Ó ṣe pàtàkí fún aráàlú láti di ìjọba ìbílẹ̀ wọn mú lóri ebi tó wà níta

Ọkan lara awọn gbajugbaja oloṣelu nipinlẹ Osun, Kayode Oduoye ti sọ pe ko si ẹbi kankan lọwọ Aarẹ ilẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu, lori ebi ti awọn araalu n pariwo.
Kayode Oduoye to tun jẹ olumọ-ọn-ka oniṣowo ati alaanu mẹkunnu sọ pe ojuṣe ijọba ibilẹ ni lati wa ọna abayọ si iṣoro to n dojukọ araalu lẹka jijẹ ati mimu.
Odunoye sọ pe Aarẹ Bola Tinubu ti gbiyanju agbara rẹ, nipa awọn agbekalẹ eto ti yoo ṣe araalu lanfaani, ati pe ijọba ibilẹ lo ku si lọwọ lati ṣe ojuṣe wọn.
Nigba to n sọrọ nibi ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba, Oduoye sọ pe gbogbo awọn eto ti Aarẹ Naijiria gbe kalẹ, lo wa fun irọrun gbogbo araalu.
"Labẹ aarẹ yii naa la ti ni ohun ti a n pe ni agbara ijọba ibilẹ. Owo n lọ si apo ijọba ibilẹ lati oke, lati ni ipa to jọju fun awọn araalu," Oduoye sọ bẹẹ.
O tẹsiwaju pe, "Ṣe ẹ ri awọn eto ti Aarẹ ti fi silẹ yii, eto bi irọrun yoo ṣe ba gbogbo wa ni. Ṣugbọn ti ẹ ba maa ri araalu nigba ti wọn ba n pariwo, Tinubu ni yoo pariwo, ko nii pariwo ijọba ibilẹ rẹ.
"Ki wọn bẹrẹ sii mu awọn ijọba ibilẹ naa lọrun ọwọ bayii."
"Kò sóhun tó burú nínú àgbékalẹ̀ Ààrẹ"
Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe, ko s'ohun to buru ninu agbekalẹ aarẹ, nitori pe gbogbo rẹ lo n ṣe iranwọ fun eto ọrọ aje kereje-kereje ati kekeekee.
"Ọpọlọpọ lo n pariwo pe ebi pọ nita. Ṣe ẹ rii, nnkankan wa ti wọn n pe ni 'macro' ati 'micro' ninu eto ọrọ aje.
"Agbekalẹ ijọba gbọdọ ni ipa rere ati ayipada lori eyi ti a n pe ni 'macro', ko to lọ sori 'micro'.
"Ẹ maa rii pe, fun apẹẹrẹ, ariwo yiyọ owo iranwọ ori epo ni awọn eeyan n pariwo. Ko si ipinlẹ to n ya owo lati san owo oṣiṣẹ mọ.
"Ko si ipinlẹ to n jẹ owo oṣiṣẹ, ti ko san owo oṣiṣẹ mọ. owo ajẹẹlẹ ati owo ifẹyinti ni wọn ti n san lasiko. Bẹẹ naa lo si jẹ pe ọpọ awọn gomina to ni nnkan to dara lakaa fun awọn eeyan wọn, ni wọn n ṣe daadaa.
"Ẹ maa rii pe wọn n ṣiṣẹ idagbasoke. A ri awọn kan to jẹ pe iṣẹ oju opopona ni wọn dawọ le. Awọn kan si ree, eto iṣẹ agbẹ ati ọgbin ni wọn mojuto.
"O wa lori iru gomina teeyan ba ni, ni ipinlẹ to ti wa. Bawo lo ṣe ye e si, bawo ni yoo ti mọ bi yoo ti na owo si.
"Aarẹ ko le wa ṣe ipinlẹ wọn fun wọn, ti aarẹ ni lati bojuto ibi ti kudiẹ-kudiẹ wa nipa ọrọ owo. O dara, owo ti a n tọju nibi sọbusidi ti a n yọ, ẹ jẹ ka ko o fun ipinlẹ."
Nípa àwọn gómìnà tó n yan amúgbágbẹ̀lẹ́
Nigba to n sọrọ nipa bi awọn gomina kan ṣe n yan awọn amugbalẹgbẹ rẹpẹtẹ, Oduoye jẹ ko di mimọ pe ko si ohun to buru nibẹ, niwọn igba to ba ti jẹ pe araalu ni wọn n yan.
O ni to ba jẹ pe awọn gomina naa n gbe eeyan lati ipinlẹ miran ni, ni awọn eeyan le maa sọ pe wọn ko ṣe daadaa, ṣugbọn lai jẹ bẹẹ, inu ipinlẹ naa lowo wọn ṣi duro si, ko jade sita.
"Ṣe ẹ ri awọn gomina ti wọn n sare yan amugbalẹgbẹ lasiko yii, mo mọ pe itumọ ti awọn eeyan yoo kọkọ fun un ni pe, nitori pe eto idibo ti to, ni wọn ṣe n yan awọn ti wọn n yan," Oduoye sọ bẹẹ.
O sọ pe, ibeere to yẹ ki wọn maa beere ni pe, "ṣe awọn araalu wọn ni wọn n yan? Ṣe awọn to jẹ oludibo ni wọn n yan. Ṣe awọn ti yoo jẹ anfaani ninu ijọba ni wọn n yan?
"To ba ti jẹ araalu wọn ni wọn n yan, ti kii ṣe pe ara Ondo wa yan ara Sokoto; ti ara Ondo ko yan ara Anambra; ti ko si yan ara Eko, to ba ti jẹ ara ilu ẹ lo yan, ti araalu yoo si jẹ anfaani lara awọn to yan, owo ilu naa lo n na fun ilu.
"Ti temi ni pe, ko gbọdọ jẹ awọn oloṣelu nikan, nitori pe to bay a, wọn maa sọ pe wọn ti ko owo jẹ."






