Ìjọba Nàìjíríà mókè lórí àkànṣe iṣẹ́ iná tí ìrétí wà pé yóò máa pèsè mẹ́gáwáàtì 1,500

Awọn ohun ipese ti eeyan kan n kọja labẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ile ẹjọ to n ri si ọrọ okoowo lagbaaye iyẹn International Chamber of Commerce ti da ijọba Naijiria lare lori igbẹjọ to nii ṣe pẹlu kikọ ileeṣẹ ti yoo maa pese ina mọnamọna Mambilla si ipinlẹ Taraba.

Ile ẹjọ naa kọ ẹjọ ti ileeṣẹ Sunrise Power pe tako ijọba Naijiria lori akanṣe iṣẹ naa.

Ohun ti ileeṣẹ naa n beere lọwọ ijọba Naijiria nile ẹjọ ni owo $680m gẹgẹ bi owo gba mabinu lori akanṣe iṣẹ naa amọ ti ile ẹjọ ti wa da ibeere ileeṣẹ naa nu.

Atẹjade ti Aarẹ Bola Tinubu fi lede ṣalaye pe ile ẹjọ naa tun da $400m ti ileeṣẹ naa n beere lọwọ ijọba Naijiria nu, ti ile ẹjọ si paṣẹ pe ki ileeṣe Sunrise ati Leno Adesanya da ida marundinlọgọrin lara owo ti ijọba Naijiria ti na lori ẹjọ naa pada ti apapọ rẹ jẹ $11.8m.

Ifanfa to n waye laaarin ijọba Naijiria ati ileeṣẹ Sunrise Power lori akanṣe iṣẹ Mambilla lo ti bẹrẹ lati ọdun 2003 nigba ti wọn fẹnuko lori kikọ akanṣẹ iṣẹ mọnamọna naa si Taraba.

Aarẹ Tinubu sọ pe igbimọ alaṣẹ Naijiria ko buwọlu akanṣe iṣẹ naa.

Lati ọpọ ọdun sẹyin ti wọn ti n gbero lori iṣẹ ina yii ṣugbọn awọn igbẹjọ to wa lori rẹ ni ko jẹ ki wọn tẹsiwaju.

Ni ibẹrẹ pẹpẹ, akanṣe iṣẹ naa ni erongba wa pe o maa pese mẹgawaati ina mọnamọna 3,960 ti o ba pari amọ ti wọn ti dinku si mẹgawaati 1,500 bayii.

Tinubu sọ pe idajọ ile ẹjọ yii jẹ igbesẹ nla si fifi opin si awọn ifanfa to n waye lori iṣẹ naa.

O fi kun pe idajọ naa ti fopin si ipenija nla to n mu ikurẹtẹ ba akanṣe iṣẹ Mambilla fun ọpọ ọdun ati pe o maa mu igbooro ba ina ọba Naijiria sii.

O tẹsiwaju pe ijọba Naijiria yoo tunbọ maa da aabo bo ara rẹ lọwọ awọn to ba fẹ maa gbe igbesẹ ti ko tọ wọle, ti awọn yoo si maa fun awọn oludokoowo to ba duro deedee ni anfaani lati dokoowo si orile ede yii.

Bakan naa ni Aarẹ Tinubu tun dupẹ lọwọ awọn aarẹ tẹlẹ ri, Olusegun Obasanjo ati Muhammadu Buhari ti wọn lọ jẹrii lasiko igbejọ naa atawọn agbẹjẹro ti wọn ṣiṣẹ lori ẹjọ naa.

Anfaani wo Naijiria yoo jẹ lori akanṣe iṣẹ yii?

Fun ọpọlọpọ ọdun ni Naijiria ti n koju idakureku ina ọba. Oniruuru ipenija lo n koju ẹka ohun amuṣagbara Naijiria to fi mọ awọn ohun elo to ti gbo, aile ṣakojọ awọn ina to pọ to, aisi ipese gaasi ti bo ṣe yẹ.

Bakan naa ni pinpin ina ati ilana ti wọn n gba pin jẹ ipenija ti Naijiria n koju titi di asiko eyi to mu ki ijọba gbe pupọ lara ẹka ina ta fawọn ileeṣẹ aladani.

Amọ sibẹ, pẹlu bi Naijiria ṣe jẹ orilẹ ede ti ọrọ aje rẹ gbooro julọ ni ilẹ Africa, ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria ni ko ri ina ọba lo to bo ṣe yẹ, ti ọpọ si maa n gbarale jẹnẹretọ tabi ẹrọ to n lo oorun lati fi pes eina.

Ọpọ ilana ati idokoowo ni ijọba tig be kalẹ lati mu atunto ba ina ọba amọ ti gbogbo rẹ ti fori sọpan.

Igbagbọ wa pe gbogbo awọn ipenija yii ni adinku maa ba nigba ti wọn ba pari akanṣe iṣẹ Mambilla.

Eyi to tumọ si o maa mu igbooro ba ina mọnamọna paapaa ni awọn agbegbe to sunmọ ibi ti akanṣe iṣẹ naa wa.