Kí ló fa rògbòdìyàn láàrín Bísọ̀ọ̀bù Onaiyekan àti ìjọba apapọ, tí wọn ṣe ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ síra wọn?

Bisọọbu Onaiyekan wọ asọ alufa, o si de fila pẹrẹsẹ pupa si pẹlu aworan aarẹ Bola Tinubu to wọ asọ sokoto ati ẹwu dudu pẹlu fila alawọ waini

Oríṣun àwòrán, Collage

Àkọlé àwòrán, Biṣọọbu Onaiyekan/Others-Bola Tinubu/Facebook
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Lopin ọsẹ to kọja yii lọrọ di pẹntuka laaarin awọn alakoso ijọ Katoliiki nilẹ Naijiria, lẹyin ipade ti wọn ṣe pẹlu Aarẹ Bola Ahmed Tinubu nile agbara, Aso Rock to wa niluu Abuja.

Awọn alakoso naa ni wọn lọ ṣabẹwo si Aarẹ, nibi ti wọn ti sọ nipa awọn adojukọ wọn, ohun to n ṣẹlẹ lagboole Kristẹẹni, ati awọn nnkan miran to tun nii ṣe pẹlu ọrọ eto aabo.

Nibi ipade ọhun la gbọ pe awọn alakoso ijọ Katoliiki naa ti gbena woju Aarẹ Tinubu, leyi to jẹ ki ileeṣẹ aarẹ fibinu sọrọ si wọn lopin ọsẹ to kọja yii, ti wọn si lawọn olori ẹlẹsin ọhun ko duro fun otitọ ati alaafia.

Ileeṣẹ aarẹ lo bu ẹnu atẹ lu iwa ti awọn olori ijọ naa hu lasiko ipade ti wọn ṣe pẹlu Aarẹ Bola Tinubu, pẹlu bi wọn ṣe sọ pe awọn eeyan ọhun kii ṣe aṣoju ẹsin lori ohun to n lọ lorileede ọhun.

Ileeṣẹ aarẹ tun bu ẹnu atẹ lu Biṣọọbu ijọ naa niluu Abuja, John Onaiyekan lori bo ṣe lọ tu aṣiri awọn ohun ikọkọ to ṣẹlẹ nibi ipade pẹlu aarẹ, to si ni kii ṣe ẹni to ṣee fi aṣiri pamọ si lọwọ.

Ninu atẹjade ti awọn agbẹnusọ aarẹ meji bii Temitope Ajayi ati Daniel Bwala fi sita lọtọọtọ lọjọ abamẹta, wọn ni ko sohun to buru ninu awọn nnkan ti aarẹ sọ nipa ohun to n ṣẹlẹ lorileede Naijiria.

Ajayi ati Bwala sọ pe iṣẹjọba aarẹ faaye silẹ fun ẹnikẹni lati sọrọ bo ṣe ri loju wọn, bẹẹ si ni ojuṣe aarẹ ni lati sọrọ gbe ara rẹ.

Igbesẹ awọn agbẹnusọ ileeṣẹ aarẹ yii ko ṣẹyin ifọrọwerọ ti Onaiyekan ṣe lọjọ Ẹti lori amohunmaworan ti ileeṣẹ Arise, nibi to ti tu aṣiri gbogbo ohun to ṣẹlẹ nibi ipade ti wọn ṣe pẹlu aarẹ lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keje, ọdun yii.

Kí ni Onaiyekan sọ, tó di wàhálà?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nibi ipade ti agba olori ẹlẹsin naa ṣe, lo ti sọ pe gbogbo igba ni eto ọrọ aje orileede Naijiria n le mọ awọn araalu, to si ni ipenija eto aabo ati ipo ti eto oṣelu awa-ara-wa wa lakooko yii ko bojumu to.

Onaiyekan sọ pe gbogbo ohun ti awọn agbaagba Biṣọọbu naa ba aarẹ sọ ko tii pọ ju, nitori pe otitọ pọmbele ni, ti awọn ko si le maa fi ọrọ sabẹ ahọn sọ.

