Ìpinyà láàárín Toyin àti Kolawole? Ohun tí a mọ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, ToyinAbraham/Instagram
Agba oṣere nni, Toyin Abraham ti sọrọ lori iroyin to n lọ lori ayelujara pe igbeyawo oun ati ọkọ rẹ, Kolawole Ajeyemi ti tuka.
Ni ọjọru ni ọkan lara awọn to maa n gbe iroyin lori ayelujara, Fatitell Gist kọ soju opo Instagram rẹ pe kudiẹkudiẹ ti n waye ninu igbeyawo Toyin Abraham ati ọkọ rẹ ati pe Toyin ti ko jade nile lọ si ile tuntun kan to ṣẹṣẹ kọ.
O kọ soju opo rẹ naa pe awuyewuye to ṣi n lọ labẹnu ni iroyin naa ati pe eeyan kan ti orukọ rẹ n jẹ Bukky Jesse lo kọkọ gbe iroyin naa sita pe aarin Toyin ati ọkọ rẹ ko danmọran mọ.
Amọ Toyin Abraham ti wa fesi si ahesọ ọrọ naa pẹlu esi to fi sabẹ iroyin ti Fatitell Gist gbe sita naa.
Toyin kọ sabẹ iroyin naa pe "a kọ lorukọ baba, ọmọ ati ẹmi mimọ, ori wa kọ ọ, ẹlẹdaa wa kọ ọ."
Esi Toyin Abraham ṣafihan pe ahesọ ọrọ lasan ni iroyin ati pe irọ to jina si ootọ ni pe igbeyawo wọn n koju wahala tabi pe awọn mejeeji ti pinya.
Agba oṣere naa tun kọ pe ipinya ko si ninu irinajo oun ati ọkọ oun nitori oun ko gbadura fun ituka laaarin oun ọkọ oun ati pe oun n fi adura jagun fun idile naa.
Igba akọkọ kọ niyi tawọn tọkọtaya naa yoo ma kojun irufẹ iroyin bayii.
Ọpọ igba ni wọn ti gbe iroyin pe igbeyawo Toyin ati ọkọ rẹ, ti oun naa jẹ agba oṣere, ti fori ṣọpọn ṣugbọn ti awọn ololufẹ mejeeji yoo tako iroyin bẹẹ.
Ni ọdun 2019 ni Toyin ati Kolawole ṣe igbeyawo ranpẹ ni ilana ibilẹ lẹyin ti awọn mejeeji ti ṣe ọrẹ fun ọpọ ọdun lagbole ere sinima Yoruba.
Lẹyin igbeyawo naa ni tọkọtaya ọhun bi ọmọ ọkunrin ti wọn pe orukọ rẹ ni Ire.
Ṣaaju igbeyawo naa ni Kolawole ti bi ọmọbinrin kan eyi ti Toyin maa n pe ni akọbi rẹ, to si maa n sọ pe ọmọ meji ni Ọlọrun fi kẹ igbeyawo awọn.

























