 ni ọwọ tẹ awọn afurasi naa nile awọn akẹkọọ to wa ni Eruku/Agbon, ijọba ibilẹ Ewekoro.
Atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa, Babaseyi Oluseyi fi sita lo fidi iroyin naa mulẹ f'awọn akọroyin niluu Abeokuta.
Oluseyi sọ pe lara awọn to wa lagbegbe naa lo pe ọlọpaa ni ipe pajawiri, lati fi to wọn leti pe awọn adigunjale ti n ṣọṣẹ nileegbe awọn akẹkọọ.
Loju ẹsẹ lo sọ pe ọga ọlọpaa ẹkun Ewekoro ati awọn ọmọ ogun rẹ ti sare gbera lọ sibẹ lati koju awọn adigunjale naa.
Agbẹnusọ naa tẹsiwaju pe, kete ti awọn adigunjale ọhun ti kofiri awọn ọlọpaa, ni wọn ti ko gbogbo ẹru ti wọn jigbe silẹ, ti wọn si juba ehoro.
"Bi wọn ṣe foju kan awọn ọlọpaa lọọkan, awọn afurasi naa ko gbogbo ẹru ti wọn ti digun gba silẹ ninu baagi ile-ẹkọ kan, ti wọn si gbiyanju lati na papa bora," Oluseyi sọ bẹẹ.
Báwo ni ọwọ́ ṣe tẹ̀ wọ́n?
Oluseyi fi kun ọrọ rẹ pe, awọn ọlọpaa naa ko kawọ gbera rara lati jẹ ki wọn salọ, o ni loju ẹsẹ ni wọn ti tẹle wọn lẹyin, ti ọwọ si tẹ meji ninu wọn.
"Ṣugbọn ṣa, ikọ ọlọpaa le wọn, wọn si ri meji mu ninu wọn," agbẹnusọ jẹ ko di mimọ.
O wa darukọ awọn afurasi meji tọwọ tẹ, gẹgẹ bii Waris Dauda, ati Tiamiyu Abiodun.
Kí ni wọ́n digun gbà?
Kete ti ọwọ ti tẹ awọn mejeeji, ni ọlọpaa ti yẹ baagi wọn wo, ti wọn sib a oniruuru ẹru ti wọn ti digun gba nibẹ.
Foonu olowo nla ti ko din ni mọkanla ni wọn ba nibẹ, eyi ti wọn ṣẹṣẹ digun gba lọwọ awọn akẹkọọ naa.
Yatọ si eyi, Oluseyi fidi rẹ mulẹ pe ọlọpaa tun ba ẹrọ kọmputa alagbeeka ninu baagi ọhun, pẹlu awọn aṣọ loriṣiriṣi.
Bẹẹ lo sọ pe gbogbo awọn akẹkọọ ti wọn digun ja lole, ni wọn ti tọka si dukia wọn, ti wọn si ti gba a pada loju ẹsẹ.
"Ìwádìí ṣì n tẹ̀síwájú"
Oluseyi sọ pe iwadii ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe lasiko ti awọn afurasi naa n ṣọṣẹ lọwọ, wọn fi ipa mu ọkan lara awọ akẹkọọ naa lati gba ẹgbẹrun lọna igba naira lọwọ rẹ.
O ni, inu apo aṣuwọn ile ifowpamọ ni wọn ti fi owo naa ranṣẹ si apo aṣuwọn ara wọn.
Bakan naa lo ni gbogbo irinṣẹ ti wọn n lo, ni awọn ti gba lọwọ wọn, ti awọn si ti kọ ọ silẹ gẹgẹ bi ẹri aridaju.
O wa ni awọn afurasi ọhun ti wa ni ẹka ileeṣẹ wọn to n ri si iwadii ọran, SICD, nibi ti iwadii ti n tẹsiwaju nipa wọn.
Bẹẹ lo fi da awọn araalu loju pe ọwọ yoo tẹ awọn yooku ti wọn na papa bora, lati le foju wọn winna ofin.


























