Temitope Osoba, òṣèré tíátà jáde láyé

Oloogbe Temitope Osoba

Oríṣun àwòrán, Osoba Temitope/Instagram

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Temitope Osoba
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Iroyin ibanujẹ mii tun ti ṣẹyọ lagbo tiata Yoruba, Temitope Esther Koworola Osoba ti jade laye.

Owurọ kutu Ọjọru, ọjọ karun-un oṣu Keje ọdun 2026 yii ni oṣere tiata bii tiẹ, Alesh Sanni, kede iku Tope Osoba loju opo Instagram rẹ.

Lasiko ti a n kọ iroyin yii, a ko ti I le fidi ohun to pa gbajumọ oṣerebinrin naa mulẹ.

"Mi o le sun latigba ti mo ti gbọ iku rẹ lale ana"

Bi Alesh to kede iku naa ṣe gbe e jade lo kọ ọrọ aro soju opo naa pe:

"Mi o le sun latigba ti mo ti gbọ iku rẹ lalẹ ana, ko buru o. Sun ire o, arabinrin mi ọwọn, Temitope Osoba."

O fi kun un pe awọn jọ lo igba, awọn si jọ ni awọn iriri ti ko ṣee gbagbe. Amọ o ti tan bayii, oun ko tiẹ mọ ohun ti oun le sọ.

Ta a ni Tope Osoba?

Oloogbe Tope Osoba

Oríṣun àwòrán, Tope Osoba/Instagram

Gbajumọ oṣere ni Oloogbe Temitope Osoba, ọmọ ilu Abeokuta nipinlẹ Ogun si ni.

O ti kopa ninu ọpọlọpọ iṣẹ ori itage lede Yoruba ati oyinbo, bẹẹ lo si n ṣe pupọ ninu ere igbalode ti a mọ si Skit.

Nnkan bii ọdun meji sẹyin ni Tope Osoba lugbadi aisan jẹjẹrẹ ọmu, nigba to kede pe oun ri apẹẹrẹ koko kekere kan ninu ọmu naa.

Oṣere naa kede pe oun lọ sileewosan, wọn si fidi ẹ mulẹ pe wọn ni lati yọ koko ọyan naa pẹlu iṣẹ abẹ.

O pada bẹbẹ owo lọwọ awọn ọmọ Naijiria lati fi ṣiṣẹ abẹ naa, wọn si yọ ọ .

Loṣu Keji ọdun 2025 ni BBC News Yoruba ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun Oloogbe Tope Osoba, o si ṣalaye nigba naa pe ko wu oun lati tọrọ owo nita gbangba, amọ nigba ti ko si ọna miran, ti owo naa si gbọdọ pe lo mu oun gbe bẹbẹ iranlọwọ naa.