Nítorí ìjàmbá ọkọ̀, ìjọba Ogun fẹ́ẹ́ fòfin de ọjà títà ní Sango Tollgate

Gomina ipinle Ogun; Ọmọọba Dapo Abiodun

Oríṣun àwòrán, Dapo Abiodun/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Lati fopin si ijamba ọkọ to sabaa maa n waye nibi ti a mọ si Sango Tollgate, aala ipinlẹ Eko ati Ogun, ijọba Gomina Dapo Abiodun ti kede pe oun yoo gbe garaji ọkọ ti ko ba ofin mu to wa nibẹ lọ si apa ibomiran.

Yatọ si eyi, ijọba Ogun tun loun yoo fofin de ọja tita loju ọna ti mọto ati ero pọ nibẹ naa.

Kọmiṣanna eto ayika nipinlẹ Ogun, Ola Oresanya, lo kede eyi lasiko abẹwo rẹ si agbegbe Sango Tollgate.

Oresanya to kọwọọ rin pẹlu awọn oṣiṣẹ lati ẹka to n ri si idọti nipinlẹ Ogun; Ogun State Waste Management Authority (OGWAMA), sọ pe:

"Mo ti gba idari lati ọdọ Gomina Dapo Abiodun, ẹni ti ifẹmiṣofo to n waye lemọlemọ lagbegbe yii n kọ lominu, pe ka wadii ohun to n fa ijamba, ka si fopin si ijamba to ṣee dena to n waye nibi yii.

"Lẹyin ayẹwo finni-finni nipa iṣẹlẹ yii, ijọba Ogun pẹlu awọn ti ọrọ kan ti pinnu, lati gbe ibudo ọkọ ti ko lẹtọ to wa nibẹ lọ sibomiran.

"Bakan naa ni wọn yoo si tun fofin de ọja tita ni Tollgate, eyi to ti n ṣẹlẹ lati nnkan bii ọdun mẹẹẹdọgbọn sẹyin.

"Wọn yoo ko wọn lọ sibo miran to jinna si Tollgate, to si jẹ ibi ti eto wa fun."

"Ijọba yoo fi gàgá di ẹgbẹ ọna mejeeji ni Tollgate lati dẹkun awọn ọkọ lati ilu mi-in ati ọja tita''

Yatọ si eyi, o ni atunṣe agbegbe naa yoo waye latọwọ awọn oṣiṣẹ OGWAMA, nigba ti ijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta pẹlu awon ẹṣo eleto ayika yoo mojuto bawọn eeyan ṣe n tẹle ohun ti ijọba n fẹ lagbegbe naa si.

Oresanya sọ pe gbogbo eto yii ki i ṣe ohun ti yoo pẹ, o ni ijọba yoo bẹrẹ rẹ lẹyẹ o sọka ni.

Ẹ o ranti pe laipẹ yii ni eeyan meje padanu ẹmi, nigba ti ijamba ọkọ tirela waye ni Tollgate.