Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Wasilat, ọdọ́bìnrin tó wo Olóòlù, ju fídíò rẹ̀ sórí TikTok ti kú, kí ni ìtumọ̀ ètùtù tí wọn ṣe fún?

Wọn n se etutu fun Wasila, o ro asọ pupa mọ aya, o so ọpọ iakrahun igbin mọ aya, o kunlẹ, ti wọn si n fa irun ori rẹ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Kii ṣe iroyin tuntun mọ pe eto ayẹyẹ ọdun Eegun Oloolu ti waye niluu Ibadan, ipinẹ Oyo ti waye, o si ti kọja lọ.

Ṣugbọn kaka ki awọn eeyan maa sọ pataki ohun to ṣẹlẹ ati idagbasoke to waye nibi ayẹyẹ naa, ọrọ ọdọmọbinrin kan ti wọn pe ni Wasila, ẹni to lọ ṣe fọnran eegun Oloolu, to si gbe e sori ayelujara ni awọn eeyan n sọ bayii.

Ọjọbọ, ọsẹ to kọja ni ayẹyẹ naa waye, gẹgẹ bo ṣe maa n waye lọdọọdun, ti gbogbo awọn mọlẹbi ati afẹnifẹre idile naa si peju lati kopa.

Wọn n se etutu fun Wasila, o ro asọ pupa mọ aya, o so ọpọ iakrahun igbin mọ aya, o kunlẹ, ti wọn si n fa irun ori rẹ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

"Wasilat gbe fidio Oloolu sori ayelujara ti Tiktok, to si jẹ ki gbogbo aye mọ pe oun ti lọ wo eegun ti wọn sọ pe obinrin ko gbọdọ wo"

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni Wasila lo mura bi ọkunrin, to si lọ si oju ferese ibi ti eegun naa wa, lasiko ti wọn n mura fun n lọwọ lati wo o.

Kii ṣe pe Wasila lọ wo eegun Oloolu yii nikan, o tun fi ẹrọ ibanisọrọ rẹ ṣe fọnran eegun naa ninu ile to wa, ṣaaju ko to di pe o jade sita.

Awọn to ri Wasila layika ko mọ pe obinrin ni, pẹlu bo ti ṣe mura bi ọkunrin, lati fi tan awọn eeyan jẹ, ko le ba a mu erongba rẹ ṣẹ.

Wọn ni bo ṣe ya fọnran naa tan, lo kuro nibẹ, to si gba ile rẹ lọ.

Kete to ti dele, lo ti gbe foonu rẹ, to si lọ sori ikanni ayelujara ti Tiktok lati ṣafihan akasilẹ fọnran to ti ṣe, to si jẹ ki gbogbo aye mọ pe oun ti lọ wo eegun ti wọn sọ pe obinrin ko gbọdọ wo.

Wasila ni wọn lo sọ lori ayelujara pe irọ lasan ni wọn n gbe kaakiri wi pe obinrin ko gbọdọ wo eegun naa, ati pe ko sohun to jọju ninu eegun ọhun.

Bi awọn kan ṣe n gbe lẹyin Wasila nipa igbesẹ rẹ lati tako aṣa ati iṣẹṣe, bẹẹ lawọn miran n sọ pe ko yẹ ko ṣe bẹẹ nitori pe aṣa Yoruba ṣi wa nibẹ, ko si le parẹ.

Wọn n se etutu fun Wasila, o ro asọ pupa mọ aya, o so ọpọ iakrahun igbin mọ aya, o kunlẹ, ti wọn si n fa irun ori rẹ

Oríṣun àwòrán, Screen shot

Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Wasila?

Ọrọ Yoruba to sọ pe "ẹni to ba ṣe ohun ti ẹnikan ko ṣe ri, oju rẹ yoo ri ohun ti ẹnikan ko ri ri", lo ṣẹlẹ gẹlẹ pẹlu atubọtan to koju ọmọbinrin ti wọn n pe ni Wasila yii.

Ko ju bii wakati meloo lọ, ti wọn sọ pe Wasila bẹrẹ sii ri nnkan oṣu rẹ, ti ẹjẹ si n da loju ara rẹ.

