Àdó olóró Israel ti ṣekúpa èèyàn 1001 ní Lebanon
Ado oloro lati orilẹede Israel ti kọlu afara meji to wa ni odo Litani to so guusu Lebanon mọ awọn agbegbe yooku lorilẹede naa, ileeṣẹ ologun sọ.
Eyi waye lẹyin ti ikọ ologun Israel sọ pe awọn yoo kọlu awọn agbegbe ti ikọ Hezbollah n lo lati ṣe irinna fun awọn ologun rẹ ati gbigbe ohun ija.
Ikọlu ado oloro naa tun ọpọ agbegbe ni Beirut, to si ṣekupa eeyan mejila, ti mẹtadinlọgbọn si farapa yanayana, awọn alaṣẹ Lebanon sọ.
Ẹka ilera Lebanon ni eeyan 1,001, to fi mọ ọmọde 111, ti wọn ti padanu ẹmi wọn lati ọjọ keji oṣu kẹta.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Lebanon ni wọn fa wọ inu ogun US-Israel tako Iran nigba ikọ agbebọn to n ṣe atilẹyin fun Iran, Hezbollah ju ado oloro si Israel. Israel fesi pada pẹlu ado oloro, to si kọlu awọn ooogun ni agbegbe guusu Lebanon.
Minisita fun eto aabo ni Israel, Israel Katz ni awọn afara ti awọn ja lulẹ yii ni awọn kọlu lati dena ikọ Hezbollah ṣugbọn ikọ ko ti fesi pada.
Ṣaaju ni Ọjọru, ikọ ologun Israel ṣekilọ fun awọn araalu to wa ni ẹgbẹ Litani naa pe ki wọn yago.
Ọkunrin kan, ẹni mẹdọgbọn ni oun iyalẹnu naa ni ikọlu naa jẹ, to si ba ọpọ dukia jẹ.
"Ko si ẹnikẹni nibi to n ṣe oṣelu tabi jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu kankan," o sọ. "Araalu ni wa, ko ko ba ẹnikẹni ṣe."



























