Atiku tako ìjọba àpapọ̀: ''Ẹ gbé iye tí ẹ ná lórí ọ̀nà márosẹ̀ Eko sí Calabar jáde pẹ̀lú àlàyé nípa $20b tẹ́ ẹ fẹ́ẹ́ yá''

Oríṣun àwòrán, Presidency/ Atiku Abubakar/Facebook
Atiku Abubakar to n dupo aarẹ Naijiria ninu ẹgbẹ oṣelu ADC, ti tako ijọba Tinubu lori ọna Eko si Calabar ti wọn fẹ gbe wọnu eyi to ti wa nilẹ tẹlẹ l'Ondo ati Edo.
Atiku gẹgẹ bii alatako ijọba yii sọ pe ki ijọba apapọ waa ṣalaye idi igbesẹ rẹ, ki wọn si sọ iye ti wọn ti na lori iṣẹ ọna yii.
Bakan naa lo ni kijọba apapọ ṣalaye $20 billion ti iroyin sọ pe wọn fẹ ya lati fi ṣe ọna yii.
Atiku tun sọ pe ijọba n fin awọn aṣofin lape lati buwọlu ẹyawo, o ni ki wọn ma tun ko gbese ba awọn ọmọ Naijiria, nigba ti ko si èrè kan ti wọn yoo jẹ lara owo tijọba n na ọhun.
Ninu atẹjade ti Phrank Shaibu, Oludari ipolongo fun ibo aarẹ fun Atiku fi sita lọjọ Aje lo ti ni oun fẹ mọ boya lara owo yii yoo lọ sọdọ ileeṣẹ to n ṣe ọna ọhun, iyẹn Hitech Construction Company.
"Tinubu loun yoo ṣe ọna marosẹ nla fawọn ọmọ Naijiria, nisinyi, minisita rẹ ni apa kan ọna ti wọn ti ṣe tẹlẹ ni ọna tuntun yoo tun gba.Bi oju ọna ti wọn fẹ ṣe ba yi pada, iye ti wọn n ṣe e gbọdọ han sita."
Oludije ipo aarẹ ninu ADC yii sọ pe ki David Umahi gbe akọsilẹ akọkọ lori ọna yii jade, ati atunyẹwo pẹlu ohun ti wọn yọ kuro ninu iṣẹ, titi kan iye owo ti wọn fi kun un.
Lori owo to ni ijọba fẹ ya lati ṣe ọna yii, Atiku ni itọpinpin loun fi mọ.
"To ba jẹ pe ko sohun to jọ bẹẹ, ẹ sọ bẹẹ lọwọ kan ki ẹ si jẹ ko wa ni akọsilẹ."
Bẹẹ ni Atiku wi.
Amòfin àgbà Ebun-Olu Adegboruwa àtawọn mí-ìn korò ojú sí bí ijọba ṣe fẹ́ gbé márosẹ̀ Eko sí Calabar gba Ondo/Edo

Oríṣun àwòrán, Ebun-Olu Adegboruwa/ Facebook/ Others
Awọn oloṣelu,amofin, ẹlẹgbẹjẹgbẹ atawọn eeyan ti ko jọ ara wọn ni wọn ti bẹrẹ si I koro oju si igbesẹ ijọba lori ọna marosẹ Eko si Calabar ti wọn fẹ gbe gba Ondo ati Edo bayii.
Lara awọn eeyan to ti pe fun ayipade igbesẹ naa ni gbajumọ aṣofin Ebun-Olu Adegboruwa.
Adegboruwa ninu atẹjade to fi sita lanaa ode yii ti I ṣe ọjọ kejila oṣu Kẹwaa ọdun 2026, rọ ijọba apapọ lati paṣẹ fun minisiri iṣẹ ode lati ṣalaye ayipada yii.
O ni ki wọn ma ṣe jẹ ki oun ti wọn tori rẹ gbe e kalẹ yi pada.
Adegboruwa kilọ, pe yiyi apa kan ọna yii pada le mu ki awọn agbegbe meji ma le de ọdọ ara won mọ, ti yoo si dena ilọsiwaju ọrọ aje wọn.
"Fun awọn eeyan Ilaje ati agbegbe omi nipinlẹ Ondo ati Delta, ki i ṣe ibi ti ọna gba lo ṣe koko, bi ko ṣe boya ileri idagbasoke ti wọn ṣe fun wọn yoo kan wọn lara."
Bẹẹ ni Adegboruwa wi.
Amofin agba naa ṣalaye pe ijọba sare ta aba ọna yii fawọn ọmọ Naijiria ni, ti wọn ni yoo gun de Calabar, ati apa Iwọ-Oorun bayii.
Bakan naa ni gbimọ awọn agbẹjọrọ kan niluu Ondo naa ko ṣai ba ijọba sọrọ, wọn ni ki ileeṣẹ ode kede bo ṣe daju to, pe ohun ti wọn fẹ ṣe yii yoo bọ si deede.
Awọn oloṣelu kan l'Ondo tilẹ sọ pe titẹ abala ofin kan mọlẹ ni igbesẹ yii jẹ.
Lori ayelujara, ọpọ lo n sọ pe ki ni coastal ti ijọba wulẹ n pe ọna naa, nigba ti ko fori sọ omi kankan.
Awọn mi-in n sọ pe sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ yoo wa lọna yii, yoo tako ohun tijọba tori rẹ gbe e kalẹ.
Bakan naa ni awọn mi-in n sọ pe ijọba n na owo ilu danu ni pẹlu ọna yii, bẹẹ ko daju pe araalu yoo ri ere kankan jẹ nibẹ.
Amọ ijọba apapọ ti sọ pe igbesẹ alaafia ni ọna nla yii, yoo si mu idẹra wa lopin ohun gbogbo ni.
Dave Umahi sọ laipẹ yii, pe awọn ọmọ Naijiria yoo lo ọna yii to bii ọgọrun-un ọdun.
Kí ló fa ariwo lórí ọ̀nà márosẹ̀ Eko sí Calabar tí Tinubu pàṣẹ pé kí wọ́n gbé gba Ondo àti Edo? Àlàyé rèé

