Àwọn jàndùkú kọlu ìyàwó Bola Oyebamiji lẹ́yìn ìpolongo ìbò nílùú Ede, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Oríṣun àwòrán, x/@OyebamijiBola
Awọn afurasi janduku kan ti kọlu ọkọ Sekinat Oyebamiji, to jẹ iyawo oludije sipo gomina ipinlẹ Osun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Munirudeen Bola Oyebamiji, ti ọpọ mọ si AMBO.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ko pẹ lẹyin ti obinrin naa ṣe ipolongo ibo fun ọkọ rẹ ni Alajue Ward 2 to waniluu Ede, ni imurailẹ fun eto idibo gomina ti yoo waye lọsẹ to n bọ ti wọn kọlu u.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Nigba ti BBC Yoruba kan si agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Osun, DSP Abiodun Ojelabi, o ni lootọ ni iṣẹlẹ naa waye, amọ awọn tig be igbesẹ lori rẹ.
Bawo ni ikọliu naa ṣe waye?
Gẹgẹ bi awọn ileeṣẹ iroyin abẹle ṣe jabọ, obinrin naa ati Bukola Adereti, to jẹ iyawo oludije fun ipo igbakeji gomina ni wọn jọ kọwọ rin.
A gbọ pe nnkan biii aago meje aṣalẹ lasiko ti wọn n kuro nibi ipolongo naa lawọn janduku bii marundinlogun kọlu ọkọ wọn atawọn ọkọ mii ti wọn jọ n kọwọ rin.
A tilẹ gbọ pe alaga ajọ NURTW, ti ẹka Sekona farapa lasiko ikọlu ọhun amọ ori ko aya Oyebamiji ati Adereti yọ.
Yatọ si ọlọpaa to fidi ikọlu naa mulẹ, alaga ijọba ibile Ede South, Kolawole Salami naa tun fidi rẹ mulẹ.
Salami bu ẹnu atẹ lu ikọlu ọhun, bẹẹ lo ke si awọn agbofinro ki wọn bẹrẹ iwadii lori ohun to ṣẹlẹ ki wọn si fi imu gbogbo awọn to lọwọ ikọlu naa danrin.
Gẹgẹ bi Salami ṣe sọ, awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu Accord ni awọn janduku naa.
O si ke si ileeṣẹ ọlọpaa ki wọn ṣe iwadii to tọ lori iṣẹlẹ ọhun ki wọn ma si ṣe e ni oku oru.
Wayi o, gbogbo igbiyanju wa lati kan si Oyebamiji funra rẹ lori iṣẹlẹ naa loja si pabo.
Titi di asiko ti a n ko iroyin yii jọ, ẹgbẹ oṣelu Accord ko tii sọ nnkan lori rẹ.



























