Ẹgbẹ́ ọmọ ogun Houthi ní òun ti fi àdó olóró ránṣẹ́ sí olú ìlú Saudi Arabia

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ẹgbẹ ọmọ ogun Houthi ti Iran n ṣatilẹyin fun ni Yemen ti kede pe awọn ti ju ado oloro siluu Riyadh to jẹ olu ilu Saudi Arabia atawọn dukia ijọba ilẹ naa kan lagbegbe eti Okun Pupa.
Ijọba Saudi sọ pe oun koju ado oloro kan loju ofurufu, eyii ti wọn kọkọ fi ṣọwọ si Riyadh amọ ko sọ nipa awọn ikọlu mii tabi awọn ti iṣẹlẹ naa kan.
Ṣaaju ni eefin dudu ti kọkọ gbalẹ lẹba awọn agba epo kan ti ko jina si papakọ ofurufu Riyadh lọjọ Abamẹta.
Eyii mu ki awọn eeyan kan gbagbọ pe lootọ ni iroyin ikọlu Houthi si Saudi Arabia waye.
Bakan naa ni fere pajawiri dun niluu naa fun igba akọkọ lati oṣu Keje ti Houthi ti bẹrẹ ikọlu si Saudi lakọtun.
Ileeṣẹ ijọba Amẹrika to wa nilẹ naa ti kilọ fun awọn ọmọ Amẹrika ki wọn maa ṣọra ki wọn si gbaradi fun idiwọ si irinajo ofurufu nibẹ.
Ninu atẹjade ti Amẹrika fi ṣọwọ fi awọn eeyan rẹ nibẹ, o ni ija naa le lagbara ju bo ṣe wa lọwọ yii lọ.
Atẹjade naa gba awọn ọmọ Amẹrika nimọran pe ki wọn lọ si agbegbe mii to jina rere si ogun ọhun.
Ẹwẹ, atẹjade kan lati akata ijọba Saudi fidi rẹ mulẹ pe ohun ija to n daabo bo ilẹ naa dojukọ awọn ado oloro ti wọn fi ṣọwọ si awọn ilu bii Bish, Taif, Farasan ati Yanbu ko to balẹ sibi ti awọn araalu n gbe.
Agbẹnusọ Houthi, Yahya al-Sarea sọ loju opo ayelujara pe oniruru ado oloro lawọn ti fi ṣọwọ si awọn dukia ijọba ni Saudi.
O ni ikọlu naa ko ṣẹyin igbiyanju ijọba Saudi lati kọ ilu Sanaa, to jẹ olu ilu Yemen.
Ṣaaju ni Sarea ti kọkọ fẹsun kan ijọba Saudi pe o fi ado oloro to le ni 300 ranṣẹ si Yemen laarin ọsẹ to kọja.
Ileeṣẹ iroyin AFP jabọ pe eeyan mejidinlaadọta lo ba ikọlu laarin orilẹede mejeji lọ lọjọ Abamẹta, amọ a ko le fidi iroyin naa mulẹ.


























