Kí ló ṣẹlẹ̀ tí Seyi Makinde ń pe Sharafadeen Alli ní lọ́yà tí ò dé kóòtù rí? Àlàyé rèé

Gomina Seyi Makinde lapa osi, o wọsọ alawọ aro, o si de fila pupa, o fi igo soju. Sẹnetọ Sharafadeen Alli lapa ọtun, oun naa wọsọ alawọ aro, o de fila alawọ kan naa.

Oríṣun àwòrán, Gov. Seyi Makinde/ Facebook/ BBC

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Gomina ipinlẹ Oyo, Onimọẹrọ Seyi Makinde, ti ju ogulutu ọrọ lu oludije sipo gomina ipinlẹ Oyo ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Sharafadeen Alli, bii idibo ọdun to n bọ ṣe n sunmọ etile.

Ọrọ nipa kikun oju oṣunwọn, iṣẹ ti wọn gbe dani ati bi kaluku ṣe dangajia to lo fa a ti oko ọrọ fi bọ lati ẹnu Makinde si Sharafadeen.

Ki lo ṣẹlẹ gan-an?

Gomina Seyi Makinde ti saa rẹ nipo gomina Oyo yoo kasẹ nilẹ lọdun to n bọ ti kede ipinnu rẹ lati dupo aarẹ Naijiria ninu ẹgbẹ oṣelu APM ni 2027.

Bẹẹ si ni Sẹnetọ Sharafadeen Alli to n ṣoju Guusu ipinlẹ Oyo naa n gbe igbesẹ lati di gomina ipinlẹ naa lọdun to n bọ, ninu ẹgbẹ oṣelu APC.

Amọ lọjọ Ẹti to kọja yii, lasiko ti Makinde n ṣalaye awọn iṣẹ to ṣe nipo gomina ati bawọn eeyan to n ba a ṣiṣẹ ṣe kaju ẹ si, o sọrọ ti ọpọ eeyan gba pe Sẹnetọ Alli lo n ba wi.

Makinde to ṣẹṣẹ pada sẹnu iṣẹ lẹyin isinmi ọlọdọọdun rẹ sọ pe:

"Ẹyin naa ri ikọ to duro niwaju yin. Onimọẹrọ ni mi, ọmọ ẹgbẹ awọn Onimọẹrọ lorilẹede Naijiria.

"Agbẹjọro ni Adele gomina, o si tun ti jẹ olootu idajọ ri. Ọjọgbọn onimọ nipa ọrọ aje ni Akọwe ijọba, Ọmọwe ni olori oṣiṣẹ.

"Awọn mọkanla to wa nipo akọkọ ninu wa la mu wa sipinlẹ Oyo.

"To ba dẹ wa wu yin, tẹ ẹ lọọ dibo fẹni to sọ pe lọya loun ti o de kootu ri. Ẹ jẹ ko darukọ ẹjọ kan to ṣe ri."

Bi Gomina Makinde ṣe sọrọ yii ni ọpọ eeyan ti bẹrẹ si i gbe e kiri pe Sharafadeen Alli lo n ba wi.

Amọ Makinde ko dakẹ sibẹ, o tun ni ki alatako oun waa tọka aṣeyọri rẹ kankan to ti ṣe, pẹlu awọn ohun to tiẹ fẹ ṣe fawọn eeyan ipinlẹ Oyo.

O ni oṣelu ki i ṣe nnkan awada, akọ iṣẹ ni.

Makinde sọ pe kadara ọpọ eeyan lo rọ mọ oṣelu, ki i ṣe ibi ere rara.