Ẹjẹ naa ni wọn lo da debi wi pe ko le mu mọra mọ, eyi ti wọn lo jẹ ko tete ronu wi pe o ṣee ṣe ko jẹ eegun Oloolu toun lọ wo, lo n fiya jẹ oun, to si ṣee ṣe koun gbabẹ sọda sọrun alakeji.

Loju ẹsẹ ni wọn lo ti gbera lọ si agboole Oloolu yii, lati ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun wọn, ti wọn si lo n bẹbẹ pe ki wọn foju aanu wo oun.

Kí làwọn etutu ti Olóòlù ṣe fún Wasila tumọ si?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

BBC Yoruba gbọ pe ọrọ abuku lawọn olori ile Oloolu naa kọkọ bẹrẹ sii sọ si Wasila, nigba to jẹwọ bo ṣe tapa si aṣa ati iṣẹṣe wọn.

Wọn ni ki Wasila lọ bẹrẹ sii gbe ẹru kadara rẹ, nitori pe oun funra rẹ lo ṣokunfa bo ṣe fa gọngọ si ara rẹ lọrun.

Pẹlu ẹbẹ ni wọn sọ pe awọn agbaagba ilẹ eegun Oloolu yii fi gba lati ṣetutu fun Wasila, lati le ra ẹmi rẹ pada saye.

Ninu fọnran to n kaakiri ori ayelujara, eyi to tẹ BBC lọwọ, la ti ri bi wọn ṣe mu Wasila jade ninu ile kan pẹlu ewurẹ ti wọn gbe kọ ọ lọrun jade.

Lẹyin eyi ni wọn mu lọ sibi to jokoo si, ti iya rẹ si ti bẹrẹ sii fa irun ori rẹ kodoro, ko to di pe wọn pa ewurẹ, ti wọn si fi ẹjẹ rẹ wẹ fun un lati ori delẹ.

Yatọ si eyi, wọn tun gbe asopọ ikaraun igbin kọ ọ lọrun lasiko ti gbogbo etutu yii n lọ lọwọ, gẹgẹ bi ilana aṣa lati ra ẹmi rẹ pada.

Ọkan lara awọn ọmọ idile naa sọ fun BBC Yoruba pe, ka ni wọn ko tete ṣe etutu naa fun Wasila ni, ko si iyemeji pe yoo ta teru nipa lẹyin ọjọ keje to foju kan eegun ọhun.

Wọn ni kii ṣe pe Wasila ri eegun ọhun oju, bi ko ṣe pe aṣọ lasan lo ri, to ro pe oun ri i soju, ati pe kani o foju rii ni, ko si bo ṣe fẹẹ ṣe e, ti yoo mu ọjọ naa jẹ ko to fi aye silẹ.

Wọn n se etutu fun Wasila, o ro asọ pupa mọ aya, o so ọpọ iakrahun igbin mọ aya, o kunlẹ, ti wọn si n fa irun ori rẹ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Wasila sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ètùtù náà

Lẹyin gbogbo etutu ti awọn olori ile Oloolu ṣe fun Wasila, ni wọn bẹrẹ sii fọrọ wa a lẹnu wo, nipa idi to fi ṣe bẹẹ, ati ohun ti oju rẹ ri.

"Mo lo ṣe fọnran Oloolu ni, latigba naa ni ara mi ko ti balẹ.

Ẹjẹ n da lara mi, ẹjẹ naa ko si da lara mi,"Wasila sọ bẹẹ.

Lẹyin to jẹwọ yii, ni wọn bẹrẹ sii ṣe iwure fun un, lati ra ẹmi rẹ pada saye.

N jẹ́ Wasila kú gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe sọ?

BBC Yoruba de agboole awọn Oloolu, lati mọ bi isẹlẹ naa se waye, etutu ti wọn se at pe boya otitọ ni iroyin naa wi pe ọmọbinrin ọhun ti jade laye.

Gbara ti a debẹ, BBC Yoruba ba Oloolu nile, to si ni pe Wasila pẹlu awọn obi rẹ n bọ wa sile Oloolu naa laipẹ.

Gbogbo ohun to ṣẹlẹ, ti Wasila ba wa sọ, la o mu wa fun un yin laipẹ, ẹ ku oju lọna...