Kóòtù sọ Blessing CEO sí àhámọ́, fún ẹ̀sùn lílu jìbìtì N36m

Blessing CEO pẹlu patako ẹsun iwa jibiti ti won fi kan an to gbe dani

Oríṣun àwòrán, EFCC

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Gbajumọ sọrọsọrọ ori ayelujara, Blessing Nkiruka Okoro tawọn eeyan mọ si Blessing CEO, ni ajọ EFCC to n ri si jibiti lorilẹede yii ti wọ lọ sile ẹjọ bayii.

Oni ọjọ Ẹti, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Karun-un ọdun 2026 ni wọn gbe Blessing lọ si kootu.

Ẹsun pe o lu ẹnikan ni jibiti owo ti iye rẹ jẹ miliọnu mẹrindinlogoji (36m) niluu Eko ni wọn fi kan an.

Ile ẹjọ giga ilu Eko to wa n'Ikoyi, niwaju Adajọ D.I. Dipeolu ni Blessing to kede pe oun ni arun jẹjẹrẹ laipẹ yii ti farahan.

Ki lo ṣẹlẹ gan-an?

Gẹgẹ bi alaye ti EFCC ṣe nipa obinrin ti ẹnu ki I sin lara rẹ yii si oju opo wọn, wọn ni ẹsun meji ni Blessing n jẹjọ rẹ.

Awọn ẹsun naa ni fifi ẹtan gba owo lọwọ eeyan ati jiji owo ti iye rẹ jẹ N36m.

Ninu iwe akọsilẹ ẹsun naa ni wọn kọ ọ si, pe Blessing CEO gba N36 million lọwọ obinrin kan, Abilekọ Ifeyinwa Nonye Okoye.

EFCC sọ pe laarin ọjọ kẹrinla si ikẹtadinlogun oṣu Keje ọdun 2024 ni Blessing gba owo naa pẹlu ẹtan.

Wọn lo sọ fun Ifeyinwa pe oun yoo gbe ile oniyara mẹfa kan fun un, eyi to wa ni 1B, Opopona Tunbosun Osobu Lekki, niluu Eko.

EFCC ṣalaye pe irọ ni ọrọ ile naa pada ja si, nigba ti Blessing Okoro ko mu adehun rẹ ṣẹ.

Ẹsun keji ni pe wọn lo dari owo to gba naa si apo ara rẹ, eyi to tun tako ofin iwa ọdaran ilẹ yii.

Blessing CEO ni oun ko jẹbi

Blessing CEO

Oríṣun àwòrán, Blessing Okoro

Nigba to n dahun si ibeere kootu, pe ṣe o jẹbi awọn ẹsun naa tabi bẹẹ kọ, Blessing ni oun ko jẹbi.

Agbẹjọro rẹ, P.I. Nwafor, ṣo fun kootu pe Ọjọbọ ni wọn ṣẹṣẹ fi iwe ẹsun le onibaara oun lọwọ.

O ni Blessing ti san ninu owo naa fun Ifeyinwa, 24m lo ni onibaara oun ti san ninu miliọnu mẹrindinlogoji (36m), yoo si san iyoku pẹlu.

Amọ Adajọ Dipeolu sọ pe ko si ohun to kan kootu ninu iyẹn, o ni ohun ti olujẹjọ ṣe labẹnu ko da igbẹjọ lori ẹsun ti won fi kan an duro.

Lẹyin eyi ni Adajọ paṣẹ pe ki wọn fi Blessing CEO pamọ si ahamọ ọgba ẹwọn, titi digba ti igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju.

Ṣugbọn agbẹjọro rẹ bẹbẹ pe ki adajọ fi Blessing si akata EFCC, titi toun yoo fi ri beeli rẹ gba.

Adajọ Dipeolu gba ipẹ agbẹjọro naa wọle, o si paṣẹ pe ki wọn tọju Blessing CEO si ahamọ EFCC.

Igbejọ mi-in di ọjọ karun-un, oṣu Karun-un ọdun 2026.

Tẹ o ba gbagbe, Blessing CEO ni obinrin naa ti awọn ọmọ Naijiria ti n pe EFCC lati mu tipẹ, lẹyin to kede pe oun ni arun jẹjẹrẹ ọyan to ti de ipele kẹrin.

Ikede naa mu ọpọ eeyan fowo ranṣẹ si Blessing nigba naa, amọ awọn ẹri to jade lẹyin igba naa fi han pe ọrọ ko ri bi obinrin naa ṣe sọ.

Ọpọ eeyan to dawo fun un nigba naa ni won beere owo wọn pada.

Amọ Blessing jade lati bu awọn eeyan to n sọ pe kawọn to dawo fun un gba owo won pada.

O ni oun ko fipa gbowo lọwọ ẹnikẹni. Ṣugbọn o pada tọrọ aforiji lọwọ awon omo Naijiria, o si loun ṣetan lati da owo wọn pada.

Ta a ni Blessing CEO

Blessing Okoro

Oríṣun àwòrán, Blessing Okoro

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọmọ ipinlẹ Ebonyi, lapa Ila Oorun Naijiria ni Blessing Nkiruka Okoro. Ijọba ibilẹ Onitsha ni wọn ti bi i.

Orukọ to sọ ọ di gbajumọ ni Blessing CEO.

Onkọwe ni, sọrọsọrọ ori ayelujara ni, bẹẹ lo si tun maa n sọrọ lori igbeyawo ati ibaraẹnidọrẹẹ ati ibalopọ.

O bi awọn ọmọkunrin meji.

Ẹni ọdun mejidinlogun, (18) ni Blessing nigba to fẹ ọkọ rẹ akọkọ ni 2010, ọkunrin naa lo bi awọn ọmọ rẹ meji fun.

Igbeyawo naa tuka nigba ti Blessing pe ẹni ọdun mọkanlolgun (21)

Ẹni ọdun mẹtadinlogoji (37) ni bayii.

Oṣu Kẹrin ọdun 2019 ni Blessing CEO ṣafihan awọn foto ile nla to ni oun kọ si Enugu, amọ ko pẹ ti Onye Eze, ẹni to ni ile ọhun fi jade pe irọ ni Blessing n pa, oun kọ lo ni ile naa, o si fi ọlọpaa mu un..

Lẹyin eyi ni Blessing ṣe fidio to fi tọrọ aforiji pe irọ loun n pa.

Nipa ajọṣe pẹlu ọkunrin, ọkunrin kan, Ikechukwu Darlington Ogbonna tawọn eeyan mọ si IVD ni wọn ni Blessing n ba dọrẹẹ, ti ọrọ naa si di ariwo nigba ti iyawo Ogbonna to n jẹ Bimbo ni oun ko ni I gba ki Blessing ni nnkan lati ṣe pẹlu ọkọ oun.

Oṣu Kẹwaaa ọdun 2022 ni Bimbo ku lojiji, ko pẹ sigba naa ni iroyin gbe e pe Blessing ati IVD ti n fẹra wọn.

Ko si pẹ sigba naa ti IVD fi ni ki Blessing jẹ kawọn gbe ifẹ awọn lọ si ipele to han saye.