Idà ahun ti pa ahun! Àdó olóró bú, pa ọ̀pọ̀ ọmọ ẹgbẹ́ ISWAP lásìkò tí wọn n to àdó ikú papọ̀ láti kọlu iléeṣẹ́ ológun

Awọn ọmọ ogun ISWAP

Oríṣun àwòrán, intelregion

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi Islamic State West Africa Province (ISWAP) marun un, ẹnikan ti wọn pe ni oṣiṣẹ eto ilera wọn ati akọmọsẹ ninu ado oloro ṣiṣe mẹrin ti gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra ni ijọba ibilẹ Marte, nipinlẹ Borno.

Iroyin ni ado oloro ti wọn fẹ lọ fi ṣọṣẹ lagbegbe kan nibẹ lo bu gbamu lasiko ti wọn ko tii ṣetan fun ikọlu ti wọn n lọ ṣe.

Onimọ nipa ọrọ abo kan, Zagazola Makama, sọ pe lọjọ Iṣẹgun pe agbegbe Maina Daya, to wa laarin Sabon Tumbu ati Jubilaram, ti ko fi bẹẹ jina si ijọba ibilẹ Monguno ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.

A gbọ pe ado oloro naa gbẹmi Usman Dan Fulani, to jẹ dokita ISWAP ati awọn ọmọ ilẹ Arab ti wọn jẹ ogbontarigi ninu ado oloro agbelẹrọ ṣiṣẹ.

Awọn ọmọ ogun ni wọn fẹ lọ kọlu, ki ado oloro ọhun to bu mọ wọn lọwọ

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, awọn ọmọ ogun Naijiria ti wọn wa ni ẹka Sector 1 ti Operation HADIN KAI ni wọn fẹ lọ kọlu ki ado oloro ọhun to bu mọ wọn lọwọ.

Awọn onimọ nipa eto abo gbagbọ pe iku awọn eeyan naa yoo mu ifasẹyin ba akitiyan awọn agbesunmọmi to n kogun ja agbegbe Marte si Monguno fun igba diẹ.

Awọn iroyin kan ti a ko le fidi rẹ mulẹ sọ pe aṣẹ ti jade si awọn ologun Operation HADIN KAI lati jawe sobi lilepa awọn agbesunmọmi agbegbe naa lẹyin iṣẹlẹ ọhun.

Iroyin naa sọ pe awọn ologun ti bẹrẹ si n kaakiri awọn agbegbe Monguno, Marte, ati Gamboru Ngala lati dẹkun awọn agbesunmọmi mii ti yoo gbiyanju lati ṣọṣẹ lawọn agbegbe ọhun.

Ọpọ aṣeyọri ni ileesẹ ologun Naijiria ti ṣe lẹnu lọlọ yii.

Ti ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni ileeṣẹ naa ṣe aṣoyọri gbigbẹmi ọkan gboogi lara awọn adari ISWAP lagbegbe Lake Chad, eyii ti wọn ṣe ni ifọwọsowọpọ pẹlu ileeṣẹ ologun ilẹ Amẹrika.

Ni nnkan bii ọsẹ meji nsẹyin naa tun ni olori awọn to n ṣeranwọ owo fun ISWAP pẹlu awọn ọmọ rẹ ọkunrin jọwọ ara fun ileeṣẹ ologun.