Obìnrin tó bá rí Olóòlù, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò gbẹ lorí ìdúró ni, èyí tó bá ya fídíò rẹ̀ bíi Wasilat láì ṣe ìràpadà, yóò kú tàbí ya wèrè láàárín ọjọ́ keje - Ìdílé Olóòlù

Àkọlé fídíò, Obìnrin tó bá rí Olóòlù, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yóò gbẹ lorí ìdúró ni, èyí tó bá ya fídíò rẹ̀ bíi Wasilat láì ṣe ìràpadà, yóò kú tàbí ya wèrè
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 8

Akọwe Ile Aje Oloolu, Oloye Gbolahan Ishola ti sọ pe kii ṣe nnkan kekere ni keeyan foju kan Eegun Oloolu, ati pe ẹni to ba foju kan agba Eegun naa yoo kabamọ.

Oloye Ishola lo sọrọ yii lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ lẹyin iṣẹlẹ to waye lọsẹ to kọja, ninu eyi ti wọn fẹsun kan obinrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Wasilat, pe o ṣe fọnran Eegun Oloolu, to si gbe e sori ayelujara.

Ishola sọ pe ka ni wọn ko ṣe gbogbo etutu irapada ti wọn ṣe fun Wasilat lọjọ naa ni, Ọjọru, ọsẹ yii ni obinrin naa ko ba ti jade laye.

Ishola ni ko sẹni to ṣe iru nnkan bẹẹ, to kọja ọjọ meje loke eepẹ.

Oloye Gbolahan Ishola wọ asọ toketilẹ alawọ buluu ati fila rẹ

"Igba ti Eegun yoo fi iya jẹ Wasilat, ti Eegun fẹẹ tu aṣiri rẹ, ti Eegun fẹ fi ṣe ẹsin, lo ni ko ju fidio Oloolu sori Tiktok, oun naa fẹ gbajumọ ni"

Akọwe Ile Aje Oloolu, to gba ẹnu gbogbo mọlẹbi naa sọrọ, ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa ohun to ṣẹlẹ fun BBC Yoruba, to si ni ko si nnkan ti yoo ṣe Wasilat mọ lẹyin irapada ti wọn ti ṣe fun un.

"Ọjọbọ ni ipari jijade Oloolu maa n bọ si, gbogbo ọna ti wọn maa n rin lati Agugu, to fi de inu Paara inu Ewe, gbogbo ọna yẹn, to fi de ọna Amuloko ni wọn maa n lọ ni ọjọ Alamisi yẹn," Ishola sọ bẹẹ.

O tẹsiwaju pe "Ti ọjọ Alamisi ni ọmọ yẹn ṣe fidio yẹn, nigba ti Oloolu wa ni Oremeji si Babanla, lo ṣe fọnran yẹn jade.

Awa ko mọ, nitori niṣe lo dabi ẹni pe ori ile alaja meji lo ti lọ ṣe e, o si mura bi ọkunrin.

"Igba ti Eegun yoo fi iya jẹ ẹ, ti Eegun fẹẹ tu aṣiri rẹ, ti Eegun fẹẹ fi ṣe ẹsin, lo ni ko juu sori fọnran ayelujara ti wọn n pe ni Tiktok, oun naa fẹẹ gbajumọ.

"O fẹ ki aye mọ pe 'ṣebi Oloolu ti wọn sọ pe wọn kii ri ree', lo ba gbe e sibẹ."

Bi ẹ ko ba gbagbe, Ọjọbọ, ọsẹ to kọja ni aṣekagba eto ayẹyẹ ọlọdọọdun ti Eegun Oloolu waye, nibi ti gbogbo awọn ọmọ idile naa ati awọn afẹnifẹre ti peju.

Nibẹ ni wọn sọ pe Wasilat ti mura bi ọkunrin, to si lọ ṣe fọnran Eegun naa, eyi ti wọn lo ti tapa si iṣẹṣe, ko to di pe ọrọ yiwọ.

Kii ṣe pe ọrọ tun deedee yiwọ nikan, bi ko ṣe pe bọmọbinrin naa ṣe tun lọ gbe fọnran ọhun sori ayelujara lo jẹ ko dẹni ti gbogbo aye n sọrọ rẹ lonii.

