Ìjọba kéde òfin kónílé gbélé báwọn ọ̀dọ́ ṣe bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn lórí àwọn èèyàn mẹ́tàdínlógójì tó kú sí àhámọ́ NSCDC

Awọn ero to yawọ ọfiisi ajọ NSCDC

Oríṣun àwòrán, Reuters

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Ijọba ipinlẹ Niger ti kede ofin konile o gbele fun ọjọ kan ni ilu Minna, olu ilu ipinlẹ naa latari iwọde to bẹrẹ ni ilu naa lori iku awọn eeyan ti wọn fẹsun kan pe wọn n wakusa lọna aitọ to ku si ahamọ ajọ ẹṣọ aabo NSCDC.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ fun BBC pe lẹyin irun jimọ ni ofin konile gbele yoo ti bẹrẹ ti di ọla, ọjọ Abamẹta.

Ileeṣẹ ọlọpaa rọ awọn eeyan lati tẹle ofin naa lojuna ati da aabo bo emi ati dukia awọn ati lati dena dida ilu ru latọwọ awọn kọlọransi eeyan.

Awọn fidio to wa lori ayelujara ṣafihan bawọn ọdọ kan ṣe ya sawọn opopona to ṣe koko ni ilu Minna lati fẹhonuhan lori iku awọn eeyan naa.

Fidio naa ṣafihan bawọn ọlọpaa ṣe n gbiyanju lati fi afẹfẹ gaasi tajutaju lati fi tu awọn eeyan naa ka.

Olugbe agbegbe Tunga Sabon Titi nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ti ko fẹ ki a darukọ oun sọ fun BBC pe bi awọn eeyan ṣe n ju oko si awọn ọlọpaa ni awọn ọlọpaa naa n yinbọn.

O ni eeyan mẹrin ni ibọn ọlọpaa ba lasiko iwọde naa ti ọkan ninu wọn si jade laye lẹsẹkẹsẹ.

Agbẹnusọ ajọ NSCDC, Babawale Afolabi sọ fun BBC pe awọn eeyan to padanu ẹmi wọn si ahamọ ileeṣẹ naa lo jẹ mẹtalelọgbọn.

Ṣugbọn awọn araalu kan n sọ pe iye awọn eeyan naa ju bẹẹ lọ.

Ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí àwọn afurasí mẹtadinlogójì tó kú sí àhámọ́ NSCDC nípinlẹ Niger

Awọn osiṣẹ NSCDC ree ti wọn duro pẹlu ibọn ogun wọn, wọn duro si ara ọkọ amuṣẹya wọn

Oríṣun àwòrán, Nigeria Security and Civil Defence Corps/Facebook

Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii tan, ni ko tii sẹni to le sọ pato ohun to ṣokunfa iku awọn eeyan ti ko din ni mẹtadinlogoji, ti wọn ku si ahaamọ ileeṣẹ Sifu Difensi, NSCDC nipinlẹ Niger.

Awọn eeyan naa la gbọ pe wọn fẹsun kan wi pe wọn n wa kusa ijọba lọna aitọ lagbegbe Wushishi si Lukoto nipinlẹ niluu Minna, ipinlẹ Niger.

Ninu igbiyanju lati gbogun ti wiwa kusa lọna aitọ, NSCDC la gbọ pe wọn lọ si agbegbe M.I. Wushishi/Lukoto lọjọ kẹẹdogun si ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 lati mu awọn afurasi.

Ọpọ awọn afurasi ni iroyin fi to wa leti pe awọn oṣiṣẹ NSCDC mu laaarin ọjọ meji naa, ti wọn si ko wọn si ahaamọ.

Si iyalẹnu, pupọ ninu awọn tọwọ tẹ na ani wọn ku si ahaamọ, lasiko ti NSCDC lawọn n ṣe iwadii lọwọ.

"Afurasí tó lé láàdọ́ta la mú

Nigba to n ba BBC sọrọ, agbẹnusọ ileeṣẹ NSCDC nilẹ Naijiria, Babawale Afolabi sọ pe ojoojumọ ni awọn awakusa lọna aitọ n pọ si kaakiri agbegbe to wa ni Niger.

Afolabi sọ pe awọn to le ni aadọta ni ọwọ awọn tẹ ninu iṣẹ ti awọn ṣe ni ibẹrẹ ọsẹ yii, bo tilẹ jẹ pe wọn ko tii foju wọn ba ile-ẹjọ.

O ni awọn ṣi n gba orukọ wọn ati ọrọ iwadii lẹnu gbogbo awọn afurasi naa lọwọ, ko to di pe wọn bẹrẹ sii ku.

