Ìbẹ̀rù gba ọkàn àwọn oníbàárà bí báǹkì Zenith ṣe lọgun pé àwọn oníjìbìtì ti gba ẹ̀búrú wọnú àkọ́sílẹ̀ àwọn oníbàárà rẹ̀ àtàwọn ilé ìfowópamọ́ míì

Oríṣun àwòrán, Other
Ibẹrubojo ti gba ọkan awọn onibara ileeṣẹ ifowopamọ Zenith Bank lẹyin ti awọn eeyan kan gba ọna ẹyin wọ inu apo iṣuna awọn onibara naa lati ni anfaani si awọn akọsilẹ nipa wọn.
Zenith bank funra rẹ lo fidi ọrọ naa mulẹ ninu atẹjiṣẹ to fi ranṣẹ si awọn onibara ọhun lọjọ Iṣẹgun.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, lara awọn alaye ti awọn eeyan naa ri nipa awọn onibara wọn ni "email address ati ẹrọ ibaraẹnisọrọ" awọn onibara naa.
Zenith fidi rẹ mulẹ pe kii ṣe awọn nikan ni wọn doju iṣẹlẹ naa kọ nitori o kan awọn ileeṣẹ mii pẹlu.
Ile ifowopamọ naa ni bo tilẹ jẹ pe iṣẹlẹ ọhun waye, oju opo awọn ileeṣẹ naa ko lule, bẹẹ ni awọn onibara si le dunradura lawọn oju opo ọhun.
O ni "A rọ awọn obibara wa ki wọn ṣọra fun atẹjiṣẹ email, atẹjiṣẹ ori ẹrọ ilewọ ati ipe ori aago, ẹ ma sọ ọrọ ikọkọ ti ẹ fi n wọ inu apo iṣuna, PIN ati OTP tabi awọn nnkan mii to jọ bẹẹ fun ẹnikẹni."
"Lootọ ni awọn kan kọlu wa amọ a ti gbe igbesẹ to yẹ"
Ninu atẹjiṣe ti Zenith Bank fi ranṣẹ si awọn onibara wọn, wọn ni "Onibara wa tootọ, a ti bẹrẹ iwadii lori bi awọn kan ṣe lanfani si awọn alaye diẹ ninu eyii ti ẹrọ ibaraẹnisọrọ ati email wa ninu rẹ.
"Iṣẹlẹ yii jẹ ọkan lara awọn iru rẹ to ṣẹlẹ kaakiri agbaye.
"Ni kete ti a kofiri rẹ ni a tete ṣe awọn ohun to tọ lati daabo alaye yii gẹgẹ bii onibara wa.
"Gbogbo awọn oju opo ifoworanṣẹ wa lo wa ni digbi ti gbogbo rẹ si n ṣiṣẹ bo ṣe yẹ.
"Gẹgẹ ọna lati daabo bo yin, a rọ awọn onibara wa ki wọn ṣọra fun atẹjiṣẹ email, atẹjiṣẹ ori ẹrọ ilewọ ati ipe ori aago, ẹ ma sọ ọrọ ikọkọ ti ẹ fi n wọ inu apo iṣuna, PIN ati OTP tabi awọn nnkan mii to jọ bẹẹ nipa apo iṣuna yin fun ẹnikẹni."
"Afojusun wa ni lati daabo awọn onibara wa ati gbogbo alaye nipa wọn to wa lakata wa."
Lẹyin naa ni wọn kede awọn ẹrọ ibaraẹnisọrọ ati apo email ti awọn eeyan le maa pe ti wọn ba kofiri ohun ajeji ninu apo iṣuna tabi aapu wọn.





