O ni awọn iwe ti wọn gbe lọ siwaju aarẹ lo jẹ erongba ati ipinnu gbogbo ohun ti wọn ba bọ nibi ipagọ ti wọn ṣe laipẹ yii.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe, "Ẹ jẹ ki n sọ eyi fun un yin pe ohun ti aarẹ wa ka sita, kii ṣe ọrọ ẹnu rẹ lasan, bi ko ṣe erongba gbogbo wa pata ti a ko jọ lọtọọtọ. A ṣagbeyẹwo rẹ finnifinni, bẹẹ si la fi to awọn tọrọ kan leti.

"Ipagọ awa Biṣọọbu ga ju ẹnikẹni tabi ẹgbẹ yoowu ti a wa nibẹ lọ, to si jẹ pe ohun naa lo ṣoju gbogbo awọn aṣoju Biṣọọbu to kopa.

"Fun idi eyi, ipagọ apero awa Biṣọọbu lo ṣagbekalẹ iwe naa. Wọn kọ ọ, a tun un kọ, bẹẹ la tun ṣe ayipada ninu awọn aṣiṣe to wa ninu rẹ. Kii ṣe pe a kan gbe e lọ, tabi wi pe a fi ọwọ yọbọkẹ mu," o ṣalaye.

Agba ẹlẹsin naa sọ pe awọn Biṣọọbu ko ni erongba oṣelu kankan ti awọn n lepa, tabi awọn ni iwa imọtara-ẹni-nikan lati daabobo, bi ko ṣe pe otitọ lawọn n sọ nipa awọn ipenija to n koju gbogbo ọmọ Naijiria.

"Mo lero wi pe o ni anfaani lori eto yii lati ran gbogbo ọmọ Naijiria leti wi pe, gẹgẹ bii Biṣọọbu, a ko ni erongba lati gba iṣẹ Aarẹ Tinubu tabi iṣẹ ẹnikẹni. A kii ṣe oloṣelu to n du ipo.

"Olori ẹlẹsin la jẹ ti a si ro pe a ni ojuṣe – ti kii ṣe lati waasu nikan ọrọ Ọlọrun nikan, bi ko ṣe lati tun sọrọ lori ohun to nii ṣe pẹlu awọn eeyan wa ati awọn araalu lapapọ. Ẹ maa ṣakiyesi eyi ninu ohun to wa ninu iwe ti a kọ ati ilana ti a gba kọ ọ," Onaiyekan sọ bẹẹ.

O fi kun ọrọ rẹ pe awọn sọ fun Aarẹ Tinubu wi pe agbekalẹ eto ọrọ aje n ko irẹwẹsi ọkan ba awọn ọmọ Naijiria, ṣugbọn ara duro lori wi pe eto ọrọ aje dagba labẹ iṣejọba rẹ.

Bakan naa lo sọ pe awọn Biṣọọbu mọn-ọn-mọ gbe awọn ohun to jẹ otitọ nipa adojukọ gbogbo ọmọ Naijiria lọ siwaju aarẹ, dibo ki wọn maa tan an jẹ lori ipo ti orileede Naijiria.

"Nigba ti orileede ba n ṣẹjẹ, ẹ ko gbọdọ lero ipade to dara pẹlu olori orileede. A sọ fun un wi pe eto ọrọ aje ko ran awọn araalu lọwọ; ṣugbọn o sọ pe nnkan to n ṣe daadaa ni. Aarẹ sọ fun wa pe oun ko gba pẹlu wa.

"Awa naa ko lero wi pe ki aarẹ gba ohun ti a sọ gbọ. Awa ti ṣe ojuṣe wa, a ti fi ọrọ ati imọlara wa ranṣẹ, mo mọ pe to ba ya, ẹnikan yoo fi awọn ohun ti a sọ han an.

"A kii ṣe oloṣelu to n le ipo oṣẹlu. Olori ẹlẹsin la jẹ, ti a si ro pe kii ṣe ojuṣe wa nikan ni lati waasu ọrọ ẹsin, bi ko ]se lati sọrọ lori awọn nnkan to n ṣẹlẹ si awọn eeyan wa," o sọ bẹẹ.

