Wo kókó ohun tí Atiku bá àwọn ọmọ Nàìjíríà, Tinubu sọ nípa àlèkún tó ń bá owó epo bẹntiróòlù

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar/Facebook
Oludije sipo aarẹ Naijiria legbẹ oṣelu Africa Democratic Congress, ADC, Atiku Abubakar ti rọ aarẹ Naijiria, Bola Tinubu lati tete wa ọna lati mu adinku ba owo epo bẹntiroolu to tun gbẹnu soke lojuna ati mu adinku ba inira tawọn ọmọ Naijiria n koju.
Nibi ọrọ ti Atiku ba awọn ọmọ Naijiria sọ lọjọ Ẹti, ọjọ Kejidinlogun, oṣu Kẹsan-an ni o ti sọrọ nipa iye owo epo bẹntiroolu, awọn eto ibojuaanuwoni ati bi awọn araalu ṣe n gbe, to si sọ pe yiyọ iranwọ ori epo ti mu alekun ba owo tawọn eeyan fi n wọkọ, ounjẹ ati ipese ọja.
O sọ pe lati igba ti aarẹ ti gbapo lọjọ Kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 ni awọn eeyan ti n koju inira nitori ijọba ko pese awọn eto to maa mu idẹkun ba idile, awọn oṣiṣẹ, awọn agbe atawọn ileeṣẹ.
O woye pe bi owo epo bẹntiroolu ṣe n gbowo lori lo n kan gbogbo awọn ẹka yooku lori eto ọrọ aje to fi mọ owo ounjẹ, agbẹ okoowo ati bẹẹ bẹẹ lọ.
"Nigba ti epo ba ti gbowo lori, owo ọkọ maa lekun, owo ounjẹ maa lekun. Awọn agbẹ maa na owo to pọ lati gbe ere oko wọn de ọja, awọn ọlọja maa r ani ọwọn lọwọ awọn agbẹ, ti awọn oṣiṣẹ yoo si maa nao wo to pọ lati fi wọ ọkọ de ibiṣẹ.
"Nigbẹyin, ori awọn araalu ni gbogbo rẹ maa da le lori, ti ijọba ti mu ki ohun amuṣagbara wọn ju bi o ṣe yẹ lọ, igbe aye naa le le koko ni."
Atiku tun bu ẹnu atẹ lu bi ijọba ko ṣe da oun lohun lori ipe pe ki wọn mu adinku ba owo epo bẹntiroolu.
O ṣeranti pe ileeṣẹ aarẹ sọ pe oun ko nimọ lori iṣejọba ati ọrọ aje lo jẹ ki oun maa pe igbese naa ṣugbọn to ni bi awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ, awọn alagbata epo, awọn olupese ọja atawọn mii ṣe n pe fun nnkankan naa yii jẹ ko han pe oun ko ṣina.
"Nigba ti awọn oṣiṣẹ, awọn olupese ọja atawọn araalu ba ti n pe ijọba lori nnkan ẹyọ kan ṣoṣo, o yẹ ki ijọba gbọ ni."
"Mo yọnda a rẹ lati ṣamulo awọn ilana ati eto mi"
Atiku, ẹni to ti figba kan ri jẹ igbakeji aarẹ Naijiria fun ọdun mẹjọ, sọ pe o yẹ ki Aarẹ Tinubu gbe igbesẹ lati ṣatungbeyẹwo awọn eto rẹ gbogbo eyi to n mu inira ba awọn araalu, ko si bẹrẹ igbesẹ to maa mu ayipada ba awujọ.
O fi kun pe ti ijọba ba nilo lati ṣamulo awọn ilana ti oun gbe kalẹ, oun maa pese rẹ fun wọn nitori ohun to jẹ oun logun ni irọrun araalu dipo fifi ọrọ awọn araalu ṣe oṣelu.
O ni ko yẹ ki ijọba tiju lati ṣamulo awọn ilana oun nitori pe oun wa ninu ẹgbẹ alatako, ti wọn si le paarọ orukọ re lai sọ pe lati ọdọ oun lo ti wa.
Bakan naa lo tun bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ijọba apapọ lati maa pese ohun amayedẹrun fun awọn eeyan dipo mimu ayipada ba awọn nnkan to n ṣokunfa inira fun wọn.
"Ẹ ye mu aye nira fun awọn araalu kẹ tun maa pin irẹsi fun wọn lati fi rẹ wọn lẹkun.
O tun sọ pe oun n gbọ finfin pe ijọba fẹ fi awọn kan ṣe iwọde ni ipinlẹ Eko lori epo bẹntiroolu pẹlu ọgbọn ati da iranwọ ori epo pada, ti wọn si maa yọ lẹyin ti ibo ba ti pari.
"Ẹ jẹ ki n ṣekilọ fawọn ọmọ Naijiria, o ṣeeṣe ki iwọde waye ni Eko laipẹ latọwọ awọn onimọto, eyi yoo mu ki Bola Tinubu da iranwọ ori epo pada fun igba diẹ.
"To ba ri iyansipo pada, o maa pada si bo ṣe wa tẹlẹ."
Ẹ ma gbiyanju lati yọ iranwọ ori ina mọnamọna bii ti ori epo bẹntiroolu
Atiku tun ṣekilọ fun ijọba lati ma tun yọ iranwọ ori ina mọnamọna eyi ti wọn n gbero lati ṣe lọdun 2027 lai gbe ilana ti ko ni fi mu inira ba araalu kalẹ.
O ni yiyọ iranwọ ori ina mọnamọna maa tunbọ sọ ọpọ idile sinu iṣe ati oṣi, to si maa ṣakoba fun awọn okoowo.
O woye pe ọpọ awọn ileeṣẹ keekeekee ni wọn ti n koju inira latari owo gegege ti wọn n san fun ina ati disu, to si ni ki ijọba lo asiko to ku ti saa wọn fi maa pari yii lati mu adinku ba iye tawọn eeyan n san fawọn ohun amuṣagbara.
O sọ pe ohun to ṣe Pataki si ohun julọ ni pe awọn ọmọ Naijiria jẹ mukundun ijọba.
Nigba to n sọrọ lori awọn igbesẹ ti yoo gbe to ba di aarẹ Naijiria, Atiku sọ pe oun maa gbe iranwọ ori epo bẹntiroolu kalẹ fun epo ti wọn ba fọ ni Naijiria nikan.
O ni eyi maa jẹ ki fifọ ep oni Naijiria pọ si, to si maa mu adinku ba iye tawọn eeyan yoo maa ra epo bẹntiroolu.
O fi kun pe oun gbagbọ pe akoko to ku fun ijọba to wa lode ṣi to lati fi ṣe atunṣe ati pe ohun ti owo to wa lọwọ awọn araalu ba to lati fi ra nnkan nikan lo le mu igbe aye rọrun fun wọn dipo owo ti ijọba n ko pamọ.


























