Ọmọ Nàìjíríà tí kò bá dìbò kò ṣe Nàìjíríà lóore- INEC

Àkọlé fídíò, Aṣoju ajọ INEC, Eniola Oladapo
Ọmọ Nàìjíríà tí kò bá dìbò kò ṣe Nàìjíríà lóore- INEC
Published

Bi eto idibo apapọ ilẹ Naijria ti yoo waye nibẹrẹ ọdun 2027 ṣe n sunmọle, ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, ti sọ pe ọmọ orilẹede yii ti ko ba dibo ko ṣe Naijiria loore.

Ninu alaye aṣoju ajọ naa; Eniola Oladapo to ṣe fun BBC News Yoruba lo ti ni ọmọ Naijiria gbọdọ jade dibo nitori ko si ilana iyansipo miran to ju ibo didi lọ.

O ni ijọba awaarawa to yatọ si ti ologun la n ṣe lọwọ ni Naijiria, araalu kọọkan naa si ni akojọpọ rẹ.

Bi araalu ko ba wa jade dibo naa nitori ẹni ti wọn dibo fun nigba kan ko wọle, iyẹn ko sọ pe ki wọn ma tun jade dibo to n bọ lọna gẹgẹ bi INEC ṣe sọ.

O ni ọmọ Naijiria lẹtọọ lati dibo, wọn si ni ipa lati ko ki Naijiria le tẹsiwaju, ki araalu naa si le ni ilọsiwaju pẹlu.

"Bi eeyan jade dibo tabi ko dibo, iyẹn ko ni ki eeyan ma sanwo ori tijọba ba la kalẹ, fun idi eyi, ohun to yẹ fun ọmọ Naijiria naa ni lati jade dibo fun ẹni ti wọn ba fẹ, ki ofin ti yoo tu wọn lara le wa si imuṣẹ."