Ajinigbe yinbọn pa awakọ wa, ibọn ba emi naa, eeyan mejila ṣi wa nigbekun wọn pẹlu- Ẹni ti ori ko yọ ninu ijinigbe nipinlẹ Nige
Lọjọ kin-in-ni oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii ti i ṣe ayajọ ọdun kẹrindinlaadọrin (66) ominira orilẹede Naijiria ni awọn eeyan kan ti wọn n bọ lati ipinlẹ Sokoto, ti wọn si n lọ si ipinlẹ Oyo, bọ sọwọ agbebọn.
Yatọ si awọn agunbanirọ ogun to n lọ si ipinlẹ Imo ti wọn ji gbe lọjọ yii kan naa, awọn ti wọn n bọ lati Sokoto yii naa ko si ajinigbe lọwọ lagbegbe kan ti a mọ si Pelegi, Mokwa, nipinle Niger.
Iroyin to kọkọ jade nigba naa ni pe ọmọ ilu Igboho, nipinlẹ Oyo ni gbogbo awon ti won ji gbe naa, ati pe akẹkọọ ni wọn.
Iroyin naa sọ pe eeyan mejidinlogun to wa ninu odidi ọkọ kan ni awọn agbebọn naa kọlu ti wọn si gbe wọgbo lọ.
Lati fidi otitọ iṣẹlẹ yii mulẹ, BBC News Yoruba kan si lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si, amọ ti wọn ri ọna sa lọ mọ awọn ajinigbe agbebọn naa lọwọ.
Yekini Suraju,toun naa jẹ awakọ, ṣalaye pe:
"Mọto wa n bọ lati Sokoto, igba ti a de apa kan Mokwa, nibi ti wọn n pe ni Pelegi, awọn bandiiti jade si wa.
"Awa tiẹ ro pe ọmọde ni awọn ta a n wo lọọkan nibi odo ti wọn wa ni, tori ẹ ni dẹrẹba ọkọ wa ṣe din bo ṣe n sare ku.