Oríṣun àwòrán, Others
Aarẹ Bola Tinubu ti paṣẹ pe ki wọn ṣe ayipada oju ọna marosẹ Eko si Calabar (Lagos-Calabar Coastal Highway) lọna ti yoo fi gba ilu Ondo wọ ipinlẹ Edo.
Minisita Iṣẹ Ode, Dave Umahi lo kede eyi.
Alaye ti Umahi ṣe lori igbesẹ naa ni pe o ṣe pataki lati dari ọna bayii lati dena ṣiṣe ọna mi-in laarin iloro eyi ti ijọba n ba bọ yii.
Umahi fi kun un pe ipinnu tuntun yii tun wa fun ẹkun omi to n waye lapa Ila-Oorun si Iwọ-Oorun ( East-West Road), paapaa lagbegbe Ughelli, nipinlẹ Delta.
O ni o wa fun lati yanju apa ibi ti irà to jin ni ọgọrun mita wa, ati omiyale to lagbara.
Umahi sọ pe o tun wa fun ki ijọba fi le din owo ku lai jẹ pe wọn yoo bẹrẹ iṣẹ ọna naa lodidi.
Amọ latigba ti aṣẹ yii ti jade ni ọpọ eeyan ti n kọminu lorii rẹ, ọpọ eeyan lo n sọ pe idi ti ijọba fi fẹ gbe igbesẹ naa ko ye awọn, ọpọ lo si n bu ẹnu atẹ lu u, ti wọn n kọwe ifisun nipa Umahi.
Ki ni "Coastal Highway" naa?
O bẹrẹ lati Victoria Island niluu Eko, loju ọna Ahmadu Bello Way, wọn si ni yoo gba Ogun, Ondo, Edo, Delta, Bayelsa, Rivers ati Akwa Ibom ko too pari si Calabar, ati Cross River State.
Ohun to wa fun:
Ijọba sọ pe o wa fun lati so Iwọ-Oorun ati Guusu Naijiria pọ, ki ọrọ aje, okoowo ati nnkan amayederun le kari.
Awọn ibudo ifọpo Dangote ati Lekki Deep Seaport to wa lọna Eko yoo si jẹ nnkan apewaawo, irinajo afẹ.
Alaye ijọba lori igbesẹ rẹ tuntun
Nigba to n ṣalaye nipa ọna yii, Minisita Iṣẹ Ode;Dave Umahi, sọ pe ijọba ti ṣe ọna yii ki afojusun ayipada oju ọjọ too bẹrẹ.
O ni omiyale to n ṣẹlẹ lẹnu lọọlọ yii si ti n jẹ kawọn eeyan maa beere pe ṣe nnkan ko ni i ṣe ọna naa.
Lati dena idaamu naa lo fa a ti ijọba fi bẹrẹ igbesẹ tuntun laaarin rẹ bo ṣe sọ.
Umahi ṣalaye pe apa kan ọna ọhun to gun ni opo 47.47-kilometre, wa lati Victoria Island niluu Eko, o ni wọn ti pari rẹ, ki ijọba ṣi i lo ku.
O tẹsiwaju pe apa keji ti wọn pin si meji lo gba kilomita marundinlọgọta (55 kilometres) o si pari si aala Eko ati Ogun.
Eyi yoo pari loṣu to n bọ bi Umahi ṣe sọ.
Ni ti Calabar, o ni igun 3A ati 3B, to jẹ kilomita 65 naa ti kọja ida ọgbọn lati pari.
"Mo ri ifisun nipa mi pe mo ti dari oju ọna Ondo gba ibomi-in, mo gba a bẹẹ.
"Amọ nnkan to ṣe pataki ni pe boya ohun to tọ la n ṣe tabi ohun ti ko tọ, a ko kabamọ igbesẹ ta a gbe l'Ondo."
Umahi to sọrọ yii, ṣalaye pe ijọba apapọ dari ọna naa pada lati dena inira, bẹẹ ni iṣẹ ṣi n lọ gidi lati di awọn ibi to yẹ pẹlu.
O ni iloro ọna yii yoo pari si apa kan Ondo-Edo, nigba ti onikilomita marundinlaadọta (45-kilometre) to gba Benin kọja wa fun lati din sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ku.
Ni ti gigun iloro Ondo-Edo pẹlu ọna to wa lẹgbẹẹ, Umahi sọ pe kilomita 104 ni.
"Ko sẹni to gbagbe ọna Lagos-Calabar Coastal Highway oni kilomita 750, a ti n wọn (survey) agbegbe Edo, Delta, Bayelsa. Yoo si kan Rivers pẹlu, iyẹn ni yoo jẹ opin ọna marosẹ Lagos-Calabar Coastal Highway."
Umahi lo sọ bẹẹ.

























