Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi tẹ́lẹ̀ Ibrahim Idris jáde láyé lẹ́ni ọdún 77, Ododo, Bello, Natasha ń ṣèdárò

Oríṣun àwòrán, Ibrahim Idris
Gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ ri, Alhaji Ibrahim Idris, ti jade laye.
Ogunjọ oṣu Kẹsan an ọdun yii ni iroyin fidi rẹ mulẹ pe Alhaji Idris jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgọrin lorilẹede UK.
Ẹwẹ, Gomina ipinlẹ Kogi, Ahmed Usman Ododo, Yahaya Bello to jẹ gomina ipinlẹ naa tẹlẹ atawọn alẹnulọrọ mii lagbo oṣelu ti ṣabẹwo sile oloogbe l'Abuja lati kẹdun pẹlu ẹbi rẹ.
Oludamọran gomina Ododo lori ibaṣepọ pẹlu araalu, Onogwu Muhammed to jẹ akọwe iroyin tẹlẹ fun Gomina tẹlẹ ri, Yahaya Bello lo sọ loju opo Facebook rẹ nipa abẹwo awọn eeyan naa sile oloogbe l'Abuja.
Muhammed sọ loju opo ayelujara rẹ pe ''Gomina Usman Ododo, Gomina tẹlẹ ri Yahaya Bello, CON, kọmiṣọna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, Abdullahi Bello atawọn abẹnugan lagbo oṣelu mii ti de sile oloogbe Gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ ri, Ibrahim Idris to jade laye lọsan ọjọ oni ọjọ Aiku.''
Idris jẹ gomina ipinlẹ Kogi laarin ọdun 2003 si ọdun 2012, Idris Wada lo gori aleefa gẹgẹ bii gomina lẹyin rẹ.
A ko le sọ pato nnkan to ṣokunfa iku rẹ ni asiko yii.
Sẹnẹtọ to n ṣoju aaringbungbun Kogi, Natasha Akpoti-Uduaghan, naa ti n ṣedaro gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ to doloogbe.
Natasha ni eekan ninu itan ipinlẹ Kogi ati ni ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ni Idris i ṣe.


























