Àwọn aráàlú faraya bí wọ́n ṣe ṣàwárí òkú obìnrin méje láàárín oṣù méjì síra wọn ní agbègbè kan náà

Awọn ọlọpaa South Africa to kọ ẹyin si ẹrọ ayaworan

Oríṣun àwòrán, Brenton Geach/Gallo Images via Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Awọn alaṣẹ orilẹ ede South Africa ti ni awọn tun ṣawari oku obinrin mii ni Ekurhule ni eyi to ti n mu ki ibẹrubojo tun maa gbọkan awọn eeyan lori aabo awọn obinrin ni orilẹ ede naa.

Wọn ni wọn ba oku ọmọbinrin naa to lefoo lori odo kan ni Clayville lẹbaa ile itaja Mall of Thembisa ni ọjọ Keje, oṣu Kẹsan-an.

Adele ọga ọlọpaa Guateng, Ọgagun Fred Kekana sọ pe awọn maa fi eyi kun iṣẹ iwadii to ti n lọ lọwọ lori ipaniyan to n waye ni orilẹ ede naa.

Minisita fọrọ awọn ọlọpaa ni South Africa, Firoz Cachalia fi aidunu rẹ lori ipaniyan naa han, to si ba ẹbi awọn eeyan to ti padanu ẹmi wọn kẹdun.

Aarẹ South Africa, Cyril Ramaphosa ti wa pe fun iwadii to loorin lori iku awọn obinrin naa.

Ikede ileeṣẹ ọlọpaa yii lo n fidi rẹ mulẹ pe ni oku Elizabeth "Tsontso" Moselakgomo lo jẹ oku obinrin kẹfa ti wọn n ṣawari.

Minisita naa ni bi wọn ṣe n ṣawari oku awọn obinrin ni paaki Kempton Park n kọ awọn lominu amọ awọn ko ni da ọwọ iwadii lori ohun to fa iku awọn eeyan naa duro.

Ọlọpaa ni oku Elizabeth "Tsontso" Moselakgomo, ẹni ọdun mejidinlogoji ti wọn kede lọjọ Aje, ọjọ Kẹrinla, oṣu Kẹsan-an ni oku karun-un ti wọn ri ni Kempton Park paapaa ni agbegbe Rhodesfield ni Guateng laaarin oṣu meji.

Amọ ni bayii, oku naa ti di mẹfa ni Kempton Park kan naa.

Minisita ọlọpaa naa ni iwadii n lọ lọwọ lati mọ boya iku awọn eeyan naa ni isopọ mọra wọn amọ ohun to ṣe Pataki julọ ni lati mọ idi ti awọn to huwa ibi naa ṣe n fojusun awọn obinrin.

Ki ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ lori pipa awọn obinrin ni South Africa

Cachalia ṣalaya pe iṣẹ ti n lọ lati ṣewadii iṣẹlẹ naa ti pe Kọmiṣanna apapọ fun ọlọpaa South Africa, Ọgagun Puleng Dimpane ti n ṣepade pẹlu awọn ikọ ọlọpaa to n ṣewadii iṣẹlẹ naa.

O ni nibi iwadii naa ni wọn ti fidi awọn ohun elo ti wọn nilo lati fi ran ikọ naa lọwọ mulẹ.

O fi kun pe awọn ọlọpaa maa ri daju lati ṣe iwadii to muna doko, ṣawari awọn to wa nidii iṣẹlẹ naa, ki wọn si foju wọn wina ofin.

"Ohun to ṣe pataki ni aabo awọn obinrin. Ileeṣẹ ọlọpaa South Africa yoo maa tẹsiwaju lati ṣiṣe pẹlu awọn araalu, awọn alẹnulọrọ lati le fidi ewu to wa mulẹ, mu alekun ba akitiyan iṣẹ ọlọpaa, ki wọn si tete ṣamulo awọn iroyin to ba ṣe koko."

Ẹwẹ, obinrin kan to sọrọ lori amohunmaworan sọ pe o seeṣe ko jẹ pe oku ọmọ oun ni awọn ọlọpaa kede pe awọn ri ni owurọ ọjọ Iṣẹgun.

Amọ ko i tii si eni to sọ orukọ tabi ṣafihan oku ẹni ti awọn ọlọpaa ṣẹṣẹ ri naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa n rọ awọn eeyan to ba le ran iwadii wọn lọwọ lati yọju si agọ ọlọpaa, ki wọn si ri daju pe awọn ko gbee iroyin ofege tabi ohun ti wọn ko le fidi rẹ mulẹ.

