"Ìyá àgbà dá abẹ́ fún ọmọ mi obìnrin láìjẹ́ kí n mọ̀ nípa rẹ̀, torí pé àwọn ọkùnrin máa ń fi obìnrin tí kò bá dá abẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́"

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
- Author, José Carlos Cueto
- Role, BBC News Mundo reporting from Colombia
- Published
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8
Ninu ohun ti awọn ajafẹtọọ n pe ni aṣeyọri pataki ninu ilosiwaju, Colombia lọsẹ to kọja ni wọn jẹ orileede akọkọ nilẹ Latin America lati sọ ikọla fawọn ọmọbinrin di eewọ ti ko ba ofin mu.
Gẹgẹ bi José Carlos Cueto ṣe gbe e jade, nigba ti wọn gbe aba naa sita nile aṣofin Colombia, ọpọ ariyanjiyan lo waye fifi opin si ohun ti wọn lo lewu pupọ naa.
Ọmọ Carla Quiñonez's ṣẹṣẹ pe oṣu mẹfa ni, nigba ti mama agba rẹ lọ da abẹ fun, eyi ti wọn pe ni Female Genital Mutilation.
Quiñonez (ti kii ṣe ojulowo orukọ rẹ) sọ pe mama agba oun da ọmọ ọhun pada foun, o ni aisan iba lara, bẹẹ ni ara rẹ wu, to si tun n da ẹjẹ labẹ.
Gbogbo igba lo n sunkun.
"Mo koju mama agba mi, ṣugbọn o sọ pe ohun to dara ni, ati pe nko le sọ fun ẹnikẹni."
Ile iwosan ti a le sọ pe o sunmọ jinna rere, fun idi eyi, iya Quiñonez, ẹni to jẹ agbẹbi, gbiyanju lati din irora ọmọ naa ku nipa fifun un ni oogun ati agbo.
O tun dojukọ iya agba naa lati tako o. Ṣugbọn iya agba yii ko kilẹ dahun.
"O sọ pe awọn ọkunrin maa n fi awọn obinrin ti wọn ko ba kọ nila ṣe yẹyẹ ni."
Ikọla nilẹ Colombia

Ewu to wa ninu abẹ dida fawọn obinrin
Ikọla fawọn ọmọbinrin jẹ yiyọ apa kan tabi gbogbo ẹya ara ibimọ obinrin to wa nita kuro, tabi fifi awọn ipalara miran ṣe awọn ẹa ara wọnyi fun awọn idi ti kii ṣe itọju ilera.
Ikọla obinrin le fa awọn iṣoro ailera, titi kan ẹjẹ aisan pupọ ati akoran, to si tun le fa awọn iṣoro miran ni ọjọ iwaju lasiko nnkan oṣu ati nigba ibimọ. O tun le jẹ ki o ṣoro fun obinrin lati ni imọlara ayọ lasiko ibalopọ.
Ajọ eleto ilera agbaye (WHO) sọ pe kaakiri agbaye, ọmọbinrin ati obinrin ti ko ni din ọgbọn-le-ni-igba (230m) ọmọbinrin to ṣi wa laaye lonii ni wọn ti kọ nila, ti ọpọ wọn si jẹ lati ilẹ Afrika.
Quiñonez, ẹni ọgbọn ọdun ti bẹrẹ iṣẹ takuntakun lati rii pe ikọla fọmọbinrin di ohun igbagbe patapata nilẹ COlombia, nibi ti awọn kan lara awọn ọmọ ẹgbẹ Emberá ṣe ti n ṣe e.
Pẹlu awọn ajafẹtọọ bii tiẹ ati awọn aṣofin ilẹ Colombia, o kopa gidigidi ninu ipolongo lati fi opin si ikọla naa, leyi to jẹ ki wọn gbesẹ le aṣa naa patapata labẹ ofin.
O sọ pe boun ṣe n dagba lojoojumọ, loun bẹrẹ sii mọ awọn ohun ikọkọ to n ṣẹlẹ.
"O maa n ṣe mi ni kayeefi ni gbogbo igba nipa idi ti awọn ọmọdebinrin ṣe maa n ku ṣaaju awọn ọmọdekunrin ni lẹyin ibimọ.
"Mo ranti ọmọ ibatan mi kan ti iya mi ṣe iranlọwọ fun nigba ti wọn bi i. Ọmọ naa ni wọn bi pẹlu alaafia pipe, ṣugbọn ọmọ naa ku lẹyin ọjọ mẹta.
"Mo bi iya mi leere nipa rẹ, o si sọ fun mi pe ọmọ naa ku nitori aisa 'jai', to jẹ aisan irandiran."
Ni bayii, Quiñonez gbagbọ pe awọn ọmọbinrin ti wọn sọ pe wọn n ku pẹlu aisan 'jai' yii, iṣoro ti wọn n koju lẹyin ikọla ọmọbinrin lo n fa a.
Ojú ìwòye dókíta àwọn ọmọdé

