Mo kájú ẹ̀ ni mo ṣe jẹ́ olórí aṣòfin fún ọdún mẹ́jọ tí mo sì ń díje sípò gómìnà báyìí - Danladi, olùdíje APC

Àkọlé fídíò, Mo kájú ẹ̀ ni mo ṣe jẹ́ olórí aṣòfin fún ọdún mẹ́jọ tí mo sì ń díje sípò gómìnà báyìí - Danladi, olùdíje APC
Mo kájú ẹ̀ ni mo ṣe jẹ́ olórí aṣòfin fún ọdún mẹ́jọ tí mo sì ń díje sípò gómìnà báyìí - Danladi, olùdíje APC
Published

Oludije sipo gomina ni ipinlẹ Kwara lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Saliu Yakubu Danladi ti sọ pe ko si oludije kankan to ni iriri to oun ninu gbogbo awọn ti wọn jọ n dije sipo naa.

Danladi sọ eyi lasiko to n kopa nibi ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba lori erongba rẹ lati dupo gomina ipinlẹ Kwara nibi eto idibo ọdun 2027.

Danladi to n fesi si ẹsun pe gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq lo fa a kalẹ gẹge bi oludije lati rọpo rẹ nigba ti saa rẹ ba pari lọdun to n bọ.

O sọ pe kii ṣe pe gomina lo fa oun kalẹ ati pe oun kaju oṣuwọn lati tukọ ipinlẹ Kwara bi oun ba ni anfaani lati di gomina nibi eto idibo naa.