Afolabi kọminu lori bi awọn eeyan ṣe n wa kusa lọna aitọ nipinlẹ Niger, to si lo n ba wọn ninu jẹ.

"O jẹ ohun to le gidi, oniruuru ẹsun wiwa kusa lọna ti ko bao fin mu, ni a ti gba ni Niger,"agbẹnusọ NSCDC sọ bẹẹ.

Siwaju sii lo fidi rẹ mulẹ pe agbegbe ti awọn eeyan naa ti lọ n wa kusa, ni wọn maa n ko goolu ati awọn ohun amuṣọrọ miran si.

"Wọn maa n ko goolu ati awọn nnkan amuṣọrọ miin sibẹ - awọn oṣiṣẹ wa to n ri sọrọ kusa maa n lọ sibẹ loorekoore lati fọwọ ofin mu awọn to n wa kusa lọna aitọ."

Ìwádìí bẹ̀rẹ̀

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣaaju, ki Afolabi too ba BBC sọrọ, lo ti jẹ ko di mimọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori ohun to ṣokunfa iku awọn eeyan naa.

Afolabi sọ bẹẹ ninu atẹjade to fi sita f'awọn akọroyin, eyi ti ẹda rẹ BBC lọwọ.

O ni awọn afurasi awakusa ti ko din ni mẹtalelogoji ni wọn ku si ahaamọ NSCDC lasiko ti iwadii n lọ lọwọ.

Aarọ Ọjọbọ, ọsẹ yii lo sọ pe wọn ri oku awọn eeyan naa nibi ti wọn fi wọn pamọ si nileeṣẹ wọn to wa ni niger.

Ọga agba NSCDC ni Niger, Suberu Aniviye sọ pe ajakalẹ arun kan lo wọle tọ awọn eeyan naa lahaamọ, to si ṣokunfa iku wọn.

Ṣugbọn ileeṣẹ NSCDC patapata ni Naijiria sọ pe awọn ko tii le fidi ohun to ṣokunfa iku awọn eeyan naa mulẹ, nitori pe abajade awọn onimọ nipa iṣegun oyinbo ko tii fidi rẹ mulẹ.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ NSCDC fi sita l'Ọjọbọ, o sọ pe ọga awọn patapata, Ahmed Abubakar Audi, ti paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ lẹkunrẹrẹ lati mọ kulẹkulẹ ohun to ṣokunfa iku awọn eeyan ọhun.

O ni igbakeji ọga agba to wa lẹka iwadii ni yoo jẹ adari ikọ ti yoo bẹrẹ iwadii nipa iku awọn eeyan, nitori pe kii ṣe ohun ti wọn gbọdọ kawọ gbera le lori.

Kí làwọn ohun tí wọ́n fẹ́ẹ́ ṣe ìwádìí rẹ̀?

Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe ṣalaye, o sọ pe igbimọ oluwadii naa yoo mọ ipo ti ilera gobgbo awọn afurasi naa wa, ko to di pe wọn mu wọn si ahaamọ.

O sọ pe wọn yoo mọ iye ati asiko ti wọn ti lo ninu ahaamọ naa wa, bẹẹ si ni wọn yoo mọ ipo ti ahaamọ ti wọn ko wọn pamọ si wa.

Ni afikun, o sọ pe wọn yoo mọ kulẹkulẹ iru itọju ilera ti wọn fun wọn, ati awọn nnkan miran to ṣokunfa iku gbogbo wọn.

"Ileeṣẹ NSCDC ti fidi iku awọn afurasi awakusa kan ti a rọwọ to laipẹ yii nipinlẹ Niger laaarin ọjọ kẹẹdogun si ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 mulẹ," atẹjade naa sọ bẹẹ.

"Lẹyin ohun to ṣẹlẹ yii, ọga agba patapata, Ahmed Abubakar Audi, ti paṣẹ pe igbimọ agbekalẹ oluwadii agba, ti igbakeji ọga agba lẹka iwadii jẹ alakoso rẹ, lati ṣagbeyẹwo gbogbo ohun to ṣe okunfa iṣẹlẹ naa.

"Wọn ti pa a laṣẹ fun igbimọ naa lati ṣe ẹkunrẹrẹ iwadii nipa ohun to ṣokunfa iku wọn, to si mọ ipo ti wọn wa lasiko ti wọn fọwọ ofin mu wọn, asiko ti wọn lo lahaamọ, ipo ti ahaamọ naa wa, ati irufẹ itọju ilera ti wọn ri gba, to fi mọ gbogbo ohun to le fa iku awọn afurasi naa," o ṣalaye siwaju.

