PFIPC: Kìí ṣe Adeyemi nìkan ló ṣe ohun tí wọ́n fẹ̀sùn rẹ̀ kàn án, ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ìjọba ló lọ́wọ́ si - Agbẹjọ́rò

Oríṣun àwòrán, Adeniyi Adeyemi
Ọga agba ajọ ti ijọba pe ni ayederu, Presidential Foreign Investment Promotion Council, Adeniyi Adeyemi, ti sọ pe kii ṣe oun nikan lo da pa arọ gidigba naa, amọ ọpọ awọn ileeṣẹ ijọba apapọ mii lo lọwọ si.
Adeyemi to ti wa lakata awọn ọlọpaa lo sọ ọrọ naa lati ẹnu agbẹjọro rẹ, Festus Akhigbe.
Afurasi naa tun sọ pe oun ti ṣetan, oun si nifẹ si ati yọju niwaju igbimọ ile aṣofin agba to n ṣewadii ọrọ naa.
Ikọ agbẹjọro afurasi ọhun sọ pe ti afurasi naa ko ba lanfani lati yọju siwaju igbimọ naa ti Yusuf Gagdi lewaju lati sọ tẹnu rẹ ki igbimọ ọhun to gbe abajade iwadii rẹ jade, yoo jẹ titẹ afurasi naa loju mọlẹ.
Abbẹjọro Adeyemi ni oun kọ igbiyanju ijọba lati mu ki araalu maa ro pe onibara oun nikan lo da ẹsun ti wọn fi kan an ṣe lai ni baba isalẹ kankan ninu ijọba.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, ọọfisi akọwe agba ijọba apapọ buwọlu awọn iwe kan to rọ mọ ajọ naa ti wọn pe ni ayederu ki wọn to fun ajọ ọhun ni ọọfisi to n lo.
O sọ ninu atẹjade kan pe "Awa, gẹgẹ bii ikọ agbẹjọro Adeniyi Adeyemi, n sọrọ yii ni gbangba lati jẹ ki araalu mọ bo ṣe n lọ, atimọlẹ onibara wa, ati iwadii ti awọn aṣofin n ṣe.
"Ọọfisi olori oṣiṣẹ Naijiria buwọlu ajọ naa, bẹẹ lo fontẹ lu u, eyii to fi gba oṣiṣẹ 314 siṣẹ."
Awọn agbẹjọro ọhun tun ni ọpọ awọn olori agbofinro lo yọju sibi ipade ti ajọ naa pe, koda ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu, EFCC fun ni dukia, wọn gba owo lọwọ rẹ, wọn si tun fun ni ami idanimọ pẹlu.
"Ko yẹ Adeyemi nikan fi ori ru ẹṣẹ ọpọ eeyan ninu ijọba"
Atẹjade naa sọ siwaju si pe awọn eeyan ati ẹka ileeṣẹ ijọba to ṣe pataki ni wọn dunadura pẹlu rẹ.
Lara wọn ni akọwe ijọba apapọ, oluṣiro agba Naijiria, banki apapọ Naijiria, olori oṣiṣẹ Naijiria, ọọfisi eto iṣuna, ajọ EFCC, ile igbimọ aṣofin agba, to fi mọ gbogbo awọn olori ẹka agbofinro Naijiria ni wọn ba a ṣiṣẹ ti wọn si dunadura pẹlu rẹ.
Awọn agbẹjọro naa wa bere pe ti gbogbo awọn eeyan wọnyii ba ba a ṣiṣẹ "Bawo ni Ọmọọba Adeniyi Adeyemi nikan ṣoṣo yoo ṣe jiya ohun ti gbogbo ẹka ijọba kuna lati ṣawari rẹ?
"Yoo ṣoro fun ẹnikan ṣoṣo lai si iranlọwọ lati tan gbogbo ẹka ijọba jẹ."
Atẹjade ọhun sọ pe niṣe lo dabii pe wọn fẹ jẹ ki Adeyemi nikan ru agbelebu aṣiṣe oniruru ẹka ijọba, eyii ti ko yẹ ko ri bẹẹ.
Lẹyin naa ni wọn ke si awọn ti ọrọ kan lati ṣewadii gbogbo awọn eeyan ati ẹka ijọba ti wọn ṣiṣẹ papọ pẹlu afurasi ọhun ki oun nikan ma baa fi ori ru ẹṣẹ ọpọ eeyan.




























