Ẹ yé gbé irọ́ kiri, kìí gbèsè ₦8,000 ló sọ Mohammed tó kú dèrò àtìmọ́lé, ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé - Ọlọ́pàá Oyo ṣàlàyé

Oríṣun àwòrán, The Punch
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti sọrọ lori iroyin to ti lu ori ayelujara pa eyi to sọ pe ọdọmọkunrin kan, Al-Amin Mohammed, gbẹmi ara rẹ lẹyin ti ọlọpaa ju si atimọle lori gbese ₦8,000 ti o jẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye loju opo X rẹ wi pe iroyin kan ni ọlọpaa mu ọkunrin yii, wọn si gbe e lọ sile ẹjọ lori gbese ₦8,000 to jẹ naa, eyi to jẹ ko gbẹmi ara rẹ lẹyin ọjọ mẹta to kuro ni ahamọ ọlọpaa.
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti wa ṣalaye wi pe irọ to jinna si oootọ ni iroyin ọhun eyi to le ṣi araalu lọna.
Awọn ọlọpaa ni kii ṣe ohun to gbe oloogbe naa de ile ẹjọ lawọn eeyan kan n gbe kiri lori ayelujara.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ọkunrin naa lọ ba obinrin to n ṣe owo POS lati gba ₦23,000, eyi ti igbagbọ wa pe yoo da pada fun obinrin oni POS naa lori aapu foonu rẹ.
''Bayii ni obinrin oni POS naa fun un ni owo yii, amọ, oloogbe yii kuro lọdọ obinrin oni POS yii lai da owo rẹ pada gẹgẹ bi o ti ṣeleri.
Lẹyin ọpọ atotonu ni ọkunrin naa da ₦15,000 pada ninu owo yii, amọ, o kọ lati san ₦8,000 ti owo to n jẹ obinrin naa ku.
Lẹyin naa ni obinrin to n ṣowo POS yii gba foonu ọkunrin yii wi pe to ba da owo oun pada loun yoo to fun un ni foonu rẹ.
Dipo ki o sanwo to ku, ọkunrin yii lọ huwa ipa si obinrin to n fi POS ṣowo nile rẹ lọjọ kẹjọ oṣu Kẹsan an ọdun yii ti o si ba ẹrọ Airtel ti obinrin naa fi n ṣe iforukọsilẹ Sim card fawọn onibaara jẹ; ₦177,000 si ni a gbọ pe wọn n ta ẹrọ naa,'' ọlọpaa ṣalaye.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ara adugbo dasi ọrọ naa, amọ, wọn ni ọrọ naa ko yanju.
Ọlọpaa ipinlẹ Oyo ni ọrọ naa pada de ọdọ awọn fijilante, awọn fijilante gan an lo wa ko awọn mejeeji lọ si agọ ọlọpaa.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn gbiyanju lati bawọn yanju ọrọ naa, amọ, ẹni to lọrọ ni oun gbọdọ gbe ọrọ naa lọ sile ẹjọ.
Bayii ni wọn gbe ọkunrin naa lọ sile ẹjọ lori ẹsun pe o huwa ipa, ati pe o ba nnkan jẹ, kii ṣe nitori ẹgbẹrun un mẹjọ naira ni wọn fi gbe e lọ sile ẹjọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ọkunrin naa dero ahamọ lọgba ẹwọn Agodi tori o kuna lati pese awọn nnkan ti ileẹjọ beere fun beeli rẹ, kii ṣe wi pe ọlọpaa ti i mọlẹ nitori gbese ₦8,000 to jẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ọkunrin naa gba itusilẹ lẹyin to pese awọn nnkan ti ileẹjọ n beere lọwọ rẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni kii ṣe nitori ₦8,000 ni ọkunrin naa fi dero atimọle bi ko ṣe awọn ẹsun mii ti wọn fi kan an.
Bakan naa tun ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ko si afarajọ rara laarin iku ọkunrin naa ati ẹjọ rẹ ti wọn mu wa sọdọ ọlọpaa.
Awọn ọlọpaa ni o yẹ ki iwadii waye lori nnkan to ṣokunfa iku ọkunrin yii, dipo bawọn kan ṣe n lọ iku rẹ mọ pe o wa ni atimọle ọlọpaa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post


























