Oriyomi Hamzat kò kópa nínú ìdìbò abẹ́nú Accord, ẹ yọ ọ́ kúrò bíi olùdíje gómìnà - Busari Gudugúdù wọ́ ẹgbẹ́ òṣèlu Accord àti INEC lọ sílé-ẹjọ́

Olakunle Busari lo n wo ọọkan yii pẹlu fila alawọ pupa lori; nigba ti Oriyomi Hmazat n rẹrin pẹlu aṣọ rẹfunrẹfun, to si na ọwọ rẹ sọọkan.

Oríṣun àwòrán, Olakunle Busari-Others/Oriyomi Hamzat/Facebook

Àkọlé àwòrán, Olakunle Busari ati Oriyomi Hamzat
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọkan lara awọn oludije sipo gomina ipinlẹ Oyo lọdun 2027 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord, Olakunle Busari, ti ọpọ eeyan mọ si Gudugúdù, lo ti wọ ẹgbẹ oṣelu naa ati ajọ eleto idibo ilẹ Naijiria, INEC lọ siwaju ile-ẹjọ giga apapọ to wa niluu Ibadan.

Busari sọ pe, oun fẹ ki ile-ẹjọ da ajọ INEC ati ẹgbẹ oṣelu Accord nipinlẹ naa lọwọ kọ, nipa bi wọn ṣe fa Oriyomi Hamzat kalẹ gẹgẹ bi ẹni ti yoo dije du ipo labẹ asia ẹgbẹ naa.

Ẹsun ti Busari gbe lọ siwaju ile-ẹjọ naa, eyi ti nọmba rẹ jẹ 'FHC/IB/CS/97/26', ni agbẹjọro rẹ, Tunji Ogunrinde ti n sọ pe, ki wọn tete yọ orukọ Oriyomi Hamzat kuro gẹgẹ bi ọmọ oye ti yoo dije fun ipo gomina lọdun 2027.

Busari, ninu ẹsun naa tun sọ pe, Hamzat ko kopa ninu eto idibo abẹnu ẹgbẹ oselu naa to waye ninu oṣu Karun-un, ọdun 2026, to si ni oun ko le gba ki wọn yan oun jẹ.

Gudugudu sọ pe oun fi ẹyin Hamzat ati gbogbo awọn oludije miran to kopa ninu idibo abẹnu naa gbolẹ nibi eto idibo abẹle naa, bo tilẹ jẹ pe sọrọsọrọ naa ko kopa nibẹ.

Busari tẹsiwaju pe, iyalẹnu nla lo jẹ foun pe ajọ INEC yọ orukọ oun kuro loju opo ayelujara wọn gẹgẹ bi oludije, ti wọn si fi ti Oriyomi Hamzat rọpo rẹ, gẹgẹ bi oludije tẹgbẹ dibo yan.

O ni oun ni ojulowo ọmọ oye tẹgbẹ naa fa kalẹ nibi eto idibo abẹle to waye lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2026.

Bakan naa lo tun rọ ile-ẹjọ lati paṣẹ fun Hamzat ko ye e pe ara rẹ ni ojulowo oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ naa.

Amọ ẹgbẹ oselu Accord tabi Oriyomi Hamzat ko tii fesi lori igbesẹ naa.