Bo tilẹ jẹ pe oniruru awuyewuye lo ti waye lori iṣẹlẹ, ti awọn eeyan si n gbe ohun ti wọn ko ri sori ayelujara, eyi lo jẹ ki BBC lọ si agboole naa, lati ba awọn agbaagba ile Oloolu sọrọ.

Akowe ile Aje Oloolu lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, ati Wasilat lasiko ti wọn n fa ori rẹ
Àkọlé àwòrán, Gbolahan Ishola/Wasilat Olaleye

"Wasilat ni Oloolu ti ṣe idajọ kekere fun oun, o ti ni ko maa ṣe ẹjẹ ni abẹ, o ti mu ẹfọri lu u, o ti fi ailera kun un"

Akọwe naa jẹ ko di mimọ pe kii ṣe awọn lawọn ri Wasilat nibi to ti n ṣe fọnran, ti awọn fi mu, o ni awọn aye lo mu u nipa oniruuru aisan ti wọn fi kan an.

"Awọn aye ba ri i, aye lọ gbe e.

Gbigbe ti aye gbe e, ti iru nnkan bẹẹ ba si ṣẹlẹ lẹyin Oloolu.

Ọmọ ti iru rẹ ba ṣẹlẹ si lẹyin Oloolu, ti Ọlọrun ba ni yoo jẹ eeyan lọjọ naa ni o, koda bo jẹ Ọkunrin, yoo jẹ sanda," Oloye Ishola sọ fun BBC Yoruba.

"A ko fẹ ki wọn fọwọ kan an, kii kuku ṣe awa la mu un, Eegun lo mu funra ẹ, to tu aṣiri rẹ sita.

Awa lọ gbe e sọdọ awọn agbofinro ni, nibi to sun ọdọ mọju.

"Wasilat ni Oloolu ti ṣe idajọ kekere foun, o ti ni ko maa ṣe ẹjẹ ni abẹ, o ti mu ẹfọri lu u, o ti fi ailera kun un.

"Bi ẹ ba woju ọmọ yẹn, ẹ ti mọ pe nnkan n ṣe e, oun naa ti fẹnu ara rẹ sọ pe bai-bai ni nnkan ti n ṣe oun."

Wasilat ro asọ pupa mọ aya, wọn gbe ikarahun igbin si aya rẹ, wọn si n fa irun ori rẹ, oun naa dori kodo

Oríṣun àwòrán, Screenshot

"A ko deedee gbe ẹran kọ Wasilat lọrun, ohun ti eegun Oloolu beere nidi ogun la lati fi ra ẹmi rẹ pada lọwọ iku ojiji la se, funra rẹ lo fori ja ile agbọn"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ishola sọ pe kii ṣe pe awọn deedee gbe ẹran kọ ọ lọrun, bẹẹ ni lawọn ko deedee fa irun ori rẹ, o ni Ogun ti wọn lọ bọ fun un lo sọ gbogbo ohun ti wọn gbọdọ ṣe.

O ni gbogbo ohun ti eegun Oloolu beere pata nidi ogun ni awọn ṣe fun un, lati fi ra ẹmi rẹ pada kuro lọwọ iku ojiji, nitori pe funra rẹ lo fori ja ile agbọn.

"Wọn lọ sidi Eegun lọ da obi ni, wọn ko deedee pa ẹran fun un; wọn lọ idi Eegun lọ sọ obi ni, wọn ko deedee gbe nnkan ti wọn gbe sii lọrun sibẹ; wọn ko si deedee fa ori ẹ.

"Nnkan ti Eegun ni ki wọn ṣe, ni wọn ṣe fun un. Ti Eegun ba gba maluu lọwọ ẹ, bi yoo ṣe gbe maluu kọrun niyẹn, ṣe o ti ye e yin.

"Ṣugbọn nnkan ti Eegun lohun yoo gba ni Agbo ẹran ti ẹyin ẹ gba igba, ki wọn o si fa ori ẹ, nitori Oloolu naa kii nirun lori.

