Ijọ Ajẹrii Jehofa ṣe atunṣe si ofin gbigba Ẹ̀jẹ̀

Owo ẹni kan to n gab ẹjẹ nile iwosan

Oríṣun àwòrán, @others

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn Adari ijọ Ajẹrii Jehofa (Jehova Witnesses) ti kede pe to ba wu awọn ọmọ ijọ wọn, o le gba ẹjẹ tabi ko fun ẹlomii ni ẹjẹ ni kete ti ẹri ọkan wọn ba ti da wọn lare lati ṣe bẹẹ.

Ijọ Ajẹri sọ eyi di mimọ ninu atẹjade lati Olu ijọ wọn to wa ni Warwick ni New York ni America loju opo ikanni agbaye wọn.

Wọn ṣalaye pe, "Ofin ijọ ko de ki eeyan fun ẹlomii ni ẹjẹ tabi ki eeyan gba ẹjẹ lọwọ ẹlomii pẹlu akoonu inu ẹjẹ bii eyi ti Oloyinbo n pe ni White cells, Red cells, Plasma ati Platelets; duba pe ki ẹri ọkan iru ẹni bẹẹ ṣa ti faramọ igbesẹ naa ni" .

Ṣugbọn awọn Adari ijọ naa fidiẹ mulẹ pe ofin ọjọ pipẹ wọn lori ki eeyan má gba ẹjẹ ko yipada rara, wọn kan fi aaye silẹ fun ọmọ ijọ ti ẹri ọkan rẹ ba faaye gba igbesẹ naa lati ṣe bẹe ni funra rẹ.

Agbẹnusọ ijọ Elẹrii Jehofa lagbaye, Paul Gillies sọ pe ẹjẹ ni ẹmi nkan gẹgẹ bi iwe Iṣe awọn Aposteli ori 15, ẹsẹ 20 ṣe fidiẹ mulẹ ninu Bibeli ti o fihan pe ẹjẹ ṣe iyebiye si Ajẹrii Jehofa gẹgẹ bii ẹbun pataki lati ọdọ Olorun.

O ṣalaye pe ijọ naa mọ pataki iṣẹ iwadii ati iṣẹ iwosan ni eyi to mu ọrọ ẹjẹ fifunni ati gbigba di ipinnu laarin Ajẹrii kọọkan ati Elẹdaa rẹ Jehofa.

Ikede tuntun yii jẹ afikun ikede ti ijọ naa kọkọ ṣe laipẹ yii pe o ṣeeṣe fun Ajẹri to ba wu lati fi ẹjẹ ara rẹ pamọ ko si tun lọ gba a lasiko to ba nilo rẹ ninu iṣẹ iṣegun.