Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà nígbèkùn, àwọn tí agbésùnmọ̀mí gbé lọ nílùú Woro àti Nuku ní Kwara gba ìtúsílẹ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede pe awọn eeyan tawọn ajinigbe ji gbe lọ niluu Woro ati Nuku nipinlẹ Kwara ti gba itusilẹ bayii.
Itusilẹ naa lo n waye lẹyin oṣu mẹfa tawọn eeyan naa ti wa nigbekun ajinigbe.
Loju opo Facebook to jẹ ti ijọba ipinlẹ Kwara ni wọn ti kede itusilẹ ọhun l'Ọjọru, ọjọ karun-un oṣu Kẹjọ ọdun 2026.
Ijọba ibilẹ Kaiama ni ilu Woro ati Nuku wa ni Kwara.
Iroyin sọ pe awọn eeyan naa to mẹ́rìndínlọ́gọ́sàn-án (176) niye nigba ti wọn ko wọn lọ.
"A dupẹ fun Oluwa, a si ki Aarẹ Tinubu, awọn ẹṣọ alaabo"
Ninu atẹjade ti ijọba Kwara fi kede ominira awọn eeyan naa ni won ti ni:
" Alihamdulillaah, a si dupẹ fun Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, awọn ẹṣọ alaabo ati gbogbo eeyan pata to kopa ninu aṣeyọri nla yii. A dupẹ !"
Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?
Tẹ o ba gbagbe, ọkan lara awọn ikọlu to milẹ titi lọdun yii ni eyi to waye lọjọ kẹta oṣu Keji ọdun 2026, niluu Woro ati Nuku, ipinlẹ Kwara.
Ikọlu naa ni eyi ti awọn afurasi Boko Haram ti kọ lẹta sawọn araalu, pe awọn fẹ wa ṣe waasi nibẹ, ti awọn araalu naa si ni awọn ko fẹ waasi wọn.
Ipadabọ rẹ ni bawọn agbesunmọmi to le lọgọrun-un ṣe yabo awọn ilu meji naa pẹlu ọpọlọpọ ọkada, ti wọn ṣina ibọn bolẹ, ti wọn si ko ọpọ eeyan wọgbo lọ.
Ko din ni eeyan igba (200) ti wọn pa, ọpọ farapa pẹlu, bẹẹ ni ọpọ eeyan di alarinkiri ti ko ni ẹbi tabi ẹnikẹni mọ, wọn ko si rile wọ mọ pẹlu.
Awọn ikọ fijilante to fẹ koju awọn agbesunmomi naa, wọn gba agbara lọwọ wọn nipa didana sun wọn mọ ibudo wọn.
Fun ọpọlọpọ oṣu lẹyin ikọlu naa, awọn ilu naa ko kun mọ pẹlu bi wọn ṣe di ahoro nitori ibẹru agbesunmọmi.
Lasiko ti a pari iroyin yii, ijọba ipinlẹ Kwara ko ti I sọrọ lori ọna tawọn to gba itusilẹ naa gba ri ominira.


























