Ìjíròrò gbóná nílé aṣòfin àgbà lórí àbá tó ní kí wọn yọ ète láti pa ara ẹni kúrò lára òfin ìwà ọ̀daràn

Oríṣun àwòrán, Tope Brown/Nigerian Senate
Ile asofin agba ni Naijiria ti n jiroro lori aba kan to n beere pe ki wọn ete lati gbẹmi ara ẹni kuro lara awọn ofin to jẹ mọ iwa ọdaran.
Aba naa si lo da awuyewuye ati ijiroro nla silẹ nibi ijoko ile asofin agba to waye lanaa.
Ohun ti wọn si n jiroro le lori naa ni pe se o lẹtọ ki orilẹede kii maa fiya jẹ awọn eeyan to ba ye nidi igbiyanju lati gba ẹmi ara wọn tabi ko maa se itọju wọn.
Aba naa, eyi ti Sẹnatọ Asuquo Ekpenyong to n soju ẹkun guusu ipinlẹ Cross Rivers se onigbọwọ rẹ ni wọn ka fun igba keji nibi ijoko ile asofin agba lanaa.
Aba naa lo n beere pe dipo ki wọn maa sa awọn eeyan to ba gbinyanju lati pa ara wọn mọ ẹwọn, se lo yẹ ki ọna abayọ mii wa fun wọn.
Lara awọn ọna abayọ ti aba naa gbe kalẹ fun ẹni to ba dete lati pa ara rẹ ni sise agbeyẹwo ọpọlọ ati igbe aye rẹ, gbigbe wọn lọ fun itọju ati sise akoso igbe aye wọn.
Amọ awọn asofin agba kan, to fi mọ aarẹ ile asofin, lo gbagbọ pe fifi iya jẹ awọn eeyan to ba gbinyanju lati gba ẹmi ara wọn yoo jẹ ẹkọ nla fun awọn eeyan miran to bag be igbesẹ naa lọjọ iwaju.
"Ti o ba gbìyànjú láti pa ara rẹ, ri daju pe o ku patapata bi bẹẹ kọ, ẹnikẹni to ba da ete lati pa ara rẹ amọ ti ko ku ni yoo lọ fi asọ penpe ro oko ọba."
Akpabio lo salaye bẹẹ nibi ijiroro ile asofin agba naa lori aba yii.
Aba yii si lo da awuyewuye nla silẹ nipa pe ki orilẹede yii kuro nidi fifi iya jẹ awọn eeyan to ba da ete lati pa ara wọn, dipo bẹẹ, se lo yẹ ko maa se itọju wọn lẹyin ti wọn ba ye isẹlẹ naa.
Gẹgẹ bi ofin orilẹede yii to kan iwa ọdaran, abala 327 ati 231 ti wi, iwa ọdaran nla ni ete lati gba ẹmi ara ẹni.
Amọ Sẹnatọ Ekpenyong salaye ninu aba naa pe ofin to nii se pẹlu ilera ọpọlọ nilẹ wa ti salaye pe se lo yẹ ka ri ete lati gba ẹmi ara ẹni bii igbesẹ to yẹ ka tete da si labẹ ofin ilera ọpọlọ.
"Amọ se ni ofin ilẹ wa n fi ahọn meji sọrọ lori eleyi"
Bi o tilẹ jẹ pe wọn gbe aba naa kalẹ lati sọ ete pipa ara di iwa ọdaran, bakan naa lo doju kọ ọna ti wọn fi le e se amojuto isẹlẹ yii, to fi mọ awọn nọmba ti wọn le pe, ilanilọyẹ fun araalu, idanilẹkọ fawọn ọlọpaa, olukọ ati awọn osisẹ eleto ilera to fi mọ ilana amojuto lati dena iwa pipa ara ẹni.
Asofin to se onigbọwọ aba naa ja a niyan pe sisọ ete pipa ara ẹni di iwa ọdaran lo maa n jẹ ki awọn eeyan to ba fẹ pa ara wọn mase maa beere fun iranlọwọ, eyi to si tun maa n mu kawọn idile da asọ bo irufẹ isẹlẹ bẹẹ, eyi to maa n se idiwọ lati ni akọsilẹ to peye fun sise akoso awọn isẹlẹ yii lọjọ iwaju.
Amọ ijiroro ile asofin yii lo si asọ loju awọn ibeere pataki kan lori idi ti ọpọ ọmọ Naijiria se maa n da ete lati gba ẹmi ara wọn.
Akọsilẹ nilẹ Naijiria safihan ailowo lọwọ, airisẹse, ijakulẹ ninu ọrọ ifẹ ati ibasepọ, wahala eto ẹkọ ati arun ọpọlọ lo saba maa n sokunfa ete lati pa ara ẹni, ati awọn idẹyẹsi to rọ mọ aisan ọpọlọ.




























