Kílódé tí ọtí pẹlẹbè ṣì pọ̀ ní ìgboro bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba ti gbẹ́sẹ̀ le?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ to n ri si ounjẹ ati oogun lilo ni Naijiria, NAFDAC, ti gbe agadagodo sẹnu ọna ileeṣẹ mẹta ti wọn n po ọti nipinlẹ Ogun lori ẹsun pe wọn n tẹsiwaju lati maa pọ ọti inu ọra lodi si ofin.
Agbegbe Sango-Ota ati Idi-Iroko ni NAFDAC ti gbe igbesẹ naa, eyii to jẹ ọkan lara ọna lati gbena woju awọn to n tapa si ofin pipo ọti inu ọra.
Gẹgẹ bi ohun ti ajọ naa sọ, ọpọlọppọ awọn ileeṣẹ ni wọn ri ti wọn tapa si ofin to de ọti inu ọra naa lasiko ayẹwo wọn.
Ninu ọkan lara awọn ileeṣẹ ti wọn ti pa naa ni wọn ti ri gbangba pe wọn ṣi n po ọti inu ọra.
NAFDAC juwe iwa naa gẹgẹ bii eyi to lodi si ofin to wa nilẹ.
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ ṣayẹwo si ileeṣẹ kan ninu oṣu Kinni ọdun yii nibi ti wọn ti gbẹsẹle irinṣẹ mejilelogun atawọn ohun elo ọti inu ọra.
Amọ nigba ti wọn yoo pada sibẹ, wọn ṣawari pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa ti ja okun ti NAFDAC so mọ ibẹ ti wọn si ti n ba iṣẹ wọn lọ.
Ajọ naa sọ pe igbesẹ ọhun wa lara ojuṣẹ awọn lati ri pe ileeṣẹ kankan ko po ọti inu ọra mọ lẹyin to ti do eewọ ni Naijiria.
NAFDAC tun rọ araalu lati bun awọn gbọ ti wọn ba kofiri ileeṣẹ kankan to ba n po ọti inu ọra, to fi mọ awọn to n ta a.
Lootọ ni wọn fofin de ọti inu ọra amọ o ṣi pọ ni igboro
Bo tilẹ jẹ pe lootọ ni ijọba ti fofin de ọti inu ọra, awọn eeyan ṣi n mu u kaakiri Naijiria.
Ni ọpọlọpọ agbegbe kaakiri Naijiria lawọn eeyan ṣi n ta ọti naa, bẹẹ lawọn araalu ṣi n ra a ni igboro, ọja, atawọn ibudokọ.
Awọn onimọ nipa eto ilera sọ pe bi owo ti wọn n ta ọti inu ọra naa ko ṣe wọn ati bo ṣe wa kaakri ninu ọra pẹlẹbẹ mu ko rọrun fun awọn eeyan lati maa ra a.
Iwọnyin lawọn igba ti ijọba ti gbẹsẹle ọti inu ọra ni Naijiria
Lootọ kii ṣe igba akọkọ ree ti ijọba Naijiria yoo maa pa iru aṣẹ bayii.
- Oṣu kejila ọdun 2018 - Ọdun naa ni igba akọkọ ti ijọba atawọn oniruru ajọ buwọlu adehun latin fopin si pipo ọti ninu ọra, paapaa awọn ọti ti iwọn rẹ ko ju 200ml.
- Ọjọ kinni, oṣu Keji, ọdun 2024 – NAFDAC bẹrẹ si n ko awọn ọti naa lori igba lati le mu aṣẹ iwe adehun naa ṣe.
- Oṣu keji si oṣu Kẹfa ọdun 2024 – Ile igbimọ aṣofin da si ọrọ naa wọn si rọ NAFDAC lati dawọ kiko rẹ kuro lori igba duro latari awọn ti yoo padanu owo ati iṣẹ wọn, paapaa ipa ti igbesẹ naa yoo ni lori ọrọ aje araalu to n ta a.
- Oṣu Karun un, ọdun 2024 – NAFDAC gbẹsẹ kuro lori aṣẹ naa fun igba diẹ titi di ipari ọdun 2025 ki wọn le ṣe ipade pẹlu gbogbo awọn ti rọrọ naa kan.
- Oṣu Kọkanla, ọdun 2025 – ile igbimọ aṣofin kan an nipa fun NAFDAC ko bẹrẹ aṣẹ naa ko si gbẹsẹle ọti inu ọra ni Naijiria lai fun awọn to n po o atawọn to n ta a n afikun gbendeke mii mọ.



























