'Bàbá' jáde láyé l'Aafin Ọba Oyo lẹ́ni ọdún 420

Ijapa ati Geeti Alaafin Oyo ninu ayika eweko

Oríṣun àwòrán, @Aafin

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

‎Alukoro aafin Alaafin ti ilu Oyo,Bode Durojaiye ti Kede iku "Baba' lẹyin ti o ṣe aiṣan to ko si fẹ jẹun mo.

‎Baba jẹ ijapa to ti wa ninu aafin ti Alaafin ti ilu Oyo lati ọdun ogun ọdun le ni irinwo ṣẹyin.

‎Gẹgẹ bi Bode Durojaiye, Oludari ẹka iroyin ati ipolongo fun Alaafin (Oba Abimbola Akeem Owoade I) ṣe sọ, Baba ku ni ọjọ aiku ni aafin alaafin ni Oyo .

‎Bo tile jẹ wi pe ṣaaju ikede yii, ọpọ eeyan ni ko mọ wi pe ijapa to too ọdun 420 wa ninu aafin Alaafin ti ilu Oyo.

‎Durojaiye ṣalaye wi pe,itan atẹnudẹnu fidi rẹ mulẹ wi pe,ijapa naa ti wa ninu aafin Oyo lati igba ti ilu Oyo titun ti bẹẹrẹ,ti o si ti lọ saa pẹlu ọpọlọpọ awọn Ọba to ti jẹ nilu Oyo.

‎Baba leranko to dagba julọ ni ilẹ Yoruba.

‎Durojaiye ni "A ka Baba si ẹni ti ọ ti pẹ julọ ni ilu Oyo. Oun ni ẹranko ọsin tí Alaafin fẹran julọ.

‎ Oba to wa lori oye bayii ba a ni Aafin, nitori wi pa awọn ọba ti wọn ti jẹ ṣaaju rẹ ni wọn ti n tọju Baba,ti wọn si jogun rẹ gẹgẹ bí awọn ohun ini aafin to ṣe pataki".

‎Gẹgẹ bi o ṣe sọ, awọn itan atẹnudẹnu fi han pe lati Oyo-Ile—olu-ilu ijọba Oyo atijọ—ni Baba ti déme si Aafin yii.

‎Durojaye ṣalaye wi pe itan Baba ninu aafin ju ti ẹranko inu aafin lasan lọ,ọ durọ fún apa kan ninu itan aafin ti alaafin ilu Oyo.

‎Oni Baba ṣaaju ko to ku ni ẹranko to pẹ julọ ninu gbogbo awọn ẹranko to wa ni ilẹ Yoruba .

‎Paula Gomez ṣalaye wi pe inu aafin ni wọn sin Baba si,ti wọn si ṣe ayẹyẹ idaro fun.