Gbenga Adeboye máa ń bá mi sọ̀rọ̀ lójú oorun, ẹ̀ẹ̀mẹta lóṣù sì ni wọ́n ń fi iṣẹ́ rán mi láti ọ̀run sí ayé - Àbíjọ Gbenga Adeboye
Odu ni Oloogbe Gbenga Adeboye, to jẹ gbajumọ alawada, agbohunsafẹfẹ, akọrin, osere tiata ati akewi nigba aye rẹ, kii si se aimọ fun oloko.
Koda, aimọye awo orin, awada ati ewi ni oloogbe Adeboye, ti ọpọ eeyan mọ si Funwọntan, ti gbe jade, eyi ti wọn si n fọhun lẹyin iku rẹ.
Lootọ ni awọn eeyan ko tii fi bẹẹ mọ ohun to n jẹ itakun agbaye nigba ti Gbenga Adeboye wa laye amọ ori redio ati inu awo orin rẹ ni wọn ti maa n gbadun awada ati ere Funwọntan nigba naa.
Ọgbọnjọ osu kẹrin ọdun 2003 ni Funwọntan jade laye lasiko aisan kan to se e, eyi to ti to ọdun mẹtalelogun bayii.
Sugbọn lẹyin iku rẹ, ọpọ eeyan lo jade lati sin Gbenga Adeboye jẹ, ti wọn fẹ maa se bo se n se nigba aye rẹ nidi ewi kike, orin kikọ ati gbigbe awo awada sita.

Yoruba ni ẹyẹ ti yoo se kọrin bii awoko sọwọn, bẹẹ ni ọrọ naa ri tori gbogbo awọn to fẹ se bii Gbenga Adeboye lẹyin iku rẹ ni wọn ko ni ohun bii tiẹ tabi le pe ede bo se yẹ.
Sugbọn laipẹ yii ni ọdọkunrin kan n gba ori ayelujara kan, ẹni to fi ohun, ede ati awada jọ ti Gbenga Adeboye gangan.
Koda, ikemeji Adeboye ni eeyan yoo pe Zacheus Olaoluwa ti ọpọ eeyan mọ si Return of Gbenga Adeboye, eyi to tumọ si ipadabọ Gbenga Adeboye, tori ohun gbogbo lo fi jọ iwa ati isesi oloogbe naa lori ayelujara.
Idi ree ti BBC News Yoruba fi tọ ọdọkunrin naa lọ lati mọ si nipa igbe aye rẹ ati ibasepọ to ni pẹlu Funwọntan nigba to wa loke eepẹ.
"Wọn n beere pe bawo ni mo se jẹ si Gbenga Adeboye, amọ a ko tan mọ ara wa, ọmọ Odeomu ni Adeboye, emi jẹ ọmọ Apomu, opopona lo la ilu mejeeji laarin"
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Zacheus Olaoluwa ni ọmọ bibi ilu Ikire-Apomu nipinlẹ Osun ni oun se, to si jẹ pe ọpọ lo maa n beere pe se lootọ ni oun tan mọ Gbenga Adeboye.
"Wọn maa n beere pe bawo ni mo se jẹ si Gbenga Adeboye tori mo jọ gan ni, wọn a ni tohuntohun mi, tọrọ-tọrọ, ti oju mi ati irisi mi gan si jọ ti Gbenga Adeboye.
Amọ a ko tan mọ ara wa rara, ilu lo kan pa wa pọ, ọmọ ilu Odeomu ni Adeboye nigba ti emi jẹ ọmọ ilu Apomu, opopona si lo la ilu mejeeji laarin.
Lati kekere mi ni mo ti maa n sọrọ bi mo se n sọrọ yii, ti mo si maa n da sọrọ ninu yara.
Wara Soya ni mama mi n ta, mo si maa n ba kiri wara naa."
Zacheus Olaoluwa tẹsiwaju pe lasiko ti oun n kiri wara Soya lọ, ni oun de ibi kan ti wọn ti n gbọ awo orin ati awada Gbenga Adeboye.
"Ẹ ni to n gbọ awo orin naa maa n ra wara lọ mi, mo wa lọ ba wipe ọpọ ọrọ ti mo maa n sọ ninu ile wa, ni onitọun n gbe sita ninu awo orin yii?
Ẹni yẹn wa ni emi bawo, Gbenga Adeboye ni ẹni to n sọrọ naa, nigba to maa mu paali awo orin naa jade, mo ri aworan Gbenga Adeboye lara rẹ.
Mo wa n ro pe ẹni to wa ninu aworan yii ma wa jọ mi, ti ẹni naa si fara mọ pe lootọ lo jọ mi.
O wa sọ fun mi pe oun yoo da awo awada naa duro, ibi ti Gbenga Adeboye ba si ti dakẹ ni emi yoo ti bẹrẹ lati fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni mo maa n sọ awọn ọrọ to sọ.
O ni bibẹẹkọ, oun maa na mi, mo si fara mọ, Ayetoto ni akọle awo orin ọhun lọjọ naa.
O ba da awo orin naa duro, mo ba gbe lati ibẹ, mo si n sọrọ bii Gbenga Adeboye, bi onitọun se mu igbe bọnu ree pe 'Oku ree o, oku ree o', to si sa kuro lọdọ mi"