A o tii le fidi ẹni to n ṣiṣẹ ibi yii mulẹ

Agbẹnusọ apapọ fun ileeṣẹ ọlọpaa, Athlenda Mathe sọ fawọn akọroyin lọjọ Iṣẹgun pe ni agbegbe Katema ni wọn ti ri oku ẹnikẹfa yii ni owurọ ọjọ Iṣẹgun, to si jọ ẹni to ti le ni ọgbọn ọdun.

O ni oku obinrin naa ti n jẹra diẹdiẹ to si jẹ pe aarọ naa ni wọn ju oku ọhun si agbegbe naa.

O fi kun pe iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mọ boya eeyan kan ṣoṣo lo n ṣokunfa iku ọpọ awọn obinrin yii tabi eeyan pupọ ni wọn ṣugbọn awọn ko i tii ni idahun si gbogbo ibeere yii.

O sọ pe eyi ni ko ni jẹ ki awọn ṣe iṣẹ ni warawara ki awọn le baa fi idi ootọ mulẹ.

Mathe ni oun nigbagbọ pe awọn ikọ oluwadii maa ṣe iṣẹ wọn bo ṣe yẹ lati fidi ododo mulẹ.

Awọn obinrin wo lo ti padanu ẹmi wọn ni Kempton Park?

Elizabeth “Tsontso” Moselakgomo wọ aṣọ olomi aro, o n rẹrin-in si ẹrọ ayaworan, ododo kan wa lẹyin rẹ

Oríṣun àwòrán, SA Justice, Crime Prevention and Security

Ẹni akọkọ ti wọn kọkọ ṣawari oku rẹ jẹ ẹni ọdun mẹtadinlogoji tawọn ọlọpaa ri oku rẹ ni R21 lọjọ Kẹẹdogun, oṣu Keje.

Ileeṣẹ ọlọpaa ko i tii fi orukọ rẹ lede ṣugbọn wọn ni ihoho ọmọluabi ni wọn ba oku rẹ to si jọ wi pe waya ni wọn fi fun lọrun pa.

Ikọ to n ri si didena iwa ọdaran ati amojuto aabo sọ pe ọwọ ti tẹ eeyan kan lori iku obinrin naa to si ti wa ni ahamọ.

Ọjọ Kẹrinlelogun oṣu Kẹjọ ni wọn tun ṣawari oku ẹnikeji ni agbegbe R21 kan naa ti oun naa ko si ni aṣọ lara dabi alara.

Ẹni ọdun mejilelọgbọn ni ileeṣẹ pe obinrin naa.

Ni ọjọ Kẹwaa, oṣu Kẹsan-an ni wọn tun ṣawari oku obinrin mii ti oun naa w ani ihoho ọmọluabi, ti wọn si ni oku rẹ ti n jẹra.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni bi ara rẹ ṣe ti n jẹra yii ma jẹ ko nira lati le mọ iru eeyan to jẹ gan-an amọ iwadii n lọ lati mọ ibi to ti wa.

Oku ẹnikẹrin ni wọn ṣawari ni ọjọ Kejila, oṣu Kesan-an ni ẹyin ile itura kan ni Rhodesfield.

Ẹni ọdun mejidinlogoji ni ileeṣẹ ọlọpaa pe e, ti wọn si sọ pe o wọ aṣọ ere idaraya ti o bo gbogbo ara rẹ tan.

Wọn ni awọn ẹbi rẹ lo maa fidi orukọ rẹ atawọn ohun to yẹ lati mọ nipa rẹ mulẹ nigba ti wọn ba yọju sile igbokuupamọ si to wa.

Ẹni karun-un ni Elizabeth "Tsontso" Moselakgomo, ẹni ọdun mejidinlogoji, tawọn ẹbi rẹ fidi rẹ mulẹ lọjọ Aje ni ile igbokuupamọ si Germiston.

Ni ọsan ọjọ Kẹsan-an, oṣu Kẹsan-an ni Moselakgomo ni awati lẹyin to jade nile pe oun fẹ lọ sare ni Rhodesfield, Kempton Park.

Ni bayii, awọn ọlọpaa tun ti ṣawari oku eeyan kẹfa amọ ti wọn ko tii mọ ohunkohun nipa rẹ.

Oku awọn eeyan yii ti n mu kawọn eeyan South Africa maa kọminu lori aabo awọn obinrin, ti eyi si ti n fa ibẹru bojo fawọn eeyan.

Ajọ kan to n ja fawọn obinrin, Women for Change sọ pe ṣiṣawari oku awọn obinrin yii n fa ibinu laaarin awọn obinrin, ti wọn si n sọ pe awọn ọlọpaa ko ṣe iṣẹ wọn bii iṣẹ ti awọn eeyan ba ṣẹṣẹ n wa aabo funra wọn.