Wo bí owó orí sísan lórí èrè nídìí ìdókòwò "crypto" àti irúfẹ́ okòwò bẹ́ẹ̀ ṣe kàn ọ́

Ọwọ ẹnikan da owo ẹyọ soke

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ NRS to n ri si pipa owo wọle fun ijọba ti kede alakalẹ lori sisan owo ori lori fifi owo ilẹ okeere ''crypo'' dokowo ati lori awọn idokowo mii to n lọ lori itakun ayelujara.

Ajọ NRS ṣalaye ninu atẹjade kan ti o fi sita wi pe ijọba yoo maa gba owo ori lori fifi owo ''crypo'', ''stablecoins,'' NFT atawọn idokowo mii to n lọ lori ayelujara ni Naijiria.

NRS ti ṣe agbekalẹ ilana ati ofin lori awọn to maa san owo ori yii, iru idokowo tawọn eeyan yoo maa san owo ori le lori ati ọna ti wọn yoo gba lati sọ fun ijọba lori owo ori ti wọn ba n san.

Wọnyii lawọn nnkan to yẹ ki o mọ nipa sisan owo ori lori idokowo ''crypo'' atawọn irufẹ idokowo bẹẹ mii:

Awọn wo lọrọ owo ori yii kan?

Gbogbo eeyan to ba n fi owo ''crypo'' ṣe idokowo ni ọrọ owo ori sisan yii kan.

Eleyii ni ṣe pẹlu gbogbo eeyan ati ileeṣẹ to ba n fi owo crypo atawọn owo ilẹ okeere dokowo, ti wọn si n jẹ ere pẹlu owo crypto bakan naa.

Awọn to n ṣiṣẹ fun ileeṣẹ to n fi owo crypto ṣe idokowo naa yoo maa san owo ori yii.

Gbogbo eeyan to n fi owo crypto ati irufẹ owo bayii ṣe idokowo, awọn to n lo ''wallet, atawọn to n wa kusa ni ọrọ yii kan.

Awọn mii lawọn ti wọn ba n fi crypo sanwo iṣẹ wọn fun ati awọn oṣiṣẹ to ba n fi crypto gba owo oṣu wọn

Irufẹ idokowo tawọn olokowo yoo maa sanwo owo ori le lori?

Ọna mẹfa ni idokowo tawọn olokowo yoo maa sanwo ori le lori pin si.

Idokowo pẹlu crypo ni akọkọ, lẹyin naa lo kan siṣe pasipaarọ ''tokens.''

Awọn idokowo mii ni ''stablecoins'', idokowo ''tokens'', ''utility and government tokens,'' ''NFTs'' ati idokowo owo ti CBN n ṣe..

Apẹẹrẹ owo ti wọn n lo fun idokowo Cryptocurrencies and exchange tokens'' ni Bitcoin, Ether, Solana ati BNB.

USDT, USDC, BUSD, DAI ati PayPal USD jẹ apẹẹrẹ idokowo ''Stablecoins.

Awọn okowo wo ni awọn olokowo ko ni sanwo ori le lori?

Ajọ NRS ti ṣalaye wi pe okowo eNaira ati idokowo CBDCs to jẹ ti banki CBN ko si lara iru awọn okowo ti ijọba yoo maa gbowo ori le lori.

NRS ni ko ni si afikun owo ori sisan lori iru awọn okowo yii ju eyi ti gbogbo eeyan maa n san lọ.

Ijiya fawọn to ba kọ lati tẹle alakalẹ NRS lori owo ori tuntun

Ajọ NRS ti kede ijiya to wa fun awọn eeyan ati ileeṣẹ to ba kuna lati sanwo ori tuntun lori idokowo crypto atawọn irufẹ okowo bẹẹ mii.

.Ẹnikẹni to ba kuna lati forukọ idokowo rẹ silẹ pẹlu ajọ NRS yoo san faini ₦50,000 fun oṣu akọkọ, yoo si tun maa san ₦25,000 loṣooṣu lẹyin oṣu akọkọ.

Ẹnikẹni to ba kọ lati kede iye owo ori to san fun ijọba yoo san faini ₦100,000 fun oṣu akọkọ, yoo si maa an ₦50,000 loṣooṣu lẹyin igba naa titi ti yoo fi kede iye owo ori ti o san.

₦50,000 ni faini ti o maa san ti o ba kuna lati ṣe akọsilẹ eto inawo ileeṣẹ rẹ.

Ẹnikẹni to ba kọ lati ṣe nnkan ti ajọ NRS sọ lori okowo VASP tabi P2P yoo san faini ₦10 million fun oṣu akọkọ, yoo si maa san ₦1m loṣooṣu lẹyin naa.

Bi o ṣe le forukọ silẹ fun sisan owo ori okowo crypto

Ẹnikẹni to n ba n ṣe okowo crypto atawọn irufẹ owo bẹẹ gbọdọ gba nọmba owo ori sisan.

Awọn to n ṣagbatẹru okowo owo ilẹ okeere lori ayelujara nilo nọmba idanimọ fun owo ori sisan lati forukọ wọn silẹ