Mọ̀ nípa 'monkey tail', ọtí tó ń ba ẹ̀dọ̀ àti ìfun jẹ́ tó ti gbẹ̀mí èèyàn 49

Ọkunrin kan loṣo pẹlu kondoro niwaju rẹ

Oríṣun àwòrán, Ondo Police command/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Dokita Fashua Ayodeji Anthony to n tọju awọn eeyan to mu ogogoro ''monkey tail'' to ti ṣekupa eeyan mọkandinlaadọta bayii nipinlẹ Ondo sọ pe ọti ogogoro tuntun lo tun n ṣekupa awọn eeyan bayii nipinlẹ naa.

Dokita Anthony to jẹ ọga ile iwosan Life Care Hospital ni Orita Odigbo sọ pe ''iwadii fi han wi pe wọn ṣẹṣẹ po ọti ogogoro tawọn eeyan n mu lọwọ bayii eyi to n ṣakoba fun agọ ara wọn pọ ni.

O yato si eyi ti wọn kọkọ mu to ṣakoba fun ọpọ eeyan ni ibẹrẹ oṣu Keje to kọja lọ.

A tun ri pe lara awọn eeyan ti ọti yii n ṣakoba fun ti ni awọn aisan kan tabi omiran lara tẹlẹ.

Ọpọ ninu wọn lo ti ni arun Hepatitis B lara, awọn ni aisan ẹjẹ ruru, bẹẹ lawọn mii ni aisan ẹdọ ninu agọ ara wọn.

Ọpọ awọn eeyan yii ni wọn ko mojuto aisan to wa lara wọn tẹlẹ ki wọn to tun lọ mu ogogoro yii.''

Ọga agba ile iwosan Life Care ni Orita Odigbo sọ pe awọn eeyan mii tun le dagbere faye ti wọn ko ba dẹkun mimu ogogoro to wa nita naa.

Dokita Anthony fikun ọrọ rẹ pe awọn kan wa ti ọti yii ko jẹ ki wọn riran mọ.

Ọga agba ile iwosan Life Care sọ pe awọn to ti gbadun naa si tun n wa fun ayẹwo loorekoore ki awọn le mọ ibi ti ara wọn ku si.

Àwọn kan ò ríran mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n mu ọtí 'monkey tail' l'Ondo, ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn míì sì kú, àyàfi... - Dókítà ṣàlàyé

Dokita Anthony ṣalaye pe ''inu ifun ni ogogoro yii maa n kọkọ lọ gbara ti wọn ba ti mu un.

Ọti yii maa n jẹ ki wọn maa bi, eebi yii le ṣakoba fun nnkan miran ninu ara.

Amọ, awọn ti wọn ko ba bi pupọ ju, o ṣee ṣe ki ọti naa lọ sinu ọpọlọ wọn.

Bayii ni ọti naa yoo kọja lọ sinu oju ti yoo si ba oju jẹ, o le kọja lọ sinu kindinrin naa lati ba a jẹ.

O tun le lọ sinu ẹdọ tabi inu ọkan lati ba a jẹ, lẹyin iyẹn bayii, iku lo kan.''

Ọga agba ile iwosan Life Care ni ijọba ti ṣiṣẹ takun takun lori iṣẹlẹ naa tori wọn ti fọwọ ofin mu ọpọ awọn to n ta ọti yii.

Dokita naa ṣalaye wi pe lara awọn to n ta ọti ọhun gan an naa ti ku lẹyin tawọn naa mu un tan.

O sọ pe ijọba ti n ṣe polongo kaakiri fun araalu wi pe ki wọn ye ta tabi ra ọti ''monkey tail'' to n pawọn eeyan naa mọ.

Amọ, Dokita Anthony sọ pe awọn eeyan ti wọn n gbe ninu oko ti wọn ko lanfaani lati gbọ iroyin lo ṣee ṣe ki wọn tun maa mu ọti yii.