Siwaju sii lo sọ pe pẹlu oju ti awọn fi wo aarẹ nibi ipade lọjọ naa, awọn ṣakiyesi pe inu Aarẹ Tinubu ko dun si awọn.

"Ẹ beere lọwọ nipa ohun ti mo ṣakiyesi nipa erongba Aarẹ. Ko ya mi lẹnu wi pe inu aarẹ ko dun, bẹẹ si lawọn eeyan Aarẹ ti wọn wa nibẹ pẹlu ni inu wọn ko dun.

"Mo mọ pe ohun ti a gbe lọ yii yatọ patapata si eyi ti awọn kan ti n gbe lọ tẹlẹ fun un. Eyi si jẹọkan lara awọn ohun to n kọ wa lominu; ọpọ awọn eeyan lo yi aarẹ ka, ti wọn si n purọ fun un, eyi ti ko yẹ ko ri bẹẹ.

"Awa lero wi pe a ti ṣe ojuṣe wa. A ni ojuṣe lati mọ riri awọn eeyan lori ipo ti a ba ara wa," Onaiyekan ṣalaye.

Kí ni iléeṣẹ́ Ààrẹ wá sọ?

Nigba toun n sọrọ, Ajayi to jẹ amugbalẹgbẹ agba pataki fun aarẹ lori iroyin ati ipolongo lori bo ṣe ni awọn Biṣọọbu naa gbajumọ ipenija to n dojukọ orileede, dibo awọn aṣeyọri ti iṣakoso Tinubu ti ṣe.

O ni awọn Biṣọọbu naa wa ọna lati ri aarẹ, wọn si ri anfaani lati sọ erongba wọn, to si ni aarẹ farabalẹ gbọ wọn, to si da wọn lohun pẹlu awọn ẹri aridaju.

"Yatọ si anfaani NELFUND ti wọn lọra lati tẹwọ gba, gbogbo awọn aṣeyọri miran ni wọn ko ri. Awọn Biṣọọbu yii sọrọ, ti aarẹ fi farabalẹ gbọ wọn, ko to fun wọn lesi bo ti tọ.

"Ibi to yẹ ki ọrọ naa pari si ree.Ko si eyikeyi ninu ohun ti awọn Biṣọọbu naa sọ to kọja agbeyẹwo. Ọrọ ti wọn gbe wa ko lọ ni ibamu pẹlu ọrọ Ọlọrun tabi ọrọ igbagbọ rara. O jẹ oju ti wọn fi wo o, ati pe iru igbesẹ bẹẹ ṣee tako pẹlu ẹri aridaju," Ajayi ṣalaye.

O ni awọn agbekalẹ idagbasoke ti wa lorileede naa, paapaa nibi owo oṣu ati owo ifẹyinti sisan, to si ni ko yẹ ki ẹnikẹni le gbojufo iru idagbasoke bẹẹ.Ninu ọrọ tiẹ, Daniel Bwala to jẹ oludamọran pataki fun aarẹ lori agbekalẹ eto iroyin fẹsun kan Onaiyekan wi pe awọn ọrọ rẹ nu ti oṣelu dani.

O ni oludije sipo aarẹ ẹgbẹ oṣelu Labour, Peter Obi ni ijọ Katoliiki tẹlẹ ninu eto idibo aarẹ lọdun 2023, fun idi eyi, o sọ pe ko jọ oun loju nigba ti wọn ko ba ri nnkan gidi ninu aṣeyọri iṣakoso aarẹ.

"Cardinal Onaiyekan ko sọrọ fun awọ Kristẹẹni; o n sọrọ fun ijọ Katoliiki ni. Ati pe kii ṣe gbogbo ọmọ ijọ Katoliiki ni wọn n ṣatilẹyin fun Peter Obi.

"Fun idi eyi, Onaiyekan faramọ oṣelu ju ọrọ ẹmi lọ. Aarẹ ni ẹtọ lati ma ṣe gba awọn ọrọ tabi ohunkohun ti wọn lero lọ, nipa eto ọrọ aje Naijiria, ni ibamu pẹlu awọn ojulowo ẹri," Bwala sọ bẹẹ.