''Ṣebi o fẹẹ ri oloolu ni, ki wọn fa ori toun naa. Iya ẹ gangan ni Eegun ni ko ba a fa irun ori rẹ, ko si maa ko irun rẹ lọ, atawọn nnkan mi-in.

"Ṣe ẹ ri awọn nnkan ti wọn so kọ ọ lọrun bii kele yẹn, ẹẹ rii pe nigba to bẹrẹ sii jo yipo Ogun, bẹẹ naa lo n dun gboo-gboo. Iyẹn duro bi aja ti wọn fi ba a re iku danu.'

O sọ ọ di mimọ pe iku to yẹ ki Wasilat ku, ni ẹran agbo naa gba ku, idi ree to fi ni ori rẹ ni wọn ti pa ẹran ọhun lati fi ẹjẹ rẹ wẹ ẹ.

"Iku toun ko ba ku, ẹran yẹn lo gba iku ẹ ku, idi niyẹn ti wọn fi du ẹjẹ ẹran yẹn lee lori."

Wasilat ro asọ pupa mọ aya, wọn gbe ikarahun igbin si aya rẹ, wọn si n fa irun ori rẹ

Oríṣun àwòrán, Screenshot

"Ẹjẹ obinrin to ba fi oju kan Oloolu yoo gbẹ lori iduro ni, ibẹ ni yoo si ku si"

Nigba to n ṣalaye nipa atubọtan ohun ti yoo ṣẹlẹ si obinrin to ba foju kan Eegun Oloolu, Ishola sọ pe ẹjẹ onitọhun yoo gbẹ lori iduro ni.

O ni oniruuru ọna si ni Eegun naa n gba fiya jẹ ẹni to ba foju kan an, ati pe eyi to wu u, lo ṣe fun Wasilat lọjọ naa.

"Ọna meji leeyan maa n gba ri Oloolu, tabi ju bẹẹ lọ. Ẹni ba ri Oloolu lojukoju, ibẹ naa ni yoo ku si. Ẹjẹ rẹ yoo gbẹ kiakia ni," o sọ bẹẹ.

"Igba yẹn lẹẹ ri ti onitọhun yoo maa sọ pe ki Oloolu ṣe bi ṣe n ṣe – ki ba a jẹ ọmọ bibi inu ẹ, o ti b'ọdun lọ niyẹn.

"Teeyan ba wa ya fọto bi iru eyi ti ọmọ yẹn ṣe, ti ko ba wa fun irapada bo ṣe wa yẹn, Ọjọru ọsẹ yii ni yoo ṣilẹ wọ - yoo ku lo n jẹ bẹẹ, tabi ko ma ṣe gan-an-gan-an-gan, ko ya were.

"Idajọ to ba wu Oloolu fun un, ko gbọdọ kọja ọjọ meje. Ọmọ yẹn, irapada ni wọn ṣe fun un, irapada lasan ni.

Ko si nnkan to kan an pẹlu ori fifa, ko si nnkan to kan an ko maa fi ẹsẹ rin, ti irun e ba ti kun, bisimilai.

"Ṣugbọn nnkan ti wọn sọ fun un ni pe ma tii ma gbe nnkan sori, ko jẹ ki atẹgun fẹ si oun lori, kii Oloolu wa bẹ ẹ wo.

"Awọn ti wọn ko nifẹẹ ọmọ yẹn, awọn ti wọn jẹ gẹgẹ bi ọta Oloolu, wọn sọ pe ọmọ ti ku, ṣugbọn ọmọ bẹ laye o."

O wa rọ gbogbo obi ati alagbatọ lati tọwọ awọn ọmọ wọn bọ aṣọ lasiko ti ba tun n ṣe ayẹyẹ ọdun Egungun Oloolu naa, ati pe ki wọn fi ọrọ Wasilat ṣe arikọgbọn.

"Wọn ti ri ohun to ṣẹlẹ si ọmọ yẹn, to ba di ọdun to n bọ, kaluku yoo tori ọmọ rẹ bọṣọ.

Ọlọrun yoo jẹ ki wọn le gbọ, ti wọn ko ba gbọ, ki wọn fi tọmọ yẹn ṣe arikọgbọn, ọlọrun yoo jẹ ki awọn naa bọ sọwọ Oloolu."