Mo fẹ́ràn obìnrin lóòótọ́ àmọ́.... – Ayo Olaiya

Àkọlé fídíò, Ayo Olaiya
Mo fẹ́ràn obìnrin lóòótọ́ àmọ́.... – Ayo Olaiya
Published

Gbajumọ oṣere tiata nni, Oluwabusayomi Timothy ti ọpọ mọ si Ayo Olaiya ti sọrọ lori idi to fi n jẹ orukọ naa ati idagbasoke rẹ ninu ere tiata.

Olaiya sọ fun BBC News Yoruba pe nitori pe iya oun ṣe wahala nigba ti wọn n tọ oun, ti iku ko si jẹ ki iya naa gbadun obi to gbo ko to mu u sọdọ ni oun fi sọ ara oun ni Olaiya.

O sọ pe ọpọ iṣẹ ni oun ṣe ki oun to di ilumọọka nidii iṣẹ tiata ti oun yan laayo.

Ayo Olaiya joko lori aga, o de igo, wọ ilẹkẹ sọwọ ati ọrun, o rẹrin-in si ẹrọ ayaworan

O ni oun ṣiṣẹ awọn to maa n sọ ẹnu ọna lati le ko owo jọ fi ṣe fiimu ki ori to gbe oun jana nidii iṣẹ tiata, ti idi oun si gbona ki oun to maa jẹ ata gẹgẹ bi owe Yoruba.

Nigba to n sọrọ nipa ẹsun tawọn kan maa n fi kan an pe o fẹran obinrin, Olaiya sọ pe bẹeni nitori oun fẹran iya oun daadaa ati ololufẹ oun naa.

O fi kun pe ipa ti oun n ko ninu ere ko tumọ si pe iru iwa bẹẹ ni oun maa n hu loju aye.

Olaiya ni gbogbo nnkan ti oun maa n ṣe ninu ere, pe inu ere lo mọ.