Àlàyé lórí bí iléẹjọ́ ICC ṣe fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé agbẹjọ́rò àgbà tẹ́lẹ̀ Malami tako Naijiria lórí ẹjọ́ ilé-iṣẹ́ amúnáwa Mambilla

Abubakar Malami wọ agbada funfun ati fila

Oríṣun àwòrán, EFCC/Getty images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ile ẹjọ to n ri si ọrọ okoowo lagbaaye iyẹn International Chamber of Commerce, ICC, ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé agbẹjọ́rò àgbà àti minisita eto ìdájọ ni Naijiria tẹlẹ, Abubakar Malami, tako nnkan ti orilẹede Naijiria fẹ lori ẹjọ ileeṣẹ amunawa Mambilla.

Igbimọ igbẹjọ náà to gbe ìdájọ rẹ kalẹ niluu Paris yi ẹjọ ti ileeṣẹ Sunrise Power and Transmission pe ijọba Naijiria danu.

Igbimọ ICC dajọ wi pe Malami ati Saleh Mamman to jẹ minisita ohun amusagbara nigba naa ko ni aṣẹ lati sọ pe ki ìjọba àpapọ̀ mu adehun t'awọn kan buwọ́lu laarin oṣu Kínní sí oṣù Kẹta ọdún 2020 eyi ti ààrẹ Naijiria ko fòntẹ̀ lu ṣẹ.

Ifanfa to n waye laaarin ijọba Naijiria ati ileeṣẹ Sunrise Power lori akanṣe iṣẹ Mambilla lo ti bẹrẹ lati ọdun 2003 nigba ti wọn fẹnuko lori kikọ akanṣẹ iṣẹ mọnamọna naa si Taraba.

Aarẹ Tinubu sọ pe igbimọ alaṣẹ Naijiria ko buwọlu akanṣe iṣẹ naa.

Lati ọpọ ọdun sẹyin ti wọn ti n gbero lori iṣẹ ina yii ṣugbọn awọn igbẹjọ to wa lori rẹ ni ko jẹ ki wọn tẹsiwaju.

Ni ibẹrẹ pẹpẹ, akanṣe iṣẹ naa ni erongba wa pe o maa pese mẹgawaati ina mọnamọna 3,960 ti o ba pari amọ ti wọn ti dinku si mẹgawaati 1,500 bayii.

Ijokoo igbẹjọ naa sọ pé ìwà ajẹbanu lo jẹ k'awọn kan tọwọ bọwe adehun lorukọ ijoba Naijiria pẹlu ileeṣẹ Sunrise Power and Transmission, nigba ti ààrẹ Naijiria ko mọ ohun kan nipa adehun náà.

Ninu adehun tí Malami ati Mamman buwolu lorukọ ijoba, orilẹede Naijiria ni lati san $200m fun ileeṣẹ Sunrise lẹẹkan ṣoṣo.

Amọ, adehun mii to waye lọjọ keedogbon oṣù Kẹta sọ pe ìjọba sí le kọkọ san $100m ki wọn to san iyokù to bá ya.

Ṣugbọn aitẹle adehun yii yoo mu Naijiria san faini $200m.

Amọ, igbimọ igbẹjọ ICC fidi rẹ múlẹ pe Malami ko dúnàádúrà fun Naijiria bi ko ṣe fún ileeṣẹ Sunrise.

Ìjọba Nàìjíríà mókè lórí àkànṣe iṣẹ́ iná tí ìrétí wà pé yóò máa pèsè mẹ́gáwáàtì 1,500

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣaaju ni Ile ẹjọ to n ri si ọrọ okoowo lagbaaye iyẹn International Chamber of Commerce ti da ijọba Naijiria lare lori igbẹjọ to nii ṣe pẹlu kikọ ileeṣẹ ti yoo maa pese ina mọnamọna Mambilla si ipinlẹ Taraba.

Ile ẹjọ naa kọ ẹjọ ti ileeṣẹ Sunrise Power pe tako ijọba Naijiria lori akanṣe iṣẹ naa.

Ohun ti ileeṣẹ naa n beere lọwọ ijọba Naijiria nile ẹjọ ni owo $680m gẹgẹ bi owo gba mabinu lori akanṣe iṣẹ naa amọ ti ile ẹjọ ti wa da ibeere ileeṣẹ naa nu.

Atẹjade ti Aarẹ Bola Tinubu fi lede ṣalaye pe ile ẹjọ naa tun da $400m ti ileeṣẹ naa n beere lọwọ ijọba Naijiria nu, ti ile ẹjọ si paṣẹ pe ki ileeṣe Sunrise ati Leno Adesanya da ida marundinlọgọrin lara owo ti ijọba Naijiria ti na lori ẹjọ naa pada ti apapọ rẹ jẹ $11.8m.

Ifanfa to n waye laaarin ijọba Naijiria ati ileeṣẹ Sunrise Power lori akanṣe iṣẹ Mambilla lo ti bẹrẹ lati ọdun 2003 nigba ti wọn fẹnuko lori kikọ akanṣẹ iṣẹ mọnamọna naa si Taraba.

Aarẹ Tinubu sọ pe igbimọ alaṣẹ Naijiria ko buwọlu akanṣe iṣẹ naa.

Lati ọpọ ọdun sẹyin ti wọn ti n gbero lori iṣẹ ina yii ṣugbọn awọn igbẹjọ to wa lori rẹ ni ko jẹ ki wọn tẹsiwaju.

Ni ibẹrẹ pẹpẹ, akanṣe iṣẹ naa ni erongba wa pe o maa pese mẹgawaati ina mọnamọna 3,960 ti o ba pari amọ ti wọn ti dinku si mẹgawaati 1,500 bayii.

Tinubu sọ pe idajọ ile ẹjọ yii jẹ igbesẹ nla si fifi opin si awọn ifanfa to n waye lori iṣẹ naa.

O fi kun pe idajọ naa ti fopin si ipenija nla to n mu ikurẹtẹ ba akanṣe iṣẹ Mambilla fun ọpọ ọdun ati pe o maa mu igbooro ba ina ọba Naijiria sii.

O tẹsiwaju pe ijọba Naijiria yoo tunbọ maa da aabo bo ara rẹ lọwọ awọn to ba fẹ maa gbe igbesẹ ti ko tọ wọle, ti awọn yoo si maa fun awọn oludokoowo to ba duro deedee ni anfaani lati dokoowo si orile ede yii.

Bakan naa ni Aarẹ Tinubu tun dupẹ lọwọ awọn aarẹ tẹlẹ ri, Olusegun Obasanjo ati Muhammadu Buhari ti wọn lọ jẹrii lasiko igbejọ naa atawọn agbẹjẹro ti wọn ṣiṣẹ lori ẹjọ naa.