Mi ò ní juwọ́ sílẹ̀ fún ẹnikẹ́ni kódà bí ẹgbẹ́ alátakò bá parọpọ̀ di ọ̀kan - Adegoke, olùdíje ADC ní ìpínlẹ̀ Oyo

Àkọlé fídíò, Mi ò ní juwọ́ sílẹ̀ fún ẹnikẹ́ni kódà bí ẹgbẹ́ alátakò bá parọpọ̀ di ọ̀kan - Adegoke, olùdíje ADC ní ìpínlẹ̀ Oyo
Mi ò ní juwọ́ sílẹ̀ fún ẹnikẹ́ni kódà bí ẹgbẹ́ alátakò bá parọpọ̀ di ọ̀kan - Adegoke, olùdíje ADC ní ìpínlẹ̀ Oyo
Published

Oludije sipo gomina ipinlẹ Oyo lẹgbẹ oṣelu Africa Democratic Party, ADC, Taofeek Adegboyega Adegoke ti sọ pe oun ko ni juwọ silẹ fun ẹnikẹni bi gbogbo ẹgbẹ oṣelu alatako ba parapọ di ẹyọkan.

Adegoke sọ eyi lasiko to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori erongba rẹ lati dupo gomina ipinlẹ Oyo nibi eto idibo ọdun to n bọ.

O ni ọrọ oṣelu gba kiko ọpọ eeyan mọra, ti oun yoo si gba ọpọ eeyan to ba fẹ darapọ mọ oun laaye ṣugbọn oun ṣi ni oun maa durro gẹgẹ bi oludije.

Taofeek Adegoke wọ asọ toketilẹ alawọ buluu ati fila asọ oke buluu, o so ọwọ rẹ mejeeji papọ