Ìjọba dá ọ̀gá NSCDC dúró lójijì

Suberu Aniviye, alakos agba fun NSCDC nipinlẹ Niger

Oríṣun àwòrán, NSCDC NigerState Command Headquarters/Facebook

Ijọba apapọ Naijiria ti wa sọ pe ki ọga agba ileeṣẹ alaabo NSCDC nipinlẹ Niger lọ rọkunle, nitori b'awọn afurasi kan ṣe ku si ahaamọ labẹ iṣakoso rẹ.

Suberu Aniviye lorukọ ọga agba naa ti ijọba apapọ ni kọ lọ rọkunle.

Minisita fọrọ abẹle, Olubunmi Tunji-Ojo lo fidi iroyin yii mulẹ ninu atẹjade to fi sita lorukọ ijọba apapọ Naijiria.

Atẹjade naa ti oludamọran pataki fun minisita naa lori eto iroyin, Alao Babatunde buwọ lu, jẹ ko di mimọ pe ohun to ku diẹ kaato ni iku awọn eeyan naa.

"Ohun to ba ni lọkan jẹ ni iṣẹlẹ naa, ṣugbọn sibẹ, ẹkunrẹrẹ iwadii yoo waye, nigba ti ọga agba ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ labẹ iṣakoso rẹ yoo ṣi lọ rọkunle naa," atẹjdae naa sọ bẹẹ.

"A n ṣakoso ijọba to jẹ pataki ojuṣe rẹ ni didaabo bo ẹmi ati dukia araalu, a si ti ṣiṣẹ lati duro lori eyi."

Bakan naa lo wa ba gomina ipinlẹ naa, Mohammed Umaru Bago kẹdun iṣẹlẹ ọhun.

"A gbìyànjú láti gba àwọn èèyan wa jáde, ṣùgbọ́n..."

Awọn araalu Minna nipinlẹ Niger ti wa ba BBC sọrọ, ti wọn ṣi ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa ohun to fa bi awọn eeyan naa ṣe.

Awọn eeyan naa sọ pe awọn gbiyanju lati gba awọn eeyan naa silẹ ni ahaamọ awọn NSCDC, ṣugbọn ti wọn sọ pe wọn ko fun wọn laaye.

Ninu ọrọ ti wọn ba BBC sọ, ọkan lara awọn ti NSCDC mu ọmọ rẹ, Ọgbẹni Abdullahi Dalhatu sọ pe ori lo ko oun yọ wi pe ọmọ oun ko padanu ẹnu ẹmi rẹ.

Abdullahi Dalhatu, sọ pe o pẹ diẹ ti awọn NSCDC ti n mu awọn awọn eeyan lagbegbe naa, ti wọn si n fi wọn sahaamọ.

"Awọn alakoso NSCDC ti n mu awọn ọmọ wa lati ọjọ diẹ sẹyin, ṣugbọn wọn mu awọn eeyan kan lọjọ mẹta sẹyin.

"Nigba ti wọn mu awọn eeyan naa, a lọ sibẹ, wọn si sọ pe ka pada wa lọjọ keji. Gbogbo ọjọ keji naa la lo nibẹ, sibẹ wọn ko yọnda wọn fun wa.

"O ṣeni laanu wi pe ọjọ keji la tun bẹrẹ sii gbọ iroyin wi pe awọn ọmọ wa ti ku," Dalhatu sọ bẹẹ fun BBC.

Ọkunrin naa sọ pẹ ẹru bao un, toun sis are gba ile iwosan lọ latyi wo ọmọ oun.

"Mo lọ si ile iwosan lati wo ọmọ mi, ṣugbọn nko ri nibẹ, ko pẹ ni iya rẹ pe mi lori foonu wi pe o ti pada sile."

O wa sọ pe ọmọ oun ṣalaye foun pe inu ahaamọ naa gbona jọjọ, nitori pe ero pọ nibẹ.

"Nigba ti mo ba ọmọ mi sọrọ, o sọ pe inu ahaamọ naa gbona jọjọ, ero si pọ nibẹ, o lawọn to to ọgbọn lo wa nibẹ.

"O sọ pe anfaani toun ri ni pe ẹgbẹ ferese kekere to wa nibẹ loun duro si, ibẹ ni awọn ọrẹ oun si ti n ṣubu lulẹ, ti wọn n ku, ti awọn miran si daku."

O wa fi kun ọrọ rẹ pe, ọmọ oun sọ pe awọn n kan ilẹkun, ṣugbọn ko sẹni to wa ṣilẹkun fun awọn.