"Lọpọlọpọ igba ni mo maa n ri Gbenga Adeboye, a mọ yọ si mi, ba mi sọrọ loju ala"
Zacheus Olaoluwa tun salaye pe lọpọ igba ni oun maa n ri Gbenga Adeboye, to si maa n yọ si oun daadaa.
"Lasiko ti Gbenga Adeboye ba yọ si mi, ọpọ ọrọ asiri la jọ maa n sọ, ta si maa n sọrọ asiri ijinlẹ.
Ọpọ odu miran to ba sọ fun mi ni maa maa rẹrin, yoo maa ni iwọ ni emi, emi ni iwọ.
Ldun ti a lọ sibi isinku iya Gbenga Adeboye, wọn fun mi ni amohunbugbẹmu, wọn ni ọmọdekunrin, ọmọ ọdun mẹfa fẹ sọrọ.
Bi mo se sọrọ bayii, gbogbo awọn agbohunsafẹfẹ to wa nibẹ lo n sọkun pe se ọmọ Gbenga Adeboye ni mi ni?"
"Wọn n dunkooko mọ mi lori foonu pe ki n ma se bii Gbenga Adeboye mọ, ki n ma sọrọ bẹẹ mọ, wọn ro pe mo ti n ri owo jaburata, bẹẹ ni n ko ri owo kankan"
Olaoluwa salaye pe lẹyin ti oun ti ibi isinku iya Gbenga Adeboye naa de, nibi tawọn sọrọsọrọ ti nawo fun oun rẹkẹrẹkẹ, nnkan nla sẹlẹ si oun.
"Ọrẹ mi kan ni wọn lo pe ko fi nnkan sinu ohun mimu ẹlẹrindodo mi, n ko ba mọ ohun ti mo n se mọ, ti mo si lo odidi ọdun meje ni ori oke.
Ọjọ mẹta ni mo fẹ lo tẹlẹ, mo si pada lo odidi ọdun meje, lẹyin igba naa, mo wa di ẹni to n ti ori oke kan kan bọ si omiran.
Mo lọ si sọọsi to jẹ pe emi gan wa ya giran ninu adura gbigba, idojukọ pọ fun mi titi di isinsinyii."
Bakan naa ni Olaoluwa fikun pe ọpọ eeyan lo ti wa ba oun, ti wọn n dunkooko mọ oun, tori pe oun n sọrọ bii Gbenga Adeboye.
"Wọn ro pe boya mo ti n ri owo jaburata, bẹẹ ni n ko ri owo kankan, Ọlọrun kan gbe orukọ mi soke ni.
Pakejini ni gbogbo ohun ti wọn n ri lori ayelujara bo se ri niyẹn.
Wọn n dunkooko mọ mi lori foonu pe ki n ma se bii Gbenga Adeboye mọ, ki n ma sọrọ bẹẹ mọ, ki n kuro lori ila yẹn.
Alẹ ọjọ ti wọn sọ bẹẹ fun mi, mo ba tun ri Gbenga Adeboye loju oorun, to si n kọrin fun mi, mo wa sọ ohun to n sẹlẹ fun.
Mo ni wọn ro pe mo ti pa owo nla ni tori mo fun wọn ni ẹgbẹrun marun Naira lasan?
Gbenga Adeboye wa da mi lohun pe se n ko mọ pe ọrọ ki sibẹ ni, pe ki n ma da wọn lohun, ki n maa se temi lọ.

"Mo maa n gba isẹ lati ode ọrun, ẹẹmẹta losu titi ti yoo fi pe osu mẹta ni mo maa n gba isẹ naa, amọ ko si owo ti maa fi fọnrere isẹ naa kaakiri agbaye"
Zacheus Olaoluwa tun yan pe ti oun ba jade si igboro, ọpọ eeyan lo maa n fa oun, pe ki oun wa fun awọn ni owo.
"Wọn maa n pariwo Return of Gbenga Adeboye, Return of Gbenga Adeboye, ba wa mu owo, alaye fun wa lowo.
N ko si ni owo lọwọ, pakejini ni gbogbo rẹ, emi ti n ko ni mọto , ọkada ni mo maa n gun kiri.
Mo maa n gba isẹ lati ode ọrun, ẹẹmẹta losu titi ti yoo fi pe osu mẹta ni mo maa n gba isẹ naa, ti wọn yoo ran mi si gbogbo agbaye.
Lootọ ni wọn fun mi ni isẹ lati jẹ amọ ko si owo ti maa fi fọnrere isẹ naa kaakiri agbaye.
Idojukọ ti mo n ri, o pọ gan, a fi ki Ọlọrun gbe oluranlọwọ dide fun mi ni."