Eeyan 49 lo ti ku bayii lẹyin ti wọn mu ọti ''monkey tail'' l'Ondo

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Ondo ti kede pe o ti di eeyan mọkandinlaadọta to ti ku bayii lẹyin ti wọn mu ogogoro ''monkey tail'' nipinlẹ naa.

Ijọba ni eeyan aadọsan ni akọsilẹ fi han pe ọti naa ṣe akoba fun kaakiri ipinlẹ Ondo.

Iṣẹlẹ naa to kọkọ waye Araromi-Obu ati Odigbo ni ijọba ibilẹ Odigbo ti de ijọba ibilẹ Irele bayii nibi ti a gbọ pe eeyan mẹjọ ti ku.

Alaga ijọba ibilẹ Odigbo, Ọgbẹni Taiwo Adegoroye, ti sọ ṣaaju wi pe eeyan mẹjo lo ku ni Araromi-Obi nigba ti eeyan mẹrindinlogun jade laye ni Odigbo.

Amọ, awọn to ti ku bayii ti di mọkadinlaadọta gẹgẹ bi iroyin to jade nirọlẹ ana Ọjọru.

Kọmiṣọna fun eto ilera nipinlẹ Ondo, Dokita Banji Ajaka, naa fidi rẹ mulẹ pe awọn eeyan ti ọti naa ti ṣakoba fun tun ti pọ si i.

Dokita Ajaka ni ọpọ eeyan ni ọti yii ṣẹṣẹ sẹkupa nijọba ibilẹ Irele; o fikun ọrọ rẹ pe eeyan mẹjọ lo ku lalẹ ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii.

Ìjọba fi fòfin de títa ọtí tí kò bá ní nọ́mbà NAFDAC lára l'Ondo

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Ondo fofin de tita gbogbo oniruuru ọti lile ati awọn miran to n gba ẹnu wọle sinu ara, eyi ti ko ba ti ni ontẹ ajọ to n ṣakoso ounjẹ ati oogun lilo, iyẹn NAFDAC.

Igbesẹ yii lo waye lẹyin iku awọn ti ko din ni ọgbọn, to waye laipẹ yii nipinlẹ naa.

Atẹjade ti kọmiṣanna feto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ naa, Idowu Ajanaku fi sita lọjọ Abamẹta to kọja fidi rẹ mulẹ pe igbesẹ naa waye lati dẹkun iku awọn araalu lọna aitọ.

Ajanaku sọ pe iku awọn eeyan ọgbọn naa lo nii ṣe pẹlu ọti lile ti wọn mu, to si lawọn ko tun gbọdọ jẹ ko tan kaakiri ipinlẹ ọhun.

O tun fidi rẹ mulẹ pe igbesẹ naa waye lẹyin ti kọmiṣanna feto ilera, Dokita Banji Awolowo-Ajaka fidi rẹ mulẹ pe eeyan mọkandinlọgbọn ku lẹyin ti wọn mu ọti lile tan, ati pe iṣẹle to to ọgọta iru rẹ ni awọn ti ṣe akọsilẹ rẹ.

Kọmiṣanna feto ilera sọ pe awọn mẹta lo ti wa lori bẹẹdi, nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ, nigba ti wọn n wo iṣesi awọn mẹtadinlọgbọn miran.

O ni ida marundinlaadọrun awọn ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si ni wọn jẹ ọkunrin ti wọn wa laaarin ọdun mẹrindinlogun si marundinlọgọta.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe awọn agbegbe bii Orita Odigbo, Araromi-Obu, Newtown, Odole, Okele ati Oniparaga ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Ajaka tun fi kun ọrọ rẹ pe awọn aisan bii ori fifọ, ara riro, irẹwẹsi ara, ailẹ min daadaa ati awọn miran lo jẹyọ lara awọn eeyan naa.

O ni ọrọ ilera awọn miran tete yiwọ patapata, leyi to ṣokunfa iku wọn laarin wakati perete.