Oríṣun àwòrán, Courtesy of Diana Ramos / Photo by David Jiménez
Laaarin ọdun 2020 si oṣu Kẹfa, ọdun 2026, akọsilẹ ogoji-le-nigba (240) ni wọn ṣe nipa ikọla yii lorileede Colombia. Ninu ọpọ awọn iṣẹlẹ wọnyi, awọn ọmọbinrin lo jẹ pe wọn ko din ni ọdun mẹfa. Ṣugbọn Diana Ramos sọ pe oun nigbagba pe "kere lasan ni eyi." ninu awọn iṣẹlẹ naa.
Nibi iṣẹ rẹ nile iwosan fasiti San Jorge to wa ni Pereira, ilu kan ni ẹkun Ila-Oorun Ariwa Colombia ti wọn ti n gbin Kọfi, o loun ti ri awọn apẹẹrẹ ohun to ba ni lẹru, bi ki nnkan maa jona, ko si maa jẹra nigba ti wọn ba n ṣayẹwo fawọn ọmọbinrin ti wọn n gbe wa lori ipenija ailera.
O ranti ọmọbinrin kan ti wọn mu wa, ti oju abẹ rẹ ti di pa patapata, leyi to tunmọ si pe ko le ṣe nnkan oṣu, bẹẹ si ni ko le ni ibalopọ lasiko to ba to asiko.
"O ni lati ṣe iṣẹ abẹ atunṣe oju ara," Dokita Ramos sọ bẹẹ.
O ka ikọla ọmọbinrin si iru iwa ipa to da lori akọ tabi abo, ati iwa ipa si ẹya ara ibalopọ, eyi to le ni abajade buburu fun ẹni naa titi lai. SIbẹ, o sọ pe ọna to dara julọ lati koju iṣoro naa ni nipasẹ ẹkọ ati imọlara awọn eeyan, kii ṣe nipasẹ ijiya nikan.
"Lara awọn eeyan to n gbe lagbegbe yii gbagbọ pe awọn ko ṣe nnkan ipanilara," o fi kun ọrọ rẹ.
'Aṣa kii paayan'

Oríṣun àwòrán, José Carlos Cueto / BBC Mundo
Bii ẹgbẹrun lọna ọọdunrun ọmọ ilẹ Emberá, wa lara awọn ọmọ ibilẹ to pọ julọ lorileede Colombia, ti ninu wọn si n gbe ni orileede Ecuador ati Panama.
Ọkan lara awọn alaya abajade nipa bi awọn eeyan yii ṣe n ṣe ikọla ọmọbinrin ni, nigba ti wọn kii fi bẹẹ ri lawọn agbegbe miran ni Latim America, ni pe asiko ikonilẹru nilẹ Afrika ni wọn bẹrẹ aṣa ọhun.
Eyi si le ṣalaye nipa idi ti aṣa naa fi wọpọ ni Risaralda, Chocó ati Valle del Cauca, ilu odikeji to fẹẹ dabi ile fun ọọ awọn ara Afro-Colombian to sunmọ wọn.
Alaye miran ni pe bibi ọmọ kan kan ni ọgọrun ọdun sẹyin mu ki ibẹru ẹya ara obinrin ti a mọ si 'Clitoris' wọ inu awujọ naa. Ọpọ awọn agbalagba obinrin gbagbọ pe ẹya ara naa le dagba lati di nnkan ọmọkunrin bi wọn ko ba ge e.
Awọn miran lero wi pe bi wọn ba ko ba ge e kuro, o ṣe e ki obinrin to ba kudun ibalopọ bẹrẹ iṣẹ aṣẹwo
Bo tilẹ wu ki ipilẹ rẹ ri, , Juliana Domico to jẹ aṣoju ofin ati oludamọran agba fun awọn ọmọ ibilẹ ni ajọ apapọ ilẹ Emberá Colombia, kọ ero naa pe aṣa ikọla obinrin jẹ apa kan ninu aṣa ibilẹ awọn.
"Aṣa wa ni aṣọ ibilẹ wa, iṣẹ ọna ọwọ wa, awọn ijo ati ede abinibi wa, kii ṣe aṣa to n paaya. Aṣa kii paayan."
O tun sọ pe "A ni ireti pe wọn maa yi ofin naa pada si awọn ilana ijọba to le e ṣiṣẹ, ti wọn si maa pese awọn ohun elo ati owo to to lati mu un ṣe."
Ìhàlẹ̀ àti ìkórìíra

Quiñonez wa lara awọn to n ja fun ayipada, ṣugbọn to ni oniruuru idunkooko loun ti ri gba - paapaa lati ọdọ awọn ọkunrin.
Bo tilẹ pe ni ti ibilẹ, kii ṣe fun awọn ọkunrin lati mọ nipa rẹ, ọpọ igba ni awọn ijiroro nipa bi a ṣe le fopin si maa n waye pẹlu awọn olori ọkunrin nikan. Idi ni pe ọpọ awọn obinrin Emberá n sọ ede ibilẹ wọn, ti wọn tun n pe ni Emberá, ti wọn ko si kọ ede Spanish dandan.
Eyi tun le di awọ obinrin yii lọwọ lati ri iranlọwọ dokiyta fun awọn ọmọ wọn, iṣoro ti Quiñonez sọ pe o n buru sii nigba ti wọn ba pade awọn oṣiṣẹ ilera kan ti ko ni imọ to pe lori rẹ.
O sọ pe nigba toun mu ọmọbinrin oun lọ sile iwosan fun aisan iba to wọle lati oju ara rẹ, nọọsi to da a lohun bu ẹnu atẹ lu u, to si sọ fun un pe ohun ti oju rẹ wa, loju rẹ ri.
"Wọn tun dunkooko mọ mi nigba ti mo mu ọmọ mi kuro nibẹ, ti mo si muu lọ sibi ti wọn ti n tọju awọn ọmọde.
"Latigba naa, o tẹ mi lọrun ki n ma ṣe u ọmọbinrin mi lọ sile iwosan. Mo n tọju rẹ funra mi, ti mo si n fun un loogun. Nko figba kan kuro legbẹ rẹ."
A kò lè yàgò fún ìjíròrò

Oríṣun àwòrán, AFP via Getty Images
Quiñonezsọ pe ayipada ti n waye laaarin agbegbe Emberá, pẹlu awọn obinrin ṣe n ti nse ijiroro laarin ara awọn boya ki wọn gba aṣẹ ijọba apapọ, tabi ki wọn ṣi maa ṣe ikọla ọmọbinrin lọ.
O sọ pe oun yoo gbe igbesẹ nigba ti iya agba kan ba tun ṣe ikọla fun awọn ọmọ-ọmọ rẹ. "O sọ pe ko tii ṣe ohunkohun lori ero buburu, ati pe oun kan n fẹ lati dena awọn ọkunrin to n bu ẹnu atẹ lu awọn ọmọ-ọmọ oun."
NIpa ijiroro ori bi ile aye ṣe le lekoko to, o ni, "Awọn obinrin ti wọn ti dagba lai ni ohun ti wọn n pe ni 'clitoris', ko le ni imọlara iru ara miran."
"Yoo tun ṣoro lati ba awọn ọmọ rẹ sọrọ nipa rẹ, lọjọ kan lọjọ iwaju, "ṣugbọn o jẹ ijiroro ti ko ṣee sa fun," o ṣalaye.
"Gbogbo wa la ni lati ni oye bi ara wa ṣe ri, ka si le sọrọ lee lori lai ni itiju kankan."



























