Igun méjì ṣè'wọ́de lórí ẹ̀ṣọ́ ààbò Ìrù Ẹkùn n'Ibadan, àwọn kan fẹ́, àwọn kan ta kò ó

Awọn to faramọ idasilẹ Iru Ẹkun nilẹẹ Yoruba gbe akọle to n kede bẹẹ dani lapa osi ninu aworan yii, nigba ti awon to ta ko o wa lapa ọtun pẹlu akọle tiwọn naa.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ana ode yii ti i ṣe ọjọ Ẹti, ọjọ kejidinlogun oṣu Kẹsan-an ọdun 2026 ni iwọde iyanu kan waye niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo.

Iwaju ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Oyo to wa ni Agodi, niluu Ibadan ni igun meji korajọ si, ti awọn kan n sọ pe awọn fẹ ki i ẹṣọ alaabo Iru Ẹkun ti Oloye Sunday Adeyemo (Igboho Ooṣa) da silẹ maa tẹsiwaju nilẹẹ Yoruba.

Bakan naa ni igun mi-in si tun kora jọ si agbegbe yii kan naa, ti wọn ni awọn ko fẹ Iru Ẹkun, ki Igboho maa gbe kẹkẹ ẹgbẹ rẹ naa lọ.

Awijare awọn to faramọ Iru Ẹkun

BBC News Yoruba wa nibi iṣẹlẹ naa, a si ba igun mejeeji sọrọ.

Ninu alaye Abilekọ Omotolani Alade, ẹni to jẹ ọkan lara awọn to ni awọn fẹ ki Iru Ẹkun maa ba iṣẹ rẹ lọ nilẹe Yoruba, o ni:

"Mo faramọ Iru Ẹkun, tori ijinigbe to n waye nilẹẹ Yoruba ti pọju, ijọba nikan ko si le da gbọ ọrọ eto aabo Naijiria."

Obinrin naa tẹsiwaju pe Oloye Sunday Igboho jade lati gba gbogbo ọmọ Yoruba silẹ lọwọ awọn ajinigbe ti wọn n yọ awọn ọmọ Yoruba lẹnu ni, bẹẹ lo ṣe e ladura pe Ọlọrun a maa se atilẹyin fun Igboho.

"Awọn ti ki i ṣe ọmọ Yoruba atata ni ko nifẹẹ si Iru Ẹkun"

Bakan naa ni ọkunrin kan to pe orukọ rẹ ni Abdrafiu Olajuwon, ṣalaye pe gbogbo awọn eeyan to n sọ pe awọn ko fẹ Iru Ẹkun ki i ṣe ọmọ Yoruba atata, o ni iran atọhunrinwa ni wọn.

O fi kun pe ẹ̀rú lo n ba wọn nitori wọn mọ pe Sunday Igboho ko ni i gba wọn laye lati ma huwa ijinigbe ati ipaniyan.

Eyi lo ni o jẹ ki wọn ma sọ pe awọn ko faramọ Iru Ẹkun.

"Mo faramọ Iru Ẹkun niwọn igba ti ko ba ti tako ẹsin kankan"

Olatunbosun Nurudeen,ọkan lara awọn oluwọde to faramọ Iru Ẹkun, salaye pe ohun faramọ ikọ naa niwọn igba ti ko ba ti tako ẹṣin kankan.

O ni latigba ti Sunday Igboho ti da iko Iru Ẹkun silẹ nilẹẹ Yoruba ni alaafia ti n jọba.

Ọgbẹni Nurudeen wa rọ Oloye Sunday Igboho lati ba awọn ọmọ lẹhin rẹ sọrọ lati ma tako ẹṣin kankan.

O ni ki wọn koju awọn oniwakiwa nilẹẹ Yoruba ni.

"Mi o faramọ Iru Ẹkun, ẹni to da a silẹ n tako ẹsin Islam"

Ọkan lara awọn to tako idasilẹ Iru Ẹkun nibi iwọde naa

Lara awọn oluwọde to tako idasilẹ Iru Ẹkun nilẹe Yoruba nibi iwọde naa ni Ọgbẹni Alimi Ismail.

Ọkunrin yii ṣalaye fun BBC pe oun ko faramọ idasilẹ ikọ alaabo yii nitori ẹni to da ẹgbẹ naa silẹ n ta ko ẹṣin Islam, ti ko si yẹ ko ri bẹẹ.

O fi kun un pe awọn ẹṣọ alaabo to wa lorilẹ ede Naijiria n ṣiṣẹ wọn bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.

Alimi sọ pe wọn ko tako ẹya tabi ẹsin kankan lẹnu iṣẹ wọn, eyi si ti to fun Naijiria bo ṣe wi.

O wa rọ ijọba apapọ ati ijọba ipinlẹ lati fopin si ikọ Iru Ẹkun yii, ko ma baa da ija ẹṣin silẹ